Rachael Ayegba: Golí agbábọ́ọ̀lù obìnrin Nàìjíríà tẹ́lẹ̀ di awakọ̀ bọ́ọ̀sì ní UK

Oríṣun àwòrán, Evening Standard
Ọna ọfun, ọna ọrun, bayii ni awọn Yoruba maa n wi.Aṣọle ẹgbẹ agbabọọlu obinrin Super Falcons orilẹede Naijiria tẹlẹ, Rachael Aladi Ayegba ti di awakọ bọọsi nla lorilẹ ede bayii.Ayegba ṣoju Naijiria ninu idije ere bọọlu agbaye lọdun 2007 lorilẹ ede China.
- BBC kéde àwọn tó pegedé láti gba àmì ẹ̀yẹ èrè ìdárayá ọdún 2021
- Ojú ará bẹ̀rẹ̀ sí ní ta mí lẹ́yìn tí Gbenga Filani fipá bámi lòpọ̀- olóyún ọmọ ọdún19
- Pásítọ̀ onísọjí tó fí ipá bá olóyún oṣù mẹ́jọ sùn ní Ondo, ohun tí a mọ̀ rèé
- Fásitì fi ọwọ́ òsì júwe ilé fún olùkọ́ tó nawọ́ eré ìfẹ́ sí akẹ́kọ̀ọ́
- Arákùnrin kan r'ẹ́wọ̀n ọdún 24 he lórí ẹ̀sùn ìbálòpọ̀ pẹlú ọmọ ìkókó
- Ìjọba ìpínlẹ̀ Osun dóòlà ọmọ ọdún méje tí alágbàtọ́ rẹ̀ n fìyà jẹ
- Èèyàn àti ẹbọra ló péjù-pésẹ̀ síbi ayẹyẹ ogún ọdún tí Eniola Badmus ti n ṣeré ìtàgé
- Ọlọ́pàá ti kó àwọn afurasí tí wọ́n bá òkú Demilade nínú 'cooler' nílé wọ́n ni Ekiti lọ sílé ẹjọ́
Bakan naa ni Ayegba ṣoju Naijiria ninu idije ere bọọlu awọn obinrin ilẹ Afirika lọdun 2006 ati 2008.Ọdun mọkanla ni o fi gba bọọlu jẹun lorilẹ ede Finland ki o to lọ fun ẹkọ olukọni ere bọọlu.Iwe iroyin UK's Evening Standard sọ pe o kere tan awon awakọ bọọsi n N14m lowo oṣu ni UK.Ayegba to jẹ ẹni ọdun marundinlogoji tiẹ sọ fun iwe iroyin Evening Standard pe bi oun ṣe jẹ agbabọọlu tẹlẹ ri n ran oun lọwọ lati ṣiṣẹ dẹrẹba dara dara.Ayegba ni oun ti maa lọ UK fun họlude tẹlẹ nigba ti oun fi gbabọọlu ni orilẹ ede Finland.Lati agbegbe Victoria si Lewisham bọọsi ti Ayegbe n wa n na lẹyin ọdun mẹta ti o ti n gbe orilẹ ede UK bayii.








