Ìjọ Kátólíkì gbé Mbaka kúrò lórí ìjọ, àwọn ọmọ ìjọ fárígá

Fada Mbaka atawọn ọmọ ijọ rẹ

Oríṣun àwòrán, Uncle IB

Awọn ọmọ ijọ Adoration Ministry nilu Enugu nipinlẹ Enugu ti ṣafihan atilẹyin wọn fun olori ijọ naa Fadá Ejike Mbaka, ti ijọ Katolikii Enugu gbe kuro lori ijọ naa.

Ifẹ́honuhan yii waye ninu ọgba ile ijọsin naa, ti awọn ọmọlẹyin Mbaka si ni igbesẹ ti Bisọọbu ijọ Katoliki Enugu, Callistus Onaga gbe ko tẹ awọn lọrun.

Pupọ ninu wọn lo ja ewe lọwọ, ti wọn si kọrin atilẹyin wọ inu ọgba ile ijọsin Fr Mbaka.

Orin muso muso, a ko ni gba ni o gbafẹfẹ kan amọ ki lohun to mu ki wọn ṣe iru atilẹyin yi fun olori wọn?

Ki si ni ẹsẹ Fada Mbaka ti wọn fi yọ nipo gẹgẹ adari ijọ Adoration Ministries?

Oṣu mẹta sẹyin ni wọn ti ti ijọ Adoration Ministries

Bisọọbu ijọ Katoliki Enugu, Callistus Onaga

Oríṣun àwòrán, Callistus Onaga

Bi ẹ ba ti n fọkan ba ọrọ ijọ Adoration Ministries bọ, ẹ o ranti pe oṣu mẹta sẹyin ni Biṣọọbu Onaga ti paṣẹ pe ki wọn ti ile ijọsin naa pa.

Eyi ko si sẹyin awọn ọrọ kan to sọ pe adari ijọ naa Fr Ejike Mbaka sọ.

Lọjọ Ẹti to kọja ni wọn ni ki wọn ṣi ile ijọsin naa pada.

Sugbọn iyalẹnu lo jẹ fawọn ọmọ ijọ Mbaka, nigba ti wọn gbọ pe Biṣọọbu Onaga ti yan Fr Anthony Amadi pe ko rọpo Mbaka.

Yatọ si yiyọ ati irọpọ Mbaka yii, Biṣọọbu Onaga naa tun gbe awọn ilana tuntun kan kalẹ nipa ijọsin ninu ijọ naa.

Ilana ijọsin tuntun ti ijọ Katoliki gbe kalẹ ni Adoration Ministries

Lara awọn ilana tuntun ti Bisọọbu agba fun ijọ Katoliki Enugu gbe kalẹ fun ijọsin ninu ijọ Adoration Ministries ree:

  • Ijọsin Ọjọru ati ọjọ Ẹti ko ni waye mọ
  • Ijọsin ''Mass'' ni ọjọ Aiku nikan ni yoo ma waye
  • Fr Mbaka ko ni kọ awọn ọmọ ijọ nibi ijọsin Mass mọ
  • Fr Mbaka yoo re irinajo ijọsin titi di igba ti Biṣọọbu yoo fi ni ko pada

Ko sẹni to mọ igba ti Mbaka yoo pada de lati irinajo yii tabi iye ọjọ ti yoo fi lọ.

Awọn ofin ati ilana tuntun yi lo n mu ki awọn alatilẹyin Mbaka maa faraya.

Iru rẹ ko ṣẹṣẹ maa waye

Fada Mbaka atawọn ọmọ ijọ rẹ

Fada Mbaka ko ṣẹṣẹ maa koju ipenija iru nkan bayi.

Losu Kẹfa ọdun 2022 ni Biṣọọbu Callistus paṣẹ pe ki ijọsin kankan mase waye ni ile ijọsin Adoration ti awọn ọmọ ijọ Mbaka si ṣe iwọde tako aṣẹ yi.

Lasiko iwọde yii, wọn sọ orisirisi ọrọ nipa Biṣọọbu Onaga, ti wọn si ni kii se Biṣọọbu tawọn.

Koda wọn se iwọde kaakiri Enugu ni, ti wọn si sọ pe awọn n wa Biṣọọbu Onaga nibikibi to ba wa.

Nigba naa lọhun, n ṣe ni iroyin gbode pe awọn kan ti ji Mbaka gbe tawọn mii si ni Onaga lo wa nidi ijinigbe naa.

Wọn ba ọpọ nkan jẹ ni ile Biṣọọbu ati ni ile ijọsin Holy Ghost Cathedral Enugu.

Mbaka pada yọju si wọn, to si pẹtu si wọn pe Biṣọọbu lo pa oun laṣẹ lati foju pamọ titi di igba toun yoo fi mọ ọrọ sọ daadaa.