Nàíjíríà tóbi jù fún ìjọba àpapọ̀ láti darí, ẹ jẹ́ kí kálukú darí ẹkùn tiẹ̀ - Ladoja

Àkọlé fídíò, Rasheed Ladoja: Buhari kùnà láti ṣe àmúṣẹ ìlérí tó ṣe, kò tún le è rẹ́yìn Boko Haram
Nàíjíríà tóbi jù fún ìjọba àpapọ̀ láti darí, ẹ jẹ́ kí kálukú darí ẹkùn tiẹ̀ - Ladoja

Rasheed Ladoja: Buhari kùnà láti ṣe àmúṣẹ ìlérí tó ṣe, kò tún rẹ́yìn Boko Haram

Rasheed Ladoja

Awọn agba lo ni agba kii wa lọja, kori ọmọ tuntun wọ, nitori agba ti ko ba kẹun sọrọ, yoo kẹ itan sare.

Ba ti n se ayajọ ọdun Kejilelọgta ti ilẹ wa Naijiria gba ominira, gomina tẹlẹ nipinlẹ Oyo, to tun jẹ Ọtun Olubadan tilẹ Ibadan, Agba Oye Rasheed Adewolu Ladoja ti sọrọ soke lori awọn isẹlẹ to n waye lorilẹede yii.

Ladoja, to tun jẹ Sẹnatọ ni Naijiria lo ba BBC Yoruba sọrọ lasiko ajọdun ominira naa, eyi to tun se pẹki n pẹki pẹlu ayẹyẹ ọjọ ibi ọdun kejidinlọgọrin rẹ loke eepẹ ati bi gomina Seyi Makinde se fi opopona olobiripo nilẹ Ibadan sọri rẹ.

Ladoja, lasiko to n wo sakun ibi ti nnkan bajẹ de lorilede yii ni a ko le di ẹbi akude to wọ ilẹ yii ru ero awọn eeyan kan to ni Naijiria tete gba ominira lọwọ awọn eebo amunisin, lo sokunfa ipo ẹyin ta ba ara wa.

Buhari kuna lati se amusẹ ileri ipolongo ibo rẹ - Ladoja

Ninu ọrọ rẹ, Rasheed Ladoja ni o se ni laanu pe ọpọ ileri ti aarẹ Muhammadu Buhari se fun wa lasiko to n polongo ibo, lo ti kuna.

O ni ọga ologun ni Buhari, to si seleri pe laarin osu mẹfa, oun yoo rẹyin awọn ikọ afẹjẹwẹ Boko Haram, eyi ti ko ri bẹẹ.

Ladoja ni ilu ko fara rọ, gbogbo eeyan lo n pariwo, ti ko si sowo lati na, bẹẹ ni eto aabo to mẹhẹ n ba wa finra.

O fikun pe ọpọ agbẹ ni ko le lọ soko, tawọn eeyan ko si tun le peju se ijọsin, ti hilahilo si ba gbogbo ilu eyi to ni o tako awọn ileri ti Buhari se ko to de ipo aarẹ.

“Ki kaluku se akoso ẹkun rẹ lo dara, Naijiria ti tobi ju fun ijọba apapọ lati sakoso rẹ”

Agba oye nilẹ Ibadan naa tẹsiwaju pe awọn ẹkun to wa ni Naijiria lo n pariwo, awọn ẹlẹgbẹjẹgbẹ ajijagbara si n dide ni ẹkun wọn.

“Biafra, Niger Delta, Yoruba Nation, Awọn agbebọn ati darandaran Fulani lo n fẹ pinya kuro ni Naijiria, o si dabi ẹni pe orilede yii ti tobi ju fun ijọba apapọ lati mojuto.

Bi ọrọ ba ti wa da bayii, boya ki kaluku maa dari ẹkun rẹ ati ipese eto aabo nibẹ.”

Ladoja tun wa koro oju si bi ijọba apapọ se fun ijọba ipinlẹ Katsina lasẹ pe kawọn ẹsọ alaabo abẹle rẹ maa lo ibọn atamase Ak-47, to si fun Amotekun laaye lati lo ibọn sakabula lasan.

Àkọlé fídíò, Ladoja: Àwọn èèyàn Oyo fì ìbò sọ̀rọ̀ pé ìjọba Ajimobi kò dára

“Bi ologun ko ba gba ijọba nibẹrẹ pẹpẹ ta gba ominira, ibi ta wa yii kọ ni a ba wa”

Ọtun Olubadan wa fikun pe ẹbi ipo ẹyin ti Naijiria wa yii lo yẹ ka di le awọn ologun to wa ja ijọba gba mawọn alagbada lọwọ ni kete ta gba ominira tan.

“Awọn adari wa to ni nnkan gidi se nile aye lo n dari wa nigba naa, amọ awọn ologun to ja ijọba gba lọwọ wọn lo da isejọba ẹlẹkunjẹkun ru.

Awọn lo wa se agbekalẹ isejọba alajumọse, eyi to mu ka wa nibi ta wa lonii yii.

Ala ta n la nipa Naijiria kọ niyi rara nitori o y ka ti maa lọ sinu osupa, ti ko si yẹ ki nnkan ti ko to nnkan maa yọ wa lẹnu bayii.

A ko ba si ti lọ jinna, to ba jẹ pe wọn fi adugbo kọkan sil lati maa se ijọba ara rẹ ni.”

“Owo tawọn asofin apapọ n gba ti pọju, yoo dara ki wọn sọ isẹ wọn di Part-Time”

Sẹnatọ Ladoja tun woye pe kii se ilana isejọba awa ara wa lo buru bikose ọna tawa n gba se nilẹ yii.

O ni owo ta n na sori isejọba alagbada ti pọju pupọ, paapaa owo awọn asofin apapọ ati tawọn asoju sofin.

Ladoja ni kii se owo ti wọn kọ sinu iwe ni awọn asofin naa n gba, amọ wọn ni owo tuulu ti wọn n gba lọtọ.

O wa daba pe ki wọn sọ isẹ awọn asofin di ìdàbọ̀, ta mọ si Part-time nitori ko si ohun ti wọn n jiroro le lori ju ofin sise lọ.

Àkọlé fídíò, Rashidi Ladoja: Kí Bùhárí gbé àpótí ìbò wò, bóyá yóò borí