Gambia presidential election results: Adama Barrow wọlé ṣáà kejì gẹ́gẹ́ bí ààrẹ Gambia

Adama Barrow

Oríṣun àwòrán, Reuters

Adama Barrow tun ti jawe olubori gẹgẹ bi Aarẹ orilẹ-ede Gambia.

Ajọ eleto idibo orilẹ-ede naa, IEC, kede ni alẹ ọjọ Aiku pe Barrow ni yoo tun tukọ orilẹ-ede naa fun ọdun marun-un miran.

Idibo akọkọ si ree lati ọdun mejilelogun lorilẹ-ede naa, ti Aarẹ to wa nipo fun ọpọ ọdun, Yahya Jammeh ko dupo.

Ida mẹtalelaadọta ibo ti araalu di lọjọ kẹrin, oṣu Kejila, ọdun 2021, ni Aarẹ Barrow ni.

Bi esi idibo aarẹ orilẹ-ede Gambia ṣe ri niyii
Àkọlé àwòrán, Bi esi idibo aarẹ orilẹ-ede Gambia ṣe ri niyii

Olori alatako rẹ, Ousainou Darboe, ati awọn oludije meji miran si ti fi atẹjade sita pe awọn ko gba esi ibo naa wọle.

Taa ni Adama Barrow?

Oniṣowo karakara ilẹ ati ile ni Aarẹ Adama Barrow.

Ọdun 2017 lo kọkọ dije fun ipo oṣelu, to si wọle si ipo aarẹ orilẹ-ede Gambia.

Ẹya Fula ni ẹni ọdun marunlelaadọta naa ti wa, wọn si bi ni ọdun 1965, ni ọdun ti orilẹ-ede Gambia gba ominira.

Iroyin sọ pe o ṣiṣẹ aṣọgba ni ile itaaj nla Argos ni nkan bi ọdun 2000 lasiko to n lọ sile ẹkọ ni UK.

Ọdun 2006 lo pada sile, to si bẹrẹ okoowo karakata ilẹ ati ile.

Ọkan gboogi lara awọn alatilẹyin ẹgbẹ agbabsọlu Arsenal ni.

O si jẹ ẹlẹsin Musulumi.

Iyawo meji ni Adama Barrow ni, to si bi ọmọ marun-un, amọ ọkan lara wọn ku ni ọdun 2017 to kọkọ wọle si ipo aarẹ, lẹyin ti ajá bu ọmọ naa jẹ.