Ìjọba àpapọ̀ ṣetán láti kọ́ ẹgbẹ̀rún márùn ún ilé ọ̀fẹ́ fún ará ìlú

Housing units

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ijọba apapọ ti sọ pe oun n gbero lati kọ ile to to ẹgbẹrun marun un fawọn araalu ni gbogbo ẹkun mẹfa ti orilẹ-ede yii pin si.

Ijọba ni igbesẹ yii ko ọna ati mu ibugbe irọrun pọ si i fun awọn araalu.

Minisita abẹle fun eto ile gbigbe ati idagbasoke igberik, Alhaji Abdullahi Tijjani Muhammad Gwarzo, lo sọ eyi lasiko ifọrọwerọ kan pẹlu ileeṣẹ iroyin BBC.

Ijọba apapọ fẹẹ kọ ẹgbẹrun marun-un ile fawọn ọmọ Naijiria

Gwarzo to gba ẹnu ijọba apapọ Naijiria sọrọ tẹsiwaju pe eto wa fun ile kikọ lorilẹ-ede yii daadaa, ṣugbọn bo ṣe jẹ pe abẹ ile iṣẹ agbara ni eto naa wa tẹlẹ

lo fa a ti ko sẹ rọrun lati gbe igbesẹ ọhun.

O ni ṣugbọn ni bayii ti ko si labẹ ileeṣẹ naa mọ, iṣẹ yoo bẹrẹ laipẹ.

O ni “A lẹtọọ lati kọ ẹgbẹrun ile ni gbogbo ipinlẹ lorilẹ-ede yii, a kan n duro de Aarẹ lati fun wa laṣẹ lati bẹrẹ ni.

“Bi wọn ba ti fun wa laṣẹ, a maa bẹrẹ iṣẹ naa.

“Eto ti wa nilẹ lati fun awọn ti ko ba lagbara lati kọ ile tiwọn nile naa lọfẹẹ, bẹẹ la si maa gba owo diẹ lọwọ awọn mii ti wọn ba lanfaani lati sanwo fun jọba’’.

Minisita naa fi kun ọrọ rẹ pe gbogbo eto lo ti pari lori iṣẹ ile tawọn fẹ bẹrẹ yii, ati pe awọn yoo ṣe ifilọlẹ rẹ laipẹ.

Abala meji ni iṣẹ naa gẹgẹ bo ṣe wi, akọkọ rẹ ni ijọba pe ni ‘Mega City’, to tumọ si pe ni awọn ilu nla nla, ẹgbẹrun marun-un ile lawọn yoo kọ ni gbogbo agbegbe Naijiria.

Ṣugbọn o, gbogbo igbesẹ ile kikọ yii ni nnkan lati ṣe pẹlu eto iṣuna ijọba gẹgẹ bo ṣe sọ, eyi yoo si ṣẹlẹ laipẹ.

Gwazo ṣalaye pe apa keji eto ile kikọ naa wa fun idagbasoke igberiko, eyi ti yoo kan awọn ijọba ibilẹ, ti ijọba yoo si ṣe awọn ọna ati ọja pẹlu, ti gbogbo ẹ yoo si sẹ rẹgi bii ilu kan lapapọ gẹgẹ bo ṣe ṣalaye.