Mọ̀ síi nípa ìlànà tí ilé ìgbímọ̀ aṣòfin gbọ́dọ̀ gbé láti yọ gómìnà ìpínlẹ̀ kan

Aworan ile igbimọ aṣofin ipinlẹ Rivers ati Gomina Fubara

Oríṣun àwòrán, Ile igbimọ aṣofin ipinlẹ Rivers ati Gomina Fubara/BBC

Oriṣiriṣi awuyewuye lo ti bẹrẹ sii jẹyọ latigba ti ọrọ igbeṣe ile igbimọ aṣofin ipinlẹ River lati yọ Gomina Siminalayi Fubara ti jade lọjọ Aiku, Sannde, ọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu kẹwaa, ọdun 2023.

Irọlẹ ọjọ Sannde ọhun ni awọn kan ti wọn pe ni tọọgi lọ dana sun ile igbimọ aṣofin ipinlẹ Rivers, ṣugbọn awọn oṣiṣẹ panapana tete debẹ lati pa ina ọhun.

Iroyin to wa nilẹ bayii ni pe ile igbimọ aṣofin ipinlẹ Rivers lawọn ti pari ọrọ lati fun Gomina Siminalayi Fubara niwee lati gba ijọba kuro lọwọ rẹ, pẹlu bi wọn ti ṣe jawe lọ rọkunile fun awọn ọmọ ile igbimọ mẹrin.

Bo tilẹ jẹ pe ile igbimọ aṣofin ni agbara lati yọ gomina nigba ti wọn ba lero wi pe o yẹ ki awọn yọ, ṣugbọn o ni ilana ṣisẹntẹle gẹgẹ bi iwe ofin Naijiria ṣe laa kalẹ.

Ju gbogbo rẹ lọ, Gomina Siminalayi Fubara ti sọ pe oun ṣe ẹṣẹ kankan to le mu ki ile igbimọ aṣofin sọ wọn fẹẹ yọ oun kuro n’ipo.

“Ẹ jẹ ki wọn jade lati wa sọ fun gbogbo ọmọ ati olugbe ipinlẹ Rivers nipa ohun ti mo ṣe fun wọn, ti wọn fi fẹẹ yọ mi”, ohun ti Gomina Fubara sọ ree lasiko to n ba awọn alatilẹyin rẹ sọrọ ni gbọngan ile igbimọ naa.

Fubara tun sọ nibẹ pe oun yoo sọrọ lori ohun to n ṣẹlẹ nigba ti asiko ba to lati sọrọ.

Wọ̀nyí ni àwọn ìgbésẹ́ àti ìlànà láti yọ gómìnà

Kii ṣe ọrọ kekere ni lati yọ gomina ipinlẹ kan ni Naijiria, nitori pe gomina ọhun yoo nilo awọn ohun to tako ofin lati yọ ọ, eyi ti ko ni jẹ ki igbesẹ naa ṣee ṣe.

To ba jẹ pe awọn araalu to nigbagbọ ninu ẹ wi pe oun le le dari ipinlẹ wọn gẹgẹ bi wọn ṣe fẹ lo gbe e wọle, lo le fi lo asiko ti iwe ofin sọ.

Lori eyi, o tun ni ilana ṣisẹntẹle ti awọn alakoso gbọdọ tẹle to ba jẹ pe lotitọ ni wọn fẹẹ yẹ aga mọ gomina nidi.

Igbesẹ ati ilana lati yọ gomina wa ni abala 188 ninu iwe ofin orileede Naijiria, ti ọdun 1999.

Igbesẹ akọkọ

Bi iwe ifẹsunkan ba ti wa nilẹ tẹlẹ nipa wi pe gomina kowojẹ. Eyi lo si jẹ pe ida kan ninu mẹta ninu awọn ọmọ ile igbimọ aṣofin gbọdọ tọwọ bọwe, wọn yoo si gbe e siwaju adari ile igbimọ aṣofin.

Igbesẹ keji

Adari ile igbimọ aṣofin gbọdọ fi iwe naa ranṣẹ si gomina laarin ọjọ meje pẹlu ẹda iwe ifẹsunkan kan.

Igbesẹ kẹta

Gomina ni ẹtọ lati da wọn lohun (o si lẹtọọ lati ma ṣe dahun), ati pe ohunkohun ti gomina ba sọ gbọdọ tẹ ọkọọkan ninu awọn ọmọ ile igbimọ aṣofin.

Igbesẹ kẹrin

Laarin ọjọ mẹrinla ti wọn ba ti gbe iwe ọhun siwaju adari ile igbimọ aṣofin, wọn yoo jokoo lati sọ boya wọn ni lati ṣe iwadii tabi wọn ko nilo lati ṣe iwadii awọn ẹsun ti wọn fi kan gomina. Eyi yoo si gba iwaju ida meji ninu mẹta awọn ọmọ ile igbimọ aṣofin kọja.

Igbesẹ karun-un

Bi aba naa ba kuna lati de iwadii ida meji ninu awọn ọmọ ile igbimọ aṣofin yii, loju ẹsẹ ni igbesẹ ọhun yoo dawọ duro, ko si sohun to tun gbọdọ ṣẹlẹ lẹyin rẹ. Ṣugbọn bi ida meji ninu mẹta awọn ọmọ ile igbimọ naa ba gba aba yii wọle, eyi yoo fun olori ile igbimọ aṣofin ni anfaani lati sọ fun adajọ agba ipinlẹ naa lati yan igbimọ ẹlẹni meje dide lati tọpinpin ẹsun ti wọn fi kan gomina lai si ẹni ti yoo yẹ wọn lọwọ wo.

