Barber wọ gàù lẹ́yìn tí ọ̀rẹ́bìnrin kú lásìkò ìbálòpọ̀ gbọ́ọ̀rọ̀

Oríṣun àwòrán, Others
Ọwọ Ileeṣẹ Ọlọpaa nipinlẹ Kwara ti tẹ okùnrin kan to jẹ gẹrigẹri niluu Ilorin lori Iku obinrin kan to jade laye lẹyin ibalopọ lọjọ Aje.
Ileeṣẹ Ọlọpaa fìdí iṣẹlẹ naa mulẹ lọjọ Isẹgun, ti wọn si jẹ ko di mimọ pe awọn ti bẹrẹ iwadi lori ohun to sokunfa iku obìnrin lẹyin ti oun ati ọrẹkunrin ni ibalopọ ni ile ìtura niluu Ilorin.
Iwadii fihan pe iṣẹlẹ naa waye lọjọ Aje ni ile ìtura kan to wa ni agbegbe Temidire ni bi ọkùnrin naa to ni sọọbu ti wọn ti n tun irun ọkùnrin ṣe ti tẹlẹ ọrẹbinrin rẹ lọ si ile ìtura.
Osojumikoro to ba Ileeṣẹ Iroyin abẹle The Punch sọrọ salaye pe ọkunrin naa lo da bi pe o ti gbe ogun oloro lu ra lati ba ọrẹbinrin rẹ ni ibalopọ.
"Oloogbe naa ni íbalopọ naa su, to si gba ibẹ sọda "
O ni ọkùnrin naa pariwo síta pe ki awọn eeyan to wa ni ile ìtura gba oun, ti wọn si sure gbe obìnrin naa lọ ile iwosan ni bi to ti jade laye.
Oludasilẹ ile ìtura naa lo ransẹ pe ileeṣẹ Ọlọpaa nipinlẹ Kwara, ti wọn si mu ọkùnrin lọ ahamọ.
Agbẹnusọ fun ileeṣẹ Ọlọpaa nipinlẹ Kwara, SP Okasanmi Ajayi fìdí iṣẹlẹ naa mulẹ, to si jẹ ko di mimọ pe iwadii ti bẹrẹ.
"O ti tọ ni iṣẹlẹ naa waye. Ileeṣẹ Ọlọpaa nipinlẹ Kwara tí mu afurasi naa lati le ṣe iwadii lori ohun to waye laarin awọn mejeeji."












