‘’A fẹ́ rí àwọn agbẹ́bọn tó kú nígbá tí ológun dóòlà arìnrìnàjò ojú irin tó kù’’

Kí ló dé tí ìjọba kò rí agbébọn kan mú nínú àwọn tó gbé ọgọ́ta èèyàn nínú rélùwéè? - HURIWA

Aworan

Ajọ ajafẹtọ lorilẹede Naijiria, HURIWA ti ke si aarẹ Muhammadu Buhari lati ṣafihan awọn agbesunmọmi to ku nigba ti ikọ ọmọogun Naijiria n doola ẹmi awọn arinrinajo mẹtalelogun to ku ni ahamọ awọn ajinigbe.

Ọjọ Kejidinlọgbọ, Oṣu Kẹta, ọdun 2022 ni awọn ajinigbe ṣe ikọlu si ọkọ oju irin naa, ti wọn si pa awọn eniyan, wọn si ji awọn miran gbe.

Adari Ajọ HURIWA , Comrade Emmanuel Onwubiko ni, o ṣe ni laanu pe awọn ọgọta eniyan ni awọn agbesunmọmi naa jigbe, ti ijọba si kọ lati mu ẹyọ agbesunmọmi ẹyọ kan lori ijinigbe naa.

‘’Bawo ni wọn ṣe doola ẹmi awọn mẹtalelogun naa, Ijọba Buhari gbọdọ da wa lohun ni kiakia’’

Onwubiko tẹsiwaju pe awọn ajinigbe yii ni wọn ti fi ọpọlọpọ eniyan sinu ibanujẹ fun oṣu mẹfa, lẹyin ti wọn pa ọpọlọpọ eniyan.

Ajọ naa ni dandan, ijọba ni ẹjọ lati ro nipa iṣẹlẹ ikọlu Kaduna ati awọn ti wọn jigbe.

Wọn ni ijọba n kan an ni ipa fun awọn eniyan pe awọn ko mọ nkankan nipa iṣẹlẹ naa.

Bakan naa ni HURIWA ni ki wọn ṣe igbẹjọ Tukur Mamu ti o jẹ ẹni to n duna-dura pẹlu awọn ajinigbe naa, to si wa ni panpẹ Ajọ eleto aabo, DSS.

‘’Amọ̀ iyalẹnu lo jẹ fun awọn ọmọ Naijiria nigba ti adari ajọ ti Buhari gbe kalẹ lori eto aabo, Usman Yusuf kede pe ijọba ti doola ẹmi awọn mẹtalelogun to ku to wa ni panpẹ wọn.’’

‘’Amọ ijọba ni idahun si awọn ibeere ọmọ Naijiria. Nibo ni Tukur Mamu wa? Nibo ni awọn agbesunmọmi yii wa lẹyin oṣu mẹfa?’’

‘’Bawo ni wọn ṣe doola ẹmi awọn mẹtalelogun naa? Ijọba Buhari gbọdọ da wa lohun ni kiakia’’

Ajọ HURIWA ni ki ijọba Buhari la awọn araalu lọyẹ lori ohun ti ko ye wọn lori bi wọn ṣe doola ẹmi awọn eniyan naa.

Ààrẹ Buhari ṣàbẹ̀wò sí èrò 23 reluwé tó gba ìtúsílẹ̀ lọ́wọ́ Boko Haram

Aarẹ Buhari ati aworan reluwe kan

Oríṣun àwòrán, nigeria presidency

Aarẹ Muhammadu Buhari ti ṣabẹwo si awọn ero mẹtalelogun ti awọn agbesunmọmi Boko Haram ji gbe lasiko ti wọn kọlu reluwe to n gbe wọn lati Abuja lọ si Kaduna.

Ni ileewosan ile ẹkọṣẹ ogun NDA to wa nilu Kaduna ni Aarẹ Buhari ti ṣabẹwo si awọn eeyan naa lọjọbọ lẹyin to ṣefilọlẹ awọn akẹkọọ iṣi kọkandinlaadọrin (cadets of 69 Regular course) ẹkọṣẹ ogun ojuomi, oriilẹ, ati ofurufu nile ẹkọṣe imọ nipa ogun jija NDA ni ilu Afaka nipinlẹ Kaduna.

Lasiko abẹwo naa, aarẹ orilẹede Naijiria kan sara si awọn ọmọogun Naijiria fun iṣẹ akin ti wọn n ṣe paapaajulọ eyi ti wọn fi ri awọn eeyan naa tu silẹ lọwọ awọn agbebọn Boko Haram.

Awọn ọmọ igbimọ alabẹṣekele ti olori ileeṣẹ ọmọogun lorilẹede Naijiria gbe kalẹ labẹ idari Ọgagunfẹyinti Usman Abdulkadir to ṣe kokari itusilẹ awọn eeyan mẹtalelogun naa pẹlu wa nibi abẹwo naa.

Èrò 23 tó kù lára àwọn tí Boko Haram jí gbé nínú reluwé Abuja sí Kaduna gba ìtúsílẹ̀

Reluwe kan

Gbogbo awọn ero inu ọkọ reluwe tawọn agbebọn ji gbe lojuna Abuja si Kaduna to ku ni ahamọ awọn ajinigbe naa ti gba itusilẹ bayii.

Ijọba orilẹede Naijiria lo kede eyi l’Ọjọru ninu atẹjade kan ti Ọjọgbọn Usman Yusuf to jẹ akọwe igbimọ kan ti ileṣẹ eto abo ni Naijiria gbe kalẹ ti wọn ni CDSAC.

“Mo layọ lati fi to gbogbo orilẹede yii ati agbaye leti pe ni nnkan bii agogo mẹrin irọlẹ Ọjọru, ọjọ karun oṣu kẹwaa ọdun 2022, igbimọ ẹlẹni meje kan ti olori awọn ẹṣọ oludaabobo arẹ, Ọgagun Leo Irabor ko sodi gba awọn ero mẹtalelogun to ku lahamọ awọn agbesunmọmi Boko Haram pada lẹyin ti wọn kọlu ọkọ reluwe to n rinrinajo lati Abuja lọ si Kaduna lọjọ kejidinlọgbọn oṣu kẹta ọdun 2022.

Atẹjade naa tun fi kun un pe” Orilẹede yii dupẹ pupọ lọwọ ileeṣẹ ọmọ ogun Naijiria labẹ idari ọgagun agba fun ileeṣẹ ọmọogun oriilẹ, to lewaju eto yii lati ibẹrẹ titi de opin. Lafikun, awọn ajọalaabo gbogbo ati ileeṣẹ igbokegbodo ọ̀kọ fun iranlọwọ wọn.”

Amọṣa, titi di asiko yii, ko si iroyin kankan nipa ibi ti wọn gbe awọn ero ti wọn tu silẹ naa lọ, tabi bi wọn ṣe tu wọn silẹ lọwọ awọn agbebọn Boko Haram to ti ji wọn gbe pamọ lati nnkan bii oṣu mẹfa