Ta ni Duoye Diri tí àwọn olùdìbò yàn sípò gómìnà fún sáà kejì ní Bayelsa?

Oríṣun àwòrán, x/Governor Douye Diri
Ní ọjọ́ Kẹtàlá oṣù Kejì ọdún 2020 ni ilé ẹjọ́ tó ga jùulọ ní Nàìjíríà kéde Duoye Diri gẹ́gẹ́ bí gómìnà ìpínlẹ̀ Bayelsa lẹ́yìn tí wọ́n yẹ àga mọ́ ẹni tó jáwé olúborí ètò ìdìbò ìpínlẹ̀ náà lọ́dún 2019, David Lyon nídìí.
Èyí wáyé lẹ́yìn tí ilé ẹjọ́ fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé igbákejì David Lyon ṣàgbékalẹ̀ ayédèrú ìwé ẹ̀rí síwájú àjọ tó ń rí sí ètò ìdìbò ṣaájú ètò ìdìbò náà.
Ilé ẹjọ́ ní kí wọ́n fún Diri ní ìwé ẹ̀rí mo yege, tí INEC sì búra wọlé fún gẹ́gẹ́ bí gómìnà Bayelsa lọ́jọ́ Kẹrìnlá, oṣù Kejì ọdún 2023.
Ṣaájú kó tó di gómìnà, Duoye Diri ti ṣojú ẹkùn àárín gbùngbùn ìpínlẹ̀ Bayelsa ní ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin àgbà láàárín ọdún 2019 sí 2020.
- Ta ni Usman Ododo tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ dìbò yàn sípò gómìnà ní ìpínlẹ̀ Kogi?
- Àwòrán réè tó ṣàfihàn bí àwọn èsì ìdìbò ṣe n jáde ní ìpínlẹ̀ Kogi,Bayelsa àti Imo
- Àjọ ICPC mú èèyàn mẹ́fà lórí ẹ̀sùn kátà-kárà ìbò, wọ́n gba N4.1m lọ́wọ́ wọn
- Ìṣípòpadà bá àwọn Kọmíṣọ́nà àti AIG ogójì ní Iléeṣẹ́ Ọlọ́pàá Nàìjíríà
Ní ọjọ́ Kẹrin, oṣù Kefà ọdún 1959 ni wọ́n bí Diri tó sì ti pé ẹni ọdún mẹ́rìnlélọ́gọ́ta báyìí.
Ó lọ sí ilé ẹ̀kọ́ alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ Okoro Primary School àti Rev Proctor Memorial Primary School, Kaiama tó sì parí rẹ̀ lọ́dún 1977.
Ó tẹ̀síwájú lọ sí ilé ẹ̀kọ́ girama Government Secondary School, Odi ní ìpínlẹ̀ Bayelsa.
Lẹ́yìn náà ló lọ sí ilé ẹ̀kọ́ olùkọ́ni College of Education, Port Harcourt tó sì parí lọ́dún 1985.
Duoye Diri jáwé olúborí ìbò gómìnà ìpínlẹ̀ Bayelsa

Oríṣun àwòrán, Bayelsa Government New Media
Àjọ tó ń rí sí ètò ìdìbò ní Nàìjíríà, INEC ti kéde gómìnà Duoye Diri gẹ́gẹ́ bí ẹni tó jáwé olúborí ètò ìdìbò ìpínlẹ̀ Bayelsa.
Ní ọjọ́ Àbámẹ́ta, ọjọ́ Kọkànlá oṣù Kọkànlá ọdún 2023 ni ètò ètò sípò gómìnà wáyé ní ìpínlẹ̀ Bayelsa, Kogi àti Imo.
Gíwà àgbà ilé ẹ̀kọ́ gíga Federal University of Technology, Minna, Ọ̀jọ̀gbọ́n Faruq Kuta tó ṣiṣẹ́ fún INEC ní ìpínlẹ̀ náà ló kéde Diri bí ẹni tó jáwé olúborí.
Douye Diri tó díje fún sáà kejì lẹ́gbẹ́ òṣèlú Peoples Democratic Party ní ìbò ẹgbẹrun marundinlọgọsan ati igba o din mẹrin (175, 196) láti fi tún tukọ̀ ìpínlẹ̀ Bayelsa.

Gẹ́gẹ́ bí ìkéde INEC, olùdíje lẹ́gbẹ́ òṣèlú All Progressives Congress, APC, Timipre Sylva ló tún súnmọ́ Diri nígbà tí òun náà ní ìbò ẹgbẹrun lọna aadọfa o le mejidinlaadọfa (110,108) láti gba ipò kejì.
Diri ló gbégbá orókè ní ìjọba ìbílẹ̀ .... nínú ìjọba ìbílẹ̀ mẹ́jọ tó wà ìpínlẹ̀ náà tí Sylva sì mókè ní ìjọba ìbílẹ̀ ....
Àwọn ìjọba ìbílẹ̀ tí Diri ti mókè ni Kolokuma/Opokuma, Ogbia, Yenegoa, Sagbama, àti Ekeremor.
Sylva ní tirẹ̀ sì jáwé olúborí ní ìjọba ìbílẹ̀ Nembe àti Brass.
Ẹgbẹ́ òṣèlú mẹ́rìndínlógún ló fa olùdíje kalẹ̀ fún ètò ìdìbò gómìnà ní ìpínlẹ̀ Bayelsa.
APC faake kọri, kọ lati fọwọsi iwe esi ibo

Oríṣun àwòrán, screenshot
Aṣoju oludije ẹgbẹ oṣelu APC faake kọri nibi gbgan ikede ibo gomina ni ipinlẹ Bayelsa pe awọn ko ni buwọlu iwe esi idibo naa.
O ni ohun to ṣẹlẹ ni pe awọn agbegbe ti oludije APC ti bori ni awọn to n ṣe amojuto akojọpọ ibo naa wọgile ‘eleyi to mu ki oludije PDP gbegba oroke.
O ni ibo to le ni ẹgbẹrun mẹrinlelọgọrin ni awọn to ṣe kokari aropọ ibo naa wọgile lara ibo oludije fun ẹgbẹ oṣelu APC, iyẹn Timiprey Silva.
O ni awọn yoo tẹsiwaju lọ si ile ẹjọ to n gbọ awuyewuye esi ibo lati fi ẹhonu wọn han.
Amọṣa aṣoju oludije PDP nibi eto akojọpọ esi ibo naa rọ awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu APC ati oludije wọn lati lọ fọwọ wọnu ki wọn si gba bi esi ibo naa ṣe lọ.














