Àwọn Jàǹdùkú yabo Radio Nàìjíríà, jí ọ̀pọ̀lọpọ̀ nǹkan gbé lọ, lù ẹsọ alabo.

Aworan ohun tí àwọn janduku bajẹ

Oríṣun àwòrán, Radio Nigeria

Awọn janduku ẹlẹni mẹrin, lowurọ ọjọ Isẹgun ṣekọlu si ileeṣẹ Redio ìjọba apapọ Radio Naijiria to wa ni ilu Idofian ni ijọba ibilẹ Ifelodun nipinlẹ Kwara.

Awọn agbebọn ọhun ni wọn yabo ileeṣẹ Redio naa pẹlu ọkada meji, ti wọn si ba ọpọlọpọ dukia jẹ, ti wọn si tun gbe ọpọlọpọ iransẹ ileeṣẹ Redio naa lọ.

Nnkan bí ago mẹrin aarọ ni iṣẹlẹ naa waye, ti wọn si lu ẹsọ alabo to n sọ ileeṣẹ naa ni alubami, ki wọn to de lokun mọlẹ.

Ileeṣẹ Redio naa to jẹ ti ìjọba apapọ lo ti wa da isẹ silẹ latari ijamba tí awọn janduku naa se.

Lasiko to n sọrọ lori iṣẹlẹ naa, igbakeji Ọga agba fun eto ni ileeṣẹ naa to soju Ọga agba fun ileeṣẹ naa, Haija Binta Abubakar Mora koroju si iṣẹlẹ naa, to si ni o jẹ ohun to n dẹrun ba ìsẹ igbigbe ohun safẹfẹ lorilẹede Naijiria.

"Idunkoko si isẹ igbe ohun safẹfẹ ni eyi lorilẹede Naijiria. Laipẹ yii ni Ikọlu waye si awọn ileeṣẹ Redio wa to wa ni Lokoja nipinlẹ Kogi ati ni Lafia nipinlẹ Nasarawa.

"Ni bayi, a ti pana isẹ. Ìkọlù ti waye. Gbogbo ohun tí wọn bajẹ, ti wọn tun gbe lọ jẹ ọpọlọpọ milọnu naira. Igbesẹ yii ti wa lọrun awọn alasẹ bayii

"Ẹmi awọn osisẹ to wa lẹnu isẹ lo jẹ wa logun ju gbogbo ohun ti wọn bajẹ yii lọ nitori ti nnkan ba sẹlẹ ni, ọrọ mii ni a ma s."