Ète láti yọ Gómìnà ipinlẹ Rivers: Orọ̀ mọ̀lẹ́bí tá a máa yanjú lábẹ́lé ni- Wike

NYESOM WIKE

Oríṣun àwòrán, @WIKE

Nyesom Wike, Minisita fun Olu ilu Naijiria ti sọ ọ di mimọ pe rogbodiyan oṣelu to n ṣẹlẹ nipinlẹ Rivers ko le rara, o ni ọrọ mọlẹbi tawọn yoo pari labẹle ni.

Ilu Abuja ni Wike ti sọrọ yii lasiko to gba awọn olori kan lati Guusu-Guusu lalejo lọfiisi rẹ.

Ọjọ Aje ọsẹ yii, Mọnde ọgbọnjọ oṣu kẹwaa ọdun 2023 ni awọn ọmọ ile igbimọ aṣofin ipinlẹ Rivers kan pete ati yọ gomina ipinlẹ naa, Siminialayi Fubara, nipo, lẹyin tawọn janduku kan lọọ dana sun gbọngan pataki ti awọn aṣofin n lo fun ipade wọn nile igbimọ naa, eyi to mu kawon eeyan fẹhonu han to si di rogbodiyan nipinlẹ yii.

Iṣẹlẹ yii ni Wike toun naa jẹ gomina ana nipinlẹ Rivers dahun si, to ni rogbodiyan oṣelu lohun to ṣẹlẹ, ki i ‘se ti ẹlẹyamẹya bawọn eeyan kan ṣe n gbe e kiri.

" O yẹ ka beere alaye lati mọ ohun to ṣẹlẹ to gbe wa debi ta a bara wa yii ni, iyẹn lo maa jẹ ka mọ otitọ. Ẹgbẹ wa ti n woye iṣẹlẹ naa, ohun ti mo maa sọ nipa ẹ niyẹn, ṣugbọn ki gbogbo wa lọọ mọ pe ẹyọkan naa ni gbogbo wa. " Bẹẹ ni Wike wi.

O pẹ ti ọpọ eeyan ti n sọ pe ija oṣelu n ṣẹlẹ laarin Wike ati Gomina Siminalayi Fubara, ati pe ija igba nija ọhun, eyi ni wọn lo fa a ti aarin awọn mejeeji ko fi gun mọ tipẹ, bẹẹ lawọn mi-in n sọ pe ohun to n faja wọn naa ko tilẹ ye ẹnikẹni.

Kini o ti ṣẹlẹ tẹlẹ?

Nigba ti igbiyanju lati yọ Gomina Fubara nipo waye laipẹ yii, ọpọ eeyan lo n nawọ aleebu si Nyesom Wike, wọn ni Minisita fun ọrọ Olu ilu ilẹ wa l’Abuja naa mọ nipa ète lati yọ gomina yii nipo.

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Lara awọn to ni Wike lọwọ ninu ọtẹ naa ni Oloye Edwin Clark. Agba oṣelu to wa lati Niger Delta naa sọ pe Wike lọwọ ninu bi wọn ṣe fẹẹ yọ Fubara to wa lati apa ibi ti omi pọ si daadaa nipinlẹ Rivers kuro nipo gomina. Ṣugbọn Wike ni ko si otitọ ninu ohun ti baba agba naa sọ. O ni ọrọ oṣelu lo wa nilẹ, ko kan ti ẹlẹyamẹya rara.

Wike sọ pe, " Nigba to ba n bọ si wa lọwọ lawọn eeyan maa n gba pe eeyan daadaa ni wa, to ba ti ku diẹ kaato, ti nnkan ko ja mọ wa lọwọ mọ wọn aa ni a ko daa ni.

Ọpọlọpọ akitiyan lo maa n ṣẹlẹ labẹnu ninu oṣẹlu, ṣugbọn iyẹn ko tumọ si pe wọn ko ni i pari ẹ laarin mọlẹbi, ṣugbọn ka maa wa jade, ka maa sọ pe wọn fẹẹ fi kinni yii tako awọn Ijaw ni, iyẹn ko tọna rara.

Emi ni irinṣẹ, mo lagbara nigba naa lati sọ pe bo ṣe maa ri ree, to fi maa jẹ pe bi ohunkohun ba ṣẹlẹ, ibeere aa le waye."

