Eko the Tiger: Kà nípa bí ẹkùn tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Eko ṣe fi apá olùtọ́jú rẹ̀ ṣe ipanu lọ́san gaan

Oríṣun àwòrán, NAPLES ZOO/Reuters
Iroyin eleyi ni ṣe pẹlu Ẹkun kan ati olutọju rẹ ni aaye igbẹrankopamọ si to wa.
Gẹgẹ bi a ti ṣe gbọ wọn ti yinbọn pa ẹkun naa lẹyin to bu apa arakunrin ẹni ogun ọdun to n tọju rẹ jẹ.
Bawo wa lo ti ṣe ṣe to jẹ pe apa arakunrin yi lo fi ṣe ara rindin?
Ẹ tẹti bẹlẹjẹ maa fọkan ba ọrọ naa bọ.

Eko lorukọ ẹkun taa n wi yi wọn si n tọju rẹ ni ibudo igbẹrankopamọ to wa ni Florida.
Lọsan ọjọ kan ti arakunrin ẹni ogun ọdun to n tọju rẹ laaye ibi ti ko yẹ ni ẹkun naa ti doju ija kọ.
Awọn agbofinro to wa sibi iṣẹlẹ naa sọ pe awọn gbiyanjulati gba arakunrin naa lọwