Akeem Oseni: Ọwọ́ tẹ Soja to fẹ́sẹ́ fẹ́ lẹyin ìdájọ lori kú to pa àwọn akẹgbẹ́ wọ́n l'ọ́jọ́si

Oríṣun àwòrán, other
Ọmọ ogun Naijiria tó fẹ́sẹ̀ fẹ́ẹ lágbègbè ilé ẹjọ nílu Abuja lẹ́yin ti wọ́n dájọ ẹwọ̀n ọdun mẹwàá fún òun àti àwọn àkẹgbẹ́ rẹ̀ ní ọwọ ti tẹ bàyìí ni pápákọ òfurufu orilẹ̀-èdè Benin Republic.
Ọgbẹ́ni Oseni to jẹ́ ọkàn lára àwọn mẹrin ti wọ́n dá lẹ́jọ pe wọ́n jẹ̀bi ẹsùn pipa Corporal Lance àti Benjamin Collins lọ́jọ́ Jimọ ni wọ́n mú ni Kotonu ni ààgo meji ọ̀san ọjọ aje.
Ìròyìn fi kún un pé, àwọ̀n ọmọ ogun miran ti wà ni gbaga báyìí pẹ̀lú ni olu ile iṣẹ́ àwọn ọmọ Ogun láti wadìí bi Oseni ṣe ráàye sá kuro tẹlẹ̀.
- Àwọn ọmọ Nàìjíríà ò wo ojú ààrẹ Buhari rárá, wọ́n da ẹnu bo ìdáhùn rẹ̀ sí ìkọlù Boko Haram
- Obìnrin tó rè kọjá lójú pópó ló fà ìjàmbá ọkọ́ Osun
- BBC tún gbé e dé! Wọ́n tú àṣírí ìfiyàjẹni àwọn Ológun àti SARS káàkiri Nàìjíríà
- Àrà kengé! Ọmọ China to ẹgbá sí ìdí ọmọ'ṣẹ́ rẹ tó pẹ́ ẹ́ dé ibi'ṣẹ́
- Ohun tí a mọ̀ nípa ààrùn tó ń pani ní Nàìjíríà tí kìí ṣe CoronaVirus, Lassa, tàbí Ebola rèé
Lẹ́yin ti Oseni gba ìdájọ tan lo ni ki wọ́n gba òun láàye láti lọ tọ̀, lo ba gba ibẹ̀ pòóra.
Bakan náà ni ilé iṣẹ́ ọmọ ogun ti fi ìpè sita ni kéte ti ọ̀rọ̀ náà ṣẹ́lẹ̀ láti wa Oseni jáde, àti àwọn ọlọpàá àti àwọn ọmọogun, to fi mọ àwọn ọmọ àjọ ọtẹlẹmuyẹ ni wọ́n kopa ninu iṣẹ́ náà.
Major Ogbemudia Osawe àti Nuhu Dogary ni adajọ dá ẹwọn ọdun méwàá fun pẹlu Oseni.
Ninu àtẹjáde kan to bo si ọwọ ilé iṣẹ́ ìròyìn Punch ni àjọ ọmọogun ti fi idi rẹ múlẹ̀ pe ọwọ́ ti tẹ Oseni ni papakọ ofurufu Cotonou lásìkò to ń duro láti wọ ọkọ ti yóò gbe e lọ si Cote D'Ivoire làago marun lọ si orilẹ̀-èdè Amerika.
Níbayìí Oseni ti wa ni àhámọ ilé iṣẹ́ ọlọpàá Benin Republic ti ijọba si ti bẹ̀rl ètò láti gbé pada si orilẹ̀-èdè Naijiria.