Nigba to n ṣalaye nipa awọn idi kan ti rogbodiyan yii fi waye, Nyeson Wike sọ pe, " Wọn ni nitori ẹnikan ko fun mi ni biliọnu lọna ogun (20billion), pe mo fẹẹ pin iṣẹ agbaṣe funra mi, gbogbo awọn ọrọ bẹẹ yẹn, oṣelu ni.

Ṣugbọn ko sẹni to sọ iru ẹ nigba ti mo n ja o. Fun idi eyi, to ba wu yin kẹ ẹ maa fẹsun kan mi lateni-dọla, iyẹn o ni ki n ma sun, nitori ohun temi mọ ti mo si gbagbọ ninu ẹ ni pe ohun to tọ yẹ ni ṣiṣe."

Minisita yii tẹsiwaju, pe o ṣe pataki foun lati di ibi toun ti wa mu giri ko si duro digbi, nitori ko si oloṣelu kan to maa n fẹ padanu orirun rẹ to ti wa nibikibi ati lọjọkọjọ.

.

" Kaluku lo ni ilana oṣelu tiẹ, abi iwọ naa yoo laju rẹ silẹ kẹnikan waa ja ọ bọ?. Gbogbo wa la ni orisun wa, abi bẹẹ kọ?

Tiwọ ba gba orisun mi, sẹ mi o ni i dẹni ti wón ko ka kun ninu oṣelu mọ? Ohun to ba wu yin ni kẹ ẹ pe e, ṣugbọn nigba tasiko ba to, a maa mọ ẹni to jare atẹni to jẹbi. "

Ṣaaju ni Adari tẹlẹ fun eto idariji tijọba ṣe fawọn ajijagbara Niger Delta, Kingsley Kuku, ti ka ọrọ naa lorukọ awọn agbaagba Guusu-Guusu ti wọn ṣabẹwo si Wike.

Kingsley Kuku ṣalaye, pe arun to n ṣogoji lo n ṣe ọọdunrun, o ni inu awọn ko dun sohun to ṣẹlẹ nipinlẹ Rivers.

O tẹsiwaju pe idi niyẹn tawọn fi darapọ mọ ẹgbẹ Pan Niger Delta Forum (PANDEF) Ijaw Youth Congress, (IYC) MOSIEND, MOSOP, Ogbakor Ikwerre ati awọm ẹgbẹ mi-in naa ti wọn wa fun ki nnkan le daa fun Niger Delta, tawọn si jọ n bu ẹnu atẹ lu igbiyanju awọn ti wọn fẹẹ yọ gomina ipinlẹ Rivers nipo.

" A koro oju si igbiyanju ati ete lati yọ Gomina ipinlẹ Rivers nipo latọwọ awọn eeyan ile igbimọ aṣofin ipinlẹ yii, o jẹ ohun ti awa pẹlu gbogbo eeyan Niger Delta ko fara mọ rara.

A gba ẹnikẹni, tabi ẹgbẹ tabi awọn eeyan to ba n lọwọ ninu ina ọtẹ yii nimọran, pe ki wọn dẹkun ẹ bayii, ki wọn si jẹ kalaafia jọba.

Iwọ Wike ti o jẹ olori ẹgbẹ oṣelu nipinlẹ Rivers, ọmọ to o le fi mọna nijọba atawọn aṣofin. Awọn ẹbi rẹ ree ninu oṣelu, o daju pe wọn maa tẹti si ọ. Fun idi eyi la ṣe n pe ọ lati ba wọn sọrọ. Gbogbo oju lo n wo ọ gẹgẹ bi olulaja to o jẹ."

Ṣaaju asiko yii ni Gomina ipinlẹ Bauchi, Bala Mohammed, ti fidi ẹ mulẹ pe Aarẹ Bọla Tinubu ti da si rogbodiyan yii.

Bala Mohammed sọ pe Aarẹ Tinubu ṣepade pẹlu Gomina Rivers, Siminialayi Fubara ati Nyesom Wike. O ni wọn tilẹkun mọri ṣepade naa ni paapaa, lasiko ipade awọn ọlọpaa ilẹ Naijiria ti wọn ṣe ninu apata agbara l’Abuja.