Àwọn tó fẹ́ kí ààrẹ wá láti Ariwa ní 2023 fẹ́ mú gbogbo wa ní ọ̀bọ ni – Satguru Maharaj

Àkọlé fídíò, Sat Guru Maharaj sọ̀rọ̀ lórí ètò ìdìbò ọdún 2023
Àwọn tó fẹ́ kí ààrẹ wá láti Ariwa ní 2023 fẹ́ mú gbogbo wa ní ọ̀bọ ni – Satguru Maharaj
Satguru Maharaj

Oludari ijọ One Love Foundation, Satguru Maharaj, ti sọ pe ẹkun Gusu Naijiria ni ipo aarẹ kan lọdun 2023.

Ninu ifrọwanilẹnuwo kan to ṣe pẹlu BBC, Maharaj sọ pe awọn eeyan ẹkun Ariwa ti ṣe aarẹ fun saa meji, eyi to tumọ si pe Gusu lo yẹ ko tun bọ si gẹgẹ bi aṣa ni Naijriia.

Maharaj ni oun rọ gbogbo ọmọ Naijiria lati jade lọ dibo, amọ wọn gbọdọ mọ ẹni to yẹ lati dibo fun.

“Ko bojumu bi awọn to n du ipo aarẹ ṣe pọ, niṣe lo yẹ ki ipo naa bọ si Gusu, ti aarẹ to ba wọle yoo si yan igbakeji rẹ lati Ariwa.”

O sọ pe eyi wa ni ibamu pẹlu aṣa ni Naijria pe ki ipo aarẹ ma a lọ yika awọn ẹ̀kùn to wa.