Man U tún gbà àlejò ọ̀ràn, Arsenal rìn àrìnfẹsẹ̀si nínú ìdíje EFL

Aworan ẹgbẹ agbabọọlu Man Utd, Chelsea àti Arsenal

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Alubami iya to waye lana fun ẹgbẹ agbabọọlu Arsenal ati Manchester United ninu idije English Football League.

Ikọ Westham lo rọ ojo iya le Arsenal lori pẹlu ami ayo mẹta sì eyọkan.

Mohammed Kudus, ọmọ orilẹede Ghana ati Jarrod Bowen lo fọwọsowọpọ ṣe kini yẹn fun ikọ Arsenal.

Odegaard lo mi ami eyo kan fun Ikọ Arsenal ninu ìfẹsẹwọnsẹ to waye ni London Stadium.

Bakan naa ni ikọ Newcastle wọle lọ ba Man Utd ni paapa Old Trafford, ti wọn si gba ile mọ wọn lọwọ.

Ami ayo mẹta sodo ni Ikọ Newcastle fi gba ẹwu lọrun Man Utd.

M.Almiron, L. Hall ati J Wilock lo mi awọn fun ikọ Newcastle ninu ìfẹsẹwọnsẹ naa.

Bayii ikọ Arsenal ati Manchester United ti ja kuro ninu idije English Football League.

Chelsea fakọyọ, Blackburn sa asala fun emi rẹ.

Aworan ẹgbẹ agbabọọlu Chelsea

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ikọ Chelsea kọ lati jẹ ki ọrọ ọta ṣe mọ wọn lara, ti wọn si fi ya jẹ ikọ Blackburn Rover ni paapa Stamford Bridge.

Ọsẹ to kọja ni Brentford fi ya Chelsea mọle pẹlu ami ayo meji sodo, ti Blackburn naa si sare wa boya ẹkọ yoo soju mumu fun wọn

Ṣugbọn Chelsea yara, ti wọn si ọbẹ ẹyin jẹ wọn ní ìṣu.

Ifẹsẹwonsẹ naa pari pẹlu ami meji sodo. B. Badiashile ati R. Sterling lọ mi awọn fun ikọ Chelsea.

Bi awọn ifẹsẹwonsẹ yooku ṣe lọ ree

Bournemouth 1 vs 2 Liverpool

Everton 3 vs 0 Burnley

Ipswich Town 1 vs 3 Fulham

Manchester United 0 vs 3 Newcastle

Chelsea 2 vs 0 Blackburn Rovers

Westham 3 vs 1 Arsenal