N kò gbé ìròyìn òfegè, lóòtọ́ ní agbábọ́ọ̀lù kú ní Lekki – Ọlọ́pàá Eko

Agbabọọlu to ku ati alukoro ọlọpaa Eko

Oríṣun àwòrán, Screenshot

Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Eko, Benjamin Hundeyin ti fesi fun awọn to n bu ẹnu atẹ lu lori ẹrọ ayelujara.

Eyi ko ṣẹyin bi Hundeyin ṣe fi si ori ẹrọ ayelujara pe agbabọọlu kan ku si ori papa iṣere bọọlu ni Lekki.

Loju opo Twitter naa lo ti rọ awọn eniyan lati tọju ilera ara wọn, ki wọn si maa ṣe ayẹwo ni oorekoore, ti ko si fi ẹkunrẹrẹ iroyin naa lede.

Amọ ọpọlọpọ eniyan bẹrẹ si ni bu ẹnu atẹ lu u lẹyin ti Arakunrin kan lori Twitter, Muruako E ni irọ ni Benjamin n pa fun awọn ara ilu nitori China ni iṣẹlẹ naa ti waye.

O ni akẹkọọ to ni aisan ọkan lojiji, to si gba ibẹ lọ, eleyii to jẹ ibanujẹ fun ọpọlọpọ eniyan.

Amọ ninu esi rẹ, Hundeyin sọ fun awọn akọroyin pe kii ṣe iroyin ofege ni iṣẹlẹ naa nitori o ṣẹlẹ lootọ, ti ẹni to ṣe alaisi naa si wa ni ile igbokusi.

O ni oun sọrọ gẹgẹ bi agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa nitori iṣẹlẹ naa waye.

‘’ Iroyin ti mo kede ko ni fidio ninu, awọn akọroyin ofege lo fi fidio iṣẹlẹ ti China sibẹ ’’

Hundeyin tẹsiwaju pe ’Amọ mi o le tu iṣu de isalẹ ikoko nitori awọn mọlẹbi ko fẹ iroyin naa ni ita gbangba.’’

Bakan naa, loju opo Twitter rẹ lo ti ni awọn oniroyin ofege lo gbe iroyin ti oun fi lede lai fi fidio si.

‘’Wọn lọ gbe fidio si, ti wọn si ni Lekki lo ti ṣẹlẹ’’

‘’Awọn gan an ni oniroyin ofege, iroyin ti mo fi lede waye ni ọjọ mẹta ṣẹyin.’’

Skip X post, 1
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of X post, 1

Ogbọnjọ Osu Kẹsan ni iṣẹlẹ naa waye ni riolẹ ọjọ naa ni papa iṣere Greenfield Football Ground ni Lekki.

Lẹyin to subu naa ni wọn gbe lọ si ileewosan Evercare ni Lekki nibi ti dokita to wa ni ẹnu iṣẹ ti ni arakunrin naa ti dagbere fun aye, ti wọn si gbe lọ si ile igbokusi ti ijọba.

Awuyewuye bẹ̀rẹ̀ láàrin aráàlú àti ọlọ́pàá nípa agbábọ́ọ́lù tó kú sórí pápá

Footballer dies of cardiac arrest

Oríṣun àwòrán, @YouthspireNG

Alukoro fun ileesẹ ọlọpaa nipinlẹ Eko, Benjamin Hundeyin ti kede iku ọdọkunrin ẹni ọdun mọkanlelọgbọn kan.

Ọkunrin naa lo jade laye lẹyin to ṣubu lulẹ nibi to ti n gba bọọlu lori papa.

Agbẹnusọ fun ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko ninu ikede to gbe soju opo Twitter rẹ sọ pe agbegbe Lekki, niluu Eko ni iṣẹlẹ naa ti waye.

Ninu atẹjade ti agbẹnusọ ileeṣẹ naa, Benjamin Hundeyin fi lede, o ni ẹni ọdun mọkanlelọgbọn ni oloogbe naa ko to jade laye.

O wa rọ awọn araalu lati maa fun ara wọn ni isinmi, ki wọn si maa kiyesi ilera ara wọn, paapaa lasiko ti wọn ba n ṣe ere idaraya.

Bi o tilẹ jẹ pe alukoro ileesẹ ọlọpaa Eko ko fi aworan tabi fidio bi oloogbe naa se ku han fun araaye amọ ọpọ eeyan ti ta ko ikede rẹ naa.

Skip X post, 2
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of X post, 2

Ọlọpaa, China ni isẹlẹ naa ti waye, kii se ilu Eko - Araalu fesi fun Hundeyin

Ẹwẹ, Aawọn eeyan to fesi lori isẹlẹ yii sọ pe Hundeyin ko se iwadii to yẹ bii ọga ọlọpaa, ko to maa gbe ikede naa sita, to si n fun araalu ni iroyin eke gbọ.

Awọn eeyan kan ti wọn mọ nipa iṣẹlẹ naa ti ni kii ṣe ilu Eko ni iṣẹlẹ naa ti waye.

Koda wọn ni ọkunrin naa kii ṣe ẹni ọdun mọkanlelọgbọn gẹgẹ bii nnkan ti ọlọpaa sọ.

Gẹgẹ bi esi ti wọn n fun Hundeyin loju opo Twitter rẹ, wọn ni orilẹ-ede China ni iṣẹlẹ ọhun ti waye, ati pe ọmọ ọdun mẹtalelogun ni oloogbe naa.

Wọn wa fi ewe ọmọ mọ alukoro ileesẹ ọlọpaa leti pe ko dẹkun gbigbe iroyin eke sita.

Skip X post, 3
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of X post, 3

Bawo ni isẹlẹ naa se jẹ gan?

Ninu fidio ẹrọ ayaworan CCTV papa iṣere ti wọn ti n gba bọọlu naa, ṣe ni ọkunrin ọhun ti orukọ rẹ n jẹ Kosi, ti ọpọ awọn akẹgbẹ rẹ n pe ni Kizzy, ṣadede subu, to si gba ibẹ lọ.

Lẹyin to ṣubu tan, awọn kan lara awọn ọrẹ rẹ ti wọn jọ n gba bọọlu lero pe ṣe lo n da apara.

Ọkan ninu wọn tilẹ n sọ pe ki wọn fi silẹ nitori ere lo n ṣe, ọkan ninu wọn ni “Ẹ ma naani ọkunrin yii jare, ere lo n ṣe” nigba ti omiran si n sọ fun pe “Ere ti o n ṣe ti to jare.”

Bakan naa ni omiran ni oun yoo fun ni ọti ko le dide, amọ lẹyin iṣẹju diẹ ti ko dide ni wọn to mọ pe ọrọ naa ti kọja ohun ti wọn n lero.

Iroyin ni nigba ti wọn yoo fi gbe de ileewosan, o ti dakẹ.