Ifá ti mọ ẹni tí yóò jẹ ààrẹ Naìjíríà pẹ̀lú iyì àti ìdùnnú - Àdìmúlà Ila Orangun

Àkọlé fídíò, 2023 Elections: Agẹsin adimula Ila Orangun ní olóṣèlú kò gbọdọ̀ jẹ èèwọ̀ torí ẹ̀san
Ifá ti mọ ẹni tí yóò jẹ ààrẹ Naìjíríà pẹ̀lú iyì àti ìdùnnú - Àdìmúlà Ila Orangun

Agẹsin adimula Ila Orangun ní olóṣèlú kò gbọdọ̀ jẹ èèwọ̀ torí ẹ̀san

Fagbenle Adedayo

Awọn agba lo ni ohun to ba ruju, ka bi ilẹ leere, lara awọn ta si tun le bi leere ni Ifa Ẹlẹri ipin, atun ori ẹni ti ko sunwọn se.

Laipẹ yii si ni awọn Onisẹse nilu Ila Orangun se ọdun Ifa, idi si ree ti BBC Yoruba fi tọ wọn lọ lati beere nipa bi eto idibo ọdun 2023 yoo se lọ.

Nigba to n ba BBC Yoruba sọrọ, , Agẹsin Adimula ti Ila Orangun to tun jẹ igbakeji aarẹ fawọn ẹlẹsin ibilẹ nipinlẹ Osun, Oloye Fagbenle Adedayo sọrọ ilẹ kun.

Awa ko ni sọ ẹni ti yoo wọle ipo aarẹ amọ Ifa ti mọ onitọun - Adedayo

Ninu ọrọ rẹ, oloye Fagbele Adedayo ni awọn ko beere lọwọ Ifa nipa oludije aarẹ ti yoo wọle tabi ta ni ko ni wọle amọ ohun ti Ifa sọ ni pe gẹgẹ bii Babalawo, ko sẹni ti kii se ọmọ awọn.

O ni awọn ni awọn bi gbogbo awọn oloselu, wọn kan n jade sita ni, bi kii ba si se pe aye yipada, awọn araalu bẹ wọn nisẹ ni.

O ni wọn si gbọdọ jiyin isẹ iriju wọn pada nitori bo se yẹ ki ọrọ oselu ri niyẹn.

Fagbenle ni idi ree to se jẹ pe Babalawo to ba gbọn se gbọdọ fi ara rẹ sipo baba nitori o bi ọmọ to pọ lai yan ọkan nipọsin.

“Ifa ni awọn oloselu ko gbọdọ se ọkanjua tabi jẹ eewọ”

Fagbenle tẹsiwaju pe ohun ti babalawo gbọdọ se ni pe ko gbadura pe ẹni ti yoo bọ sibẹ, ti gbogbo nnka yoo fi dara, ni pe ko bọ sibẹ.

“Ifa wa ni awọn oloselu ko gbọdọ se ọkanjuwa lori ibo to n bọ nitori ẹni to ba se bẹẹ, yoo pada di ero ẹyin.

Iyẹn ni mo fẹ ki gbogbo awọn oloselu wa gbe dani, ki wọn ma se nnkan eewọ nitori nnkan eewọ ni ka maa yan ara wa jẹ.

Nnkan eewọ ni pe ki wọn ma fun Taye ni ohun to ba tọ si tabi ko ma se ododo ninu isẹ ilu ti wọn ba gbe le lọwọ.

Nnkan eewọ naa si ni ki wọn maa se egbe sẹyin awọn eeyan kan tabi ki wọn maa se ika nibi to yẹ ki wọn ti se rere nitori pe awọn eeyan to wa nibẹ kii se ọmọ ẹgbẹ wọn.

Wọn ko gbọdọ maa mu wọn lọ sẹwọn, tabi jo ile wọn tabi fi titi jẹ ile wọn,ara nnkan eewọ ni.

Ko si si ẹni ti yoo jẹ eewọ, ti ko ni ba eewọ rẹ nibẹ, eewọ naa pada jẹ oun atawọn ọmọ rẹ niyẹn.”

“Ifa ti mọ ẹni ti yoo jọ aarẹ amọ gẹgẹ bi baba fun gbogbo oloselu, a ko ni kede onitọun”

Nigba to n salaye fun BBC Yoruba nipa awọn nnkan miran ti Ifa sọ, Oloye Fagbenle Adedayo ni ohun Ikeji ti Ifa sọ ni pe ẹni ti yoo ba jẹ oye ilu ko gbọdọ pa eeyan tabi lo agidi.

“Ifa si ni ẹni ti yoo de ibẹ pẹlu Iyi, idunnu ati ẹyẹ ni yoo fi de ibẹ.

Ifa ti mọ onitọun amọ awa ko tii le sọ gẹgẹ bii baba gbogbo wọn."

Oloye Fagbenle wa gba awọn to n du ipo aarẹ nimọran pe ki wọn fi suuru si nitori ẹbi kan soso ni gbogbo wa, ko sibi ta fẹ lọ mọ, a ti di ọmọ Naijiria.

O ni o yẹ ki wọn jẹ ka fi ọpọlọ si, ka si fi ọpọlọ to o nitori ifa nikan ni ko mọ tara rẹ nikan.

Fagbenle ni Ifa kii sọ pe ẹlẹsin kan ni oun ko le ba se nitori naa, ki wọn j ka fi ika to ba tọ simu, ka fi re imu, ta ba si fi ọrọ ẹsin ati ti ẹya bọ oselu, Najiria yoo dara.