"Ó ti di ènìyàn mẹ́tà tí ìwádìí ní ọ̀gá dókítà ní Kwara ti pa"

Oríṣun àwòrán, Kwara state Police
Iroyin to n kaakiri lori ẹrọ ayelujara safihan pe kii ṣe eniyan meji nikan ni Ọga agba dokita ni ipinlẹ Kwara, Adio Adeyẹmi Adebọwale ti ṣekupa.
Lẹyin iroyin to jade pe o ti wa ni atimọle ọlọpaa fun ẹsun ṣiṣekupa ọrẹbinrin rẹ, Ifeoluwa ati arabinrin Nọfisat Halidu ti wọn jọ wa ni ilu Kaiama, ni ipinlẹ Kwara.
Ifeoluwa ni wọn ni wọn jọ lọ si ibi igbafẹ, ko to di wi pe o gbẹmi rẹ.
‘’Bi Dokita ṣe gbẹmi ọrẹ rẹ, oni kabukabu ree’’
Dokita Adeyemi Adebowale ni wọn fi panpẹ ọlọpaa mu pe o gun ọrẹ rẹ ni abẹrẹ pa, to si gbe oku rẹ lọ si inu igbo, ko to gbe ọkọ rẹ salọ.
Ọkunrin oni kabukabu naa lo n sisẹ ni ilu Benin, ti orukọ rẹ si n jẹ Emmanuel Agbonvinuesr.
Iroyin ni Oṣu Keje, ọdun yii ni awọn mejeeji kọkọ pade, nibi ti dokita naa ti gba ọkunrin naa gẹgẹ bi awakọ rẹ.
Alukoro ọlọpaa to fi idi isẹlẹ naa mulẹ, Chidi Nwabuzor ni lẹnu iṣẹ rẹ ni awọn mejeeji ti di ọrẹ timọtimọ.
"Abẹrẹ ní dokita gun onikabukabu ni ẹṣẹ, to si gba ibẹ lọ"
Ni Ọjọ Kẹta, Oṣu Kẹsan, ọdun 2022 ni afurasi naa pada wa si ilu Benin to si pe arakunrin Emmanuel pe ko wa ba oun ni ile itura miran, lati wa gbe lọ si ibi to ba fẹ lọ.
Lẹyin naa ni onikabukabu naa gbe kaakiri awọn ibi to fẹ lọ, to si n kigbe ẹṣẹ didun lẹyin naa.
Dokita ọhun ṣeleri lati ran an lọwọ fun tọju ẹṣẹ naa, to si gun ni abẹrẹ, ti onikabukabu naa si ku lẹṣẹkẹṣẹ.
Lọna ati bo iwa buruku rẹ mọlẹ, afurasi naa gbe oku onikabukabu naa sinu ọkọ rẹ, to si lọ juu sinu igbo.
Lẹyin naa lo salọ pẹlu ọkọ arakunrin naa.
‘’Ọrẹ mi ni mo pa, a ṣiṣe ni, mi o mọọmọ ṣe’’
Ileesẹ ọlọpaa no Dokita afurasi apaayan yii sa lọ silu Osogbo, ibi to salọ si ni wọn ti gbaa mu.
Bakan naa ni wọn si tun ri ọkọ miran gba lọwọ rẹ, to ti ta fun awọn to n ṣe kara-kata ọkọ.
Ninu ọrọ rẹ, Dokita naa bẹbẹ fun idariji ẹṣẹ lọwọ awọn ẹbi ọkunrin onikabukabu naa.
‘’Mi o mọọmọ pa, o ṣeesi waye ni, ọrẹ mi ni arakunrin yii.’’
‘’Dokita ni mi fun ọpọlọpọ ọdun, ti mo si ti doola ẹmi awọn eniyan fun aimọye ọdun’’
‘’To ba ni ohun ti mo le ṣe lati da ẹmi rẹ pada, maa ṣe nitori ọrẹ mi ni, ọpọlọpọ igba ni a ma n sọrọ.
‘’Ko si ohun ti mi o le ṣe lati fi da ẹmi rẹ pada, ka ni o ṣeeṣe fun mi lati da emi rẹ pada’’
‘’Mi o fẹ paa, o seesi ni’’
Ọlọ́pàá bá òkú obìnrin méjì nínú agolo ìdọ̀tí, sàréè pàjáwìrì lọ́físì dókìtà kan ní Kwara

