Ibi tí Yorùbá ńfẹ́ kọ́ ni Adebanjo kọjú sí, ẹ̀yìn Tinubu ni Afenifere tò sí -Wale Oshun

Oshun, Tinubu ati Adebanjo

Oríṣun àwòrán, Others

Aṣiwaju ẹgbẹ ọmọbibi ilẹ Yoruba, Afenifere Renewal Group, Ọgbẹni Olawalu Oshun, ti sọ pe Bọla Tinubu lawọn n ṣe atilẹyin fun, kii ṣe Peter Obi ti ẹgbẹ oṣelu Labour Party.

Ṣaaju ni olori Afenifere, Oloye Ayo Adebanjo sọ nibi eto kan lọjọ Aje pe Obi ni ẹgbẹ naa n tilẹyin.

Ọgbẹni Oshun sọ fun BBC pe ohun ti Ẹgbẹ Afẹnifẹre Renewal Group duro ti ni ifẹ ọmọ Yoruba nile ati lẹyin odi, ti o si da awon loju pe ohun to ọgọrọ ọmọ Yoruba n fẹ naa ni ki ọmọ Yoruba to kun oju oṣuwọn o wọle sipo aarẹ.

O ni kii ṣe pe ẹgbẹ naa ko ni igbagbọ ninu iṣọkan Naijiria, ati wi pe boya awọn eeyan lati ẹya miran ko ni jade.

“Ohun to fa ipinnu wa lati duro ti ọmọ Yoruba laarin awọn to n dije bayii ko ju wi pe, oun lo kun oju oṣuwọn julọ ninu gbogbo oludije fun ipo aarẹ.

Ọgbẹni Oshun ni Bola Tinubu, ni awọn rii pe yoo lee yanju awọn ipenija ti o n doju kọ ọmọ Naijiria, leyi ti awọn si ti n fọnrere rẹ ṣaaju akoko yii.

 Ọrọ ti Afẹnifere sọ yii n fidi ohun ti agbẹnusọ fun ileeṣẹ ipolongo ibo Bola Tinubu, Bayọ Ọnanuga sọ pe ọrọ ara oloye Adebanjọ lo n sọkii ṣe ohun ti ẹgbẹ Afẹnifẹre n fe.

Ẹnìkan kìí jẹ kílẹ̀ ó fẹ̀, Peter Obi ni Afenifere n bá lọ dípò Tinubu - Adebanjo

Ayo Adebanjo

Oríṣun àwòrán, Other

Asiwaju ẹgbẹ Yoruba kan ti a mọ si Afẹnifẹre, Oloye Ayọ Adebanjọ ti ṣalaye idi ti ẹgbẹ naa ko fi fẹ ti oludije ẹgbẹ oṣelu APC, Bola Ahmed Tinubu tabi ti PDP Atiku Abubakar lẹyin fun ibo aarẹ Naijiria ti yoo waye lọdun 2023.

Asiwaju ẹgbẹ Afẹnifẹre, Oloye Ayọ Adebanjọ ṣalaye nibi apero kan to ṣe pẹl’awọn akọroyin pe iṣọkan ati ilana aparo kan ko ga ju ọkan lọ pẹlu idajọ ododo lti ẹgbẹ naa duro fun lo mu ko pinnu eyi.

Adebanjọ n fi apero naa fesi si ọrọ ti ileeṣẹ ipolongo idibo aarẹ fun Bola Ahmed Tinubu fi sita laipẹ yii ni ninu eyi to ti sọ ọ di mimọ pe iṣẹ ara oloye Adebanjọ lo n jẹ o ko jẹ iṣẹ ọmọ Yoruba lori Peter Obi to gbe ka ori.

Oludari eto ipolongo fun ileesẹ ipolongo ibo fun Bola Tinubu, Bayọ Ọnanuga ṣalaye bu ẹnu atẹ lu bi Ayọ Adebanjọ ṣe n ṣe atilẹyin fun Peter Obi ti ẹgbẹ oṣelu Labour.

Onanuga kọ ọ si oju opo Facebook rẹ pe lootọ Adebanjọ lẹtọ si fifi atilẹyin rẹ han fun oludije yoowu to ba wu u ṣugbọn iṣẹ ara rẹ lo n jẹ, ko yẹ ko wa maa lọ ifẹ ara rẹ mọ ẹgbẹ Afẹnifẹre lẹsẹ pe oun ti oun n fẹ naa ni ẹgbẹ ọhun pẹlu nfẹ.

Adebanjọ to fesi si eyi ṣalaye iwa aisi irẹjẹ ni Afẹnifẹre n fẹ to fi gbe ijoko joko si ẹyin Peter Obi gẹgẹ bi oludije to fẹ ti lẹyin.

O fi kun pe ilana iṣejọba apapọ tootọ ti oyinbo n pe ni Federalism ni Afẹnifẹre n fẹ.

Ayọ Adebanjọ ni lootọ ọpọ awọn aṣiwaju ilẹ Yoruba lo ti kọminu lori igbesẹ naa sugbọn ti oun ti la ọrọ naa ye ti oun si ti jẹ ki wọn mọ pe ilana ẹni kan kii jẹ ki ilẹ fẹ ti Action Group ti Awolowo da silẹ laye ọjọun duro le lori lawọn ṣi n tẹlẹ.