Ilé tó dàwó ń sọ̀kò, òpó ilé sì yẹ̀, kílé tó wó lulẹ̀ láago méjì òru - Óṣojúmìikòró

Ile alaja mẹta kan ti dawo niluu Ibadan, nibi ti awọn ọja ati dukia ti iye rẹ to ọpọlọpọ miliọnu naira ti ṣofo.
Agbegbe Ashi, ni Bodija, ni iṣẹlẹ laabi naa ti waye ni afẹmọju ọjọ Aje.
Akọroyin BBC Yoruba to ṣabẹwo si adugbo naa jabọ pe nnkan bii aago meji oru ni ile naa dawo.
Ile naa n sọ̀kò, mo si ro pe awọn ọlọpaa ni - osojumikoro
Ọkan lara awọn eeyan adugbo ti ile naa ti waye, to tun jẹ ẹṣọ alaabo nibẹ, Olusegun Adeagbo, ṣalaye fun BBC Yoruba pe nnkan bii aago mẹwa alẹ ni ile naa bẹrẹ si ni ṣapẹrẹ pe o fẹ dawo.
O ni “Nnkan bii aago mẹwaa lo bẹrẹ, mo kọkọ ri ti òpó to gbe ile naa ro bẹrẹ si ni sọko, mo wa ro pe awọn ọlọpaa lo wa.”
“Mo tan ina wo oke, mo wa ri pe opo to gbe ile naa ro n ṣi, mo wa lọ ji ẹṣọ to n ṣo ile naa nitori kii ṣe ilegbe ni.”
“Bi mo ṣe ji ẹṣọ naa tan ni ile ọhun wo.”
Adeagbo sọ pe ọja ti iye rẹ to ẹgbẹlẹgbẹ miliọnu naira ni wọn n ta nibẹ.
Gẹgẹ bii ohun to sọ, gbogbo nnkan to wa ninu ile naa lo bajẹ tan yanyan.
O ni “Nnkan to bajẹ ninu ile naa yoo to ọgọrun miliọnu naira.”

"Inu ibanujẹ ni awọn to ni dukia naa wa"
Iya agba kan to n gbe lẹba ile naa, Sherifat Lateef, ṣalaye fun BBC Yoruba pe bi ọrọ ṣe jẹ gan ni Adeagbo sọ ṣaaju.
O ni ṣọọbu, ọọfisi ati ile itaja igbalode lo wa nibẹ.
Lara awọn nnkan ti iya agba ọhun sọ pe wọn n ta ninu ile ọhun ni oogun oyinbo, nnkan awọn oloyun atawọn ọmọde, ile itaja igbalode, ọọfisi ati bẹẹ bẹẹ lọ.
Yatọ sawọn dukia ati ọja to ba iṣẹlẹ naa lọ, ile ọhun tun wo lu ọkọ ayọkẹlẹ kan to wa lẹba rẹ mọlẹ.
Amọ ko si ẹmi ẹnikankan to ba iṣẹlẹ ọhun lọ.
Titi di akoko ti a n ko iroyin yii jọ, ko si ẹni to le sọ ohun to mu ki ile naa dawo.















