Ọ̀bọ já ọmọ oṣù kan gbà níbi tó ti ń mu ọmú, òkú rẹ̀ làwọn aládúgbò rí gbà

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ọbọ kan ti ja ọmọ oṣu kan gba lọwọ iya rẹ nibi to ti n mu ọmu lọwọ ninu ile wọn.
Awọn alaṣẹ lorilẹede Tanzania ni ọmọ ikoko naa ku lẹyin ti agbo awon ọbọ kan ya wọ ile awon obi ọmọ oṣu kan naa ni ileto Mwamgongo ni Kigoma, nitoei igbo ọba Gombe Nation Park lẹkun iwọ oorun orilẹede Tanzania.
Ko tii si ẹni to lee sọ ni pato iru ẹya awọn ọbọ to kọlu iya ọmọ naa.
Adari agbegbe Kigoma, James Manyama ṣalaye pe ọmọde jojolo naa ku nigba t’awọn aladugbo naa n fẹ fi ipa gba a lọwọ ọbọ naa.
James Manyana ṣalaye fun iwe iroyin Citizens Newspaper lorilẹede Tanzania pe “Iya ọmọ naa kigbe lohun rara fun iranwọ, awọn aladugbo si sare jade si ile rẹ lati rana n lọwọ gba ọmọ rẹ pada lọwọ agbo awọn ọbọ naa.”
Eyi lo mu ki awọn ọbọ naa pẹlu fa ibinu yọ.
Ọgbẹni Manyama ni ọmọde jojolo naa fi ori ati ọrun ṣeṣe , ki o to jade laye lasiko to n gba itọju.
Ileesẹ ọlọpaa ti rọ awọn ewyan orilẹede naa lati kiyesara pẹl’awọn ọbọ ti wọn n rwkoja ni igbó ọba nibẹ.
Amọṣa, Ọgbẹni Manyama ṣalaye fun BBC pe lati bii ọdun mẹta ti oun ti n ṣiṣẹ lagbegbe naa, oun ko figba kan ri gbọ irufẹ iṣẹlẹ yii.
Awọn iṣẹlẹ nipa ikọlu awọn ẹranko nlanla bii erin lori ilẹ awọn ileto to wa lagbegbe awọn igbo ọba ti maa n waye tẹlẹ ri lorilẹede baa.










