"Mo fi páálí ṣe kàtúùnù, rọ́bọ́ọ̀tì, tó ń rìn, mo gba ẹ̀bùn ẹkọ́ ọ̀fẹ́"

Ọdọmọdekunrin kan, Isah Barde ti fakọyọ lẹyin to ṣe ‘catoon’ to n rin ni ilu Kano, ni ariwa orilẹede Nigeria.
Barde to jẹ ẹni ọdun mẹtadinlogun, lo ti bẹrẹ cartoon naa lati ọdun 2020 lasiko ti ajakalẹ aarun Coronavirus gbode kan.
Ṣise cartoon pẹlu paali naa lo gbe Isah, to jẹ akẹkọọ onipele kini ni fasiti, di ilumọọka lori ẹrọ ayelujara.
Lasiko to n ba akọroyin BBC sọrọ, Barde ni lati kekere loun ti fẹran ati maa dara tuntun pẹlu ẹrọ katakata ati Esikafetọ, ko to di pe oun bọ si ori rọbọọti.
Isah gba ẹbun ẹkọ ọfẹ lọwọ ijọba Naijiria
Isah to wa ni girama ni asiko naa loni inu fiimu ati fidio ti oun ma n wo o, ti oun si ti kọ lati maa ṣe rọbọọti.
Otitọ ibẹ ni pe ko si ẹni to kọ mi lati sẹ rọbọọti , mo ma n wo fiimu bi wọn ṣe n rin, ni mo bẹrẹ si ni ṣe ti temi naa.
Nibayii, Isah ti gba ẹbun ẹkọ ọfẹ lọwọ ijọba Naijiria lati lọ kọ ẹkọ imọ ẹrọ ni fasiti Baze University ni ilu Abuja.
Ninu ọrọ rẹ, Isah ni awọn nkan ti a le ri ni ayika wa ni ojoojumọ.

''Ọdun meji ni mo fi se katuunu to n rin naa''
‘’Awọn ohun ti mo lo lati fi se cartoon naa ni paali, biro, igo ti awọn nkan ti a le ri ni ayika wa.’’
‘’Amọ awọn ohun ti mo ra ni ọja ni DC Motors.’’
‘’DC Motors ohun lo won ju ninu awọn nkan ti mo ra, to si jẹ ẹẹdẹgbẹta naira, ti mo si lo mẹfa.’’
‘’Nibayii, cartoon naa le se ohun ti mo ba se, ti mo ba gbe ọwọ si oke, cartoon naa yoo gbe ọwọ rẹ soke naa.’’
O ni oun pari cartoon naa ni aarin ọdun meji, eleyii to mu ki ajọ NITDA fun ni ẹbun iwe ọfẹ lọ si fasiti.
''Mo ni awọn ipenija lọgọọrọ''

Isah ninu ọrọ rẹ ni awọn ipenija ti oun koju ni lati ri awọn ohun elo ti oun nilo fun ṣiṣe katuunu naa.
Bakan naa lo ni ipenija ni o jẹ fun oun ni ibẹrẹ nigba ti awọn eniyan ko gba oun gbọ pe oun le ṣe nkan rere bẹẹ.
‘’Igba ti mo ṣe tan ni wọn ṣẹṣẹ n gboriyin fun mi.
Ohun ti eleyii kọ mi ni ni pe ohun ti eniyan ba fẹ ṣe, o gbọdọ fi tọkantọkan ṣe lai wo ẹyin.
Ki eniyan ma si fi ọkan si ohun ti eniyan n sọ tako iṣẹ to n ṣe.’’
‘’Mo ṣẹṣẹ bẹrẹ ni’’

Isah ninu ọrọ rẹ oun ṣẹṣẹ bẹrẹ ni,ti oun yoo si ṣe nkan nla nipa robọọti.
‘’Mo ṣẹṣẹ bẹrẹ ni, erongba mi ni lati ṣe ẹrọ igbalode ti wọn n pe ni artificial intelligence robot, eleyii ti yoo ma ṣe bi eniyan lai si remoter control ti yoo ma dari rẹ.’’
Bakan naa lo dupẹ lọwọ awọn obi rẹ to ṣe atilẹyin fun, ti wọn si jẹ ko ṣe ohun to wu ni ọkan lati ṣe.