Awọn igbimọ naa le ma oṣiṣẹ ijọba, aṣofin tabi ọmọ ẹgbẹ oṣelu.

Igbesẹ kẹfa

Igbimọ ọhun yoo nilo lati ṣe iwadii wọn laarin oṣu mẹta gbako ti wọn ba ti yan wọn. Wọn yoo si gbe e wa siwaju ile igbimọ aṣofin. Lasiko ti wọn ba n ka a, gomina ni ẹtọ lati sọrọ gbeja ara rẹ, bẹẹ lo ni ẹtọ lati yan agbẹjọro tabi amofin to le ba a duro, eyi si wa lori ohun ti gomina ba fẹ.

Igbesẹ keje

Wọn yoo yan igbimọ kan ti yoo;

(a) ni agbara lati tẹle ṣiṣẹ ti awọn aṣofin ba fun un, iyẹn lori alakalẹ ile igbimọ aṣofin ba fi lelẹ; ati pe

(b) laarin oṣu mẹta ti wọn ba yan wọn, iwadii wọn gbọdọ tẹ ile igbimọ aṣofin lọwọ.

Igbesẹ kẹjọ

Nibi ti iwadii igbimọ ọhun ko ba ti fidi ẹsun naa mulẹ, ko tun si igbesẹ miran to gbọdọ waye mọ. Ṣugbọn ṣa, ti iwadii ba fidi rẹ mulẹ pe otitọ ni awọn ẹsun ti wọn fi kan an, ile igbimọ aṣofin yoo nilo lati daba ki wọn tẹsiwaju ohun ti yoo ṣe lori iwadii yii.

Igbesẹ kẹsan

Ki wọn to le gba ipnnu naa wọle, ida meji ninu mẹta ọmọ ile igbimọ aṣofin gbọdọ bu ọwọ lu. Ni kete ti wọn ba ti bu ọwọ lu, gomina yoo dide niwaju wọn, wọn yoo si yọ ọ loju ẹsẹ lẹyin ti wọn ti gba ipinu ọhun.

Igbesẹ kẹwaa

Ko si ijokoo kankan tabi igbesẹ ti wọn le gbe lọ si eyikeyi ile-ẹjọ lẹyin ti wọn ba ti pari ipinu yii tan.

Igbesẹ kọkanla

Ni abala yii, “ṣiṣe owo kumọkumọ” jẹ ẹṣẹ nla to tako iwe ofin tabi oniruuru bi ile igbimọ aṣofin ba ṣe tunmọ rẹ si.

Bi Siminialayi Fubara se di gomina fẹgbẹ oṣelu PDP

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Oluṣiro owo agba ni Siminialayi Fubara jẹ tẹlẹ fun ijọba ipinlẹ Rivers.

O gbegba oroke ninu eto idibo abẹle ẹgbẹ PDP lỌjọru, Wẹside, ọjọ kẹtalelogun, oṣu karun-un, ọdun 2022 ni gbọngan Obi Wali to wa niluu Port Harcourt.

Agbegbe Opobo to wa nijọba ibilẹ Opobo/Nkoro, ipinlẹ Rivers lo ti jade.

Ibo 721 ni Fubara fi bori gbogbo awọn ti wọn jọ dijẹ nibi eto idibo abẹle fun PDP.

Isaac Kamalu toun wa lati agbegbe Eleme lo ṣe ipo keji pẹlu ibo mẹrindinlaadọrun (86), nigba ti Alabo Dakorinama George-Kelly ṣe ipo kẹta pẹlu ibo mẹtadinlogoji (37), ti Tammy Danagogo to ṣe ipo kẹrin ni ibo mẹrindinlogoji (36).

Ninu ọrọ idupẹ ati imọriri rẹ, Fubara dupẹ lọwọ Ọlọrun, to si ni oun fi aṣeyọri naa jin ẹgbẹ PDP.

“Oore ọfẹ lo n ṣiṣẹ. Eyi kii ṣe aṣeyọri fun Fubara, bi ko ṣe fun ẹgbẹ. Kii tiẹ tun ṣe fun ẹgbẹ nikan, bi ko ṣe lati mu ipinlẹ yii tẹsiwaju”, gẹgẹ bi ohun to sọ.

Fubara maa n sọ pe boun ṣe jawe olubori ni lati tẹsiwaju ninu awọn iṣẹ aṣeyọri ti Gomina Nyesom Wike ṣe silẹ.

Bakan naa, Gomina Nyesom Wike naa sọ pe bi Siminialayi Fubara ṣe jawe olubori jẹ iṣẹ Ọlọrun.

“Ọdọ Ọlọrun ni agbara ti wa. Nigba ti mo di gomina, mi o tiẹ kuku mọ tẹlẹ pe maa di gomina. Ki gbogbo rii pe bi Ọlọrun ṣe kọ ọ silẹ ni ohun to ṣẹlẹ yii”, wọnyi ni ọrọ Wike.