Lassa Fever: Ibà Lassa tún ti rán èèyàn mẹ́rin s'ọ́run ní ìpínlẹ̀ Kogi

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Iba Lassa to n ja ran-in ran-in tun ti ṣọṣẹ ni ipinlẹ Kogi, ẹka eto ilera nipinlẹ naa ti ṣalaye pe eeyan mẹrin lo ti jẹ Ọlọrun ni pe ninu awọn mẹsan an to lugbadi aarun naa.
Dokita Austin Ojotule, to n ri si dudena ajakalẹ aarun ni ipinlẹ Kogi lo fọrọ yii lede niluu Lọkọja tii ṣe olu ilu ipinlẹ naa.
Dokita Ojotule ṣalaye pe awọn eeyan mọkanlelọgbọn ni ẹka ilera ṣe ayẹwo fun un lẹyin ti wọn funra pe wọn ti lugbadi iba lassa.
- Yàtọ̀ f'àwọn mẹ́fà tó m bọ̀ láti ìpàgọ̀ àdúrà tó kú, àjọ FRSC Osun sọ ipò táwọn tó fara pa wà báyìí
- 'Kìí ṣe 'ibà Lassa' ló padà wọ ìpínlẹ̀ Benue', mọ̀ nípa ààrùn tó ti pa èèyàn 15 ní Benue
- Mọ̀ síi nípa ǹkan tí o lè ṣe láti dènà ibà Lassa
- 'Ẹ yé mu gaàrí mọ́, tẹ́ẹ̀ bá fẹ́ lùgbàdì ibà Lassa'
- Èèyàn mẹ́wàá tó m bọ̀ láti ìpàgọ́ àdúrà kú nínú ìjàmbá ọkọ̀ ojú pópó l'Osun
- BBC tún gbé e dé! Wọ́n tú àṣírí ìfiyàjẹni àwọn Ológun àti SARS káàkiri Nàìjíríà
- Bàbá fìdí ọmọ ọdún márùn ún jó sítóòfù gbígbònà, ó di aláàbọ̀ara nítorí ó jí ẹja
Dokita Ojotule ni mẹtadinlogun ninu wọn ni ko ni aarun naa, ninu awọn mẹsan an ti ayẹwo fi han pe wọn ni aarun ọhun ni eeyan mẹrin ti dero ọrun.
Ijọba ibilẹ Ibaji, Okene, Idah, Okehi ati Igalamela lawọn mẹsan to lugbadi aarun naa ti wa.
Ọrọ di bo lọ ya n mi lori iba lassa ni Gusau
Ojora mu ọpọ araalu Gusau nipinlẹ Zamfara lọjọ Aiku lẹyin ti ayẹwo fihan pe obinrin kan to ku niluu naa laarun iba lassa.
Ọjọ Aiku ni wọn gbe obinrin naa digbadigba lọ si ile iwosan King Fahad Women and Children Hospital nibi to ti jẹ Ọlọrun ni'pe.

Oríṣun àwòrán, OTHERS
Awọn oniṣẹ eto ilera ṣe ayẹwo fawọn to wa ninu yara wọọdu kan naa pẹlu obinrin yii lati mọ boya awọn naa ti ni aarun Lassa.
Ile iwosan naa gbiyanju lati dena ki awọn eeyan mii wọle lati dena itankalẹ aarun iba lassa.
Wo iye ibùdó ìtójú ibà Lassa tó wà ní Nàìjíríà
Ajọ to n gbogun ti ajakalẹ arun lorilẹede Naijiria, NCDC ti sọ wi pe ile iwosan mẹtadinlogun lo wa fun itọju aisan naa.
Ajọ NCDC sọ eyi latari bi iye awọn eniyan to ti ku nipa aisan iba orẹrẹ Lassa Fever ṣe n pọ si i kaakiri awọn ipinlẹ ni Naijiria.
NCDC lasiko ti wọn n ṣe ipade pẹlu awọn onimọ nipa aisan Lassa n woye boya ki wọn kede eto pajawiri nitori aisan Lassa naa.
Yatọ si awọn ile iṣẹ iwosan yii, awọn ibudo ti wọn ti n ṣe ayẹwo ẹjẹ lati mọ boya eniyan ni aisan naa wa ni ipinlẹ marunlorilẹede Naijiria, awọn si ni:
- National Reference Laboratory, Gaduwa, FCT.
- Irrua Specialist Teaching Hospital, Edo State.
- Lagos University Teaching Hospital (LUTH).
- Federal Teaching Hospital, Abakaliki, Ebonyi state.
- Federal Medical Centre Owo, Ondo state.












