N kò fẹ́ rí ọmọ mi Seyi nínú gbọ̀ngàn tí a ti ń ṣe ìpàdé ìgbìmọ̀ ìlú mọ́- Tinubu

Oríṣun àwòrán, Asiwaju Bola Ahmed Tinubu
Aarẹ Naijiria, Bola Ahmed Tinubu ti sọ pe oun ko fẹ ki oniruru eeyan maa wọ inu gbọgan ti wọn ti n ṣe ipade igbimọ ilu lati akoko yii lọ.
Tinunu lo sọ ọrọ naa lasiko ọkan lara awọn ipade wọn to waye laipẹ yii, ninu eyii ti fidio rẹ ti gba ori ayelujara.
O ni o loju awọn to gbọdọ maa yọju sibi ipade naa nitori kii ṣe gbogbo eeyan ni oun n fẹ nibẹ.
Ibi ipade igbimọ ilu naa ni Aarẹ atawọn alabaṣiṣẹ rẹ ti maa n jiroro lori ọrọ atunṣe ilu atawọn ọrọ mii to kan awọn ọmọ Naijiria gbọngbọn.
“Ko ṣe itẹwọgba fun ọmọ mi lati maa joko nibi ipade igbimọ ilu”
Ninu fidio naa ni Tinubu ti sọ pe “Lọsẹ to kọja ni mo ṣakiyesi pe awọn eeyan kan n yọ wọ inu yara ipade igbimọ yii.”
“Mo ri aworan ọmọ mi Seyi to joko ninu yara yii, iyẹn ko ṣe itẹwọgba rara.”
Lẹyin naa lo kede orukọ awọn to yẹ lati wa ninu ile naa, eyii to fọwọ si funra rẹ gẹgẹ bii Aarẹ.
Lara awọn ti Aarẹ Tinubu darukọ pe wọn oun fọwọsi pe wọn le maa darapọ mọ ipade naa ni Bayo Onanuga, Akeem Muri Okunola ati Damilotun Aderemi.
O ni “Awọn eeyan wọnyii nikan ni mo gba laaye lati maa darapọ mọ wa ninu iyara yii ti a ba n ṣe ipade lori ọrọ ilu.”
“Ayafi ti mo ba ranṣẹ pe ọ, maṣe darapọ mọ wa nibi.”














