Yege nípò tí a fí ẹ́ sì tàbí kóo máa lọ sílé rẹ- Ààrẹ Tinubu sọ fún àwọn mínísítà tó yàn

Aworan Aare Bola Ahmed Tinubu

Oríṣun àwòrán, Facebook/Asiwaju Bola Ahmed Tinubu

Aarẹ Bola Tinubu ti jẹ ko di mimọ pe oun yoo fọwọ osi juwe ile fun minisita tabi amugbalẹgbẹ to ba kọ lati yege nipo ti ìjọba fi si.

Aarẹ ni ijọba oun ko ni fi aye gba minisita tabi amugbalẹgbẹ ti ko le fọwọsowọpọ ninu ilọsiwaju orilẹede Naijiria.

Tinubu ṣe ikilọ yii lasiko to n side apero àwọn minisita, amugbalẹgbẹ ati osisẹ ijọba apapọ ni ile ijọba Aso Rock niluu Abuja.

Aare ni oun ko fi aye silẹ fun ọlẹ tabi awawi nitori rẹ ni oun fi fi awọn akọsẹmọsẹ yi oun ka, awọn to mọ nípa idagbasoke ilu.

O ni oun ti kesi ọkan lara amugbalẹgbẹ Aarẹ, Bala Hadiza lati lewaju igbimọ to mojuto bi ẹka ìjọba ṣe n sisẹ wọn.

"To ba n sisẹ rẹ daada, ma foya sugbọn ti a ko se nnkan nípa idagbasoke ibi tí a fi ẹ si, wa fi walẹ nitori ko si aye iru eeyan bẹ."

Lara awọn nnkan mii ti Aarẹ mu ẹnu ba ni fun awọn minisita ati amugbalẹgbẹ rẹ ni fífi opin si isẹ, airi oúnjẹ jẹ, idagbasoke ọrọ aje, ipese isẹ ati awọn nnkan mii.