Ìdí tí a fi kéde àfikún owó osù àwọn òsìṣẹ́ rèé – Sanwo-Olu

Aworan

Oríṣun àwòrán, @jidesanwoolu

Gomina ipinlẹ Eko, Babajide Sanwo-olu ti kede afikun owo osu fun awọn oṣiṣẹ ni ipinlẹ naa.

Gomina Sanwo-Olu kede rẹ lasiko to n ṣe ipade pọ pẹlu awọn oṣiṣẹ ijọba ipinlẹ Eko ni ileeṣẹ ijọba ni Alausa.

O ni awọn gbe igbeṣẹ naa nitori ọwọngogo ounjẹ, to mu ki nkan le mọ awọn araalu.

Amọ gomina naa ko sọ bi afikun owo oṣu oṣiṣẹ naa yoo ṣe lọ ati ida ti wọn fẹ fikun owo osu wọn.

Skip X post, 1
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of X post, 1

‘’Ìdí tí a fí kédé àfikún owó osù àwọn osìṣẹ́ rèé’’

Ninu ọrọ rẹ, afikun owo osu oṣiṣẹ wa lọna, ijọba si ti bẹrẹ lati fi gbogbo eto si bi o ṣeye.

‘’A gbe igbeṣẹ yii lati mu aye rọrun fun awọn araalu nitori ọwọngogo to ba iye ti wọn n ra nkan ni ọja’’

‘’Bakan naa ni ile gbigbe ti wọngogo nipinlẹ eko, eleyii si ti mu aye nira fun awọn eniyan.’’

Bakan naa ni iroyin gbe e pe gomina ipinlẹ Eko sọ nibi ipade ajọ amuṣẹya ipinlẹ naa, pe oun ko fẹ ki awọn ẹgbẹ oṣiṣẹ bẹrẹ iyanṣelodi ki awọn to ṣe afikun owo osu oṣiṣẹ nipinlẹ naa.

Skip X post, 2
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of X post, 2

Amọ o fikun un pe kii sẹ ipinlẹ Eko nikan ni ọwọngogo yii ti n waye, to fi mọ gbogbo ibi ni agbaye ni.

Bakan naa ni gomina Sanwo-Olu ni pẹlu afikun naa awọn oṣiṣẹ yoo le ṣe iṣẹ wọn bi iṣẹ ki ipinlẹ Eko le tẹsiwaju.

Sanwo-Olu ni oun ti paṣẹ fun gbogbo awọn ti ọrọ kan lati sa ipa wọn ki afikun owo oṣu naa bẹrẹ ni kiakia.