Oríṣun àwòrán, police kwara
Saaju la ti mu iroyin wa fun yin pe wọn ti ri oku arabinrin kan, Nofisat Halidu to sọnu nilu Kaiama nipinlẹ Kwara ni ọfiisi dokita iṣegun oyinbo kan, Adio Adeyẹmi Adebọwale ninu saree pajawiri to gbẹ si ọfisi rẹ.
Ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Kwara ṣalaye pe Dokita Adio Adeyẹmi Adebọwale ti a n ọrọ rẹ yii wa ni ahamọ awọn ọlọpaa nipinlẹ Edo nibi ti o ti n foju wina ofin fun ṣiṣeku pa ọrẹbinrin rẹ.
Dokita Adio Ọdẹbọwale jẹwọ fun awọn ọlọpaa ni ipinlẹ Edo pe oun loun pa ọrẹbinrin oun ti orukọ rẹ n jẹ Ifẹoluwa ti wọn n wa kiri lagbegbe Tanke nilu Ilọrin lọdun 2021. O ni inu igbo kan lagbegbe Alapa nilu Ilọrin kan naa ni oun ju oku rẹ si nibi ti wọn ti rii.
Ijẹwọ Dokita Adio yii, ti wọn ni o tun jẹ dokita agba ni ileewosan ijọba to wa nilu Kaiama, lo mu ki kọmiṣọna ọlọpaa nipinlẹ Kwara o pe fun iwadii iroyin sisọnu Nọfisat Halidu niwọn igba to jẹ pe ilu Kaiama yii kan naa ni.
Iwadii yii lo mu awọn ọlọpaa lọ si ọfiisi rẹ ti wọn si fi tipatikuuku ja lẹkun rẹ wọle ti wọn si fura si ilẹ inu ọfiisi naa pẹlu ibi kan ti wọn ri oju pe wọn ṣẹṣẹ rẹ nibẹ.
Awọn ọlọpaa ọtẹlẹmuyẹ to lọwu ilẹ ọfiisi yii nibi ti wọn ti ri oku arabinrin kan to n jẹra ninu saree pajawiri kan nibẹ.

Oríṣun àwòrán, kwara police
Nigba ti wọn tun tu ọfisi dokita Adio Ọdẹbọwale wo daadaa, wọn tun ba oku arabinrin kan ninu agolo idalẹnusi kan nibẹ. Ayẹwo oku inu agolo idalẹnusi yii ni wọn ri pe o jẹ ti arabinrin Nofisatu Halidu ti ọkọ rẹ, Halidu funrarẹ si fidi rẹ mulẹ pe iyawo oun ni.
Lara awọn ohun miran ti wọn ti wọn ba ninu ọfiisi rẹ nileewosan nla ti ijọba to wa nilu Kaiama ni ẹrọ ibanisọrọ meji to wa ninu apo ilewọ awọn obinrin naa, apo ilewọ meji, irun igbalode wiigi obinrin kan, iboju kan atawọn pata obinrin.
Gẹgẹ bi atẹjade kan ti alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ni ipinlẹ Kwara, Ajayi Okesanmi ṣe sọ, kọmiṣọna ọlọpaa nipinlẹ Kwara ti kan si ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Edo pe ki wọn jọwọ afurasi naa fun awọn nitori pe o ni ibeere pupọ lati dahun lori awọn ohun ti wọn ba ninu ọfiisi rẹ.












