Ohun tí a mọ̀ nípa ìgbẹ́jọ́ tó wáyé lórí ipò Aláàfin Oyo lánàá rèé

Oríṣun àwòrán, Seyi Makinde
Eeyan marun un ninu awọn afọbajẹ mẹfa to wa ninu igbimọ Ọyọmesi lo pe ẹjọ tako Gomina Ṣeyi Makinde, Agbẹjọro agba n'ipinlẹ Ọyọ ati ẹka ileeṣẹ ijọba to n mojuto ọrọ ijọba ibilẹ ati oye jijẹ.
Ẹjọ naa ti wọn gbe lọ si ile ẹjọ giga to n bẹ nilu Ọyọ lo da lori iyansipo Alaafin Ọyọ tuntun.
Awọn oloye to pe ẹjọ naa ni, Oloye Agba Yusuf Akinade Ayoola, (Basorun ilu Ọyọ), Oloye Agba Wakeel Akindele Oyedepo, (Lagunna ilu Ọyọ), Oloye Agba Amuda Yusuf, (Akinniku ilu Ọyọ), Oloye Agba Waheed Oyetunji (Aare Ago Basorun), ati Oloye Gbadebo Mufutau (Baale Alapo), gbogbo wọn lo si pejupesẹ si ibi igbẹjọ ti nọmba rẹ jẹ HOY/38/2023, eleyii to waye lọjọ Iṣẹgun.
Agbẹjọro fun awọn to pe ẹjọ naa, Kazeem Sobaloju, (SAN) pe fun ifidimulẹ ilana oye jijẹ saaju idajọ ile ẹjọ.
O ni koko meji ni awọn onibara oun pe ẹjọ le lori; akọkọ nibẹ ni lati dena igbẹsẹ ti o le da ilana oye jijẹ ru, ẹlẹẹkeji ni lati fi ilana oye jijẹ silẹ bi o ti wa tẹlẹ titi ti ile ẹjọ yoo fi gbe idajọ kalẹ.
Ṣugbọn agbẹjọro fun ijọba, Amofin E.O. Ojebisi ni iye ọjọ ti o gba wọn lati fi ẹjọ naa to ijọba leti ko to ọjọ marun un ti ofin la kalẹ lati fun ẹnikẹni ti a ba fẹ pe lẹjọ.
Nitori idi eyii lo fi pe fun anfani ati asiko lati gbaradi fun esi ti o tọ si awọn to pe ẹjọ tako ijọba ipinlẹ Ọyọ.
Ẹwẹ, Sobaloju parọwa si ile ẹjọ lati ma fi aye gba ẹnikẹni lati tọwọ bọ ilana oye jijẹ, nitori ọrọ naa mu ikanju lọwọ.
O ni awọn afọbajẹ ti ṣe ojuṣe wọn nipa yiyan Alaafin tuntun gẹgẹ bi ofin oye jijẹ ṣe laa kalẹ, ṣugbọn Gomina ko buwọlu igbẹsẹ awọn afọbajẹ, aṣẹ ti o pa ni pe ki wọn da gbogbo rẹ silẹ ki wọn si tun un ṣa.
Sugbọn adajọ Ladiran Akintola ni ọrọ naa ko gba kanjukanju rara, nitori naa lo fi kesi awọn agbẹjọro mejeeji lati fi ohun ṣọkan lori ọjọ ti wọn fẹ ki igbẹjọ naa waye.
O ni wọn gbudọ fun awọn ti wọn pe ẹjọ ni anfani lati gbaradi ki wọn si wa wi tẹnu wọn nile ẹjọ, nitori nipasẹ eleyii nikan ni oun le gbe idajọ kalẹ.
Ẹwẹ, lasiko ti itakurọsọ yii n lọ lọwọ nile ẹjọ, awọn ọmọ ilu korajọpọ niwaju ile ẹjọ lati fi ẹhonuhan nitori ọjọ to n lọ lori yiyan Alaafin tuntun.
Wọn parọwa si Gomina lati ma gbọjẹgẹ, ṣugbọn ki o tọ ọna ti o tọ lori ọrọ naa.
Lẹyin atotonu awọn agbẹjọro mejeeji ni adajọ sun igbẹjọ si Ọjọbọ, ọjọ keji, oṣu kọkanla ọdun yii.
Lati igba ti Ọba Lamidi Oba Lamidi Olayiwola Atanda Adeyemi III ti re iwalẹ aṣa ni ipo Alaafin Ọyọ ti ṣofo, ọpọlọpọ rogbodiyan ati awuyewuye lo si ti rọ mọ igbesẹ lati yan Alaafin tuntun.
Ni nnkan bii ọjọ diẹ sẹyin ni iroyin gbode wi pe Ọyọmesi gbe Gomina Ṣeyi Makinde lọ si ile ẹjọ lori iyansipo Alaafin Ọyọ tuntun. Iredi ti wọn fi gbe igbesẹ naa sini lati ma fi aye silẹ ki Makinde tọwọ bọ ilana ti wọn fi n jẹ oye Alaafin ilu Ọyọ.
Lẹyin ipade kan to waye ni ọgbọn ọjọ oṣu kẹsan an ọdun yii, awọn afọbajẹ ṣe alaye wi pe Ọmọọba Lukuman Gbadegesin ni awọn yan lati gun ori itẹ Alaafin ilu Ọyọ, ṣugbọn Makinde ko buwọlu igbesẹ naa titi di asiko yii.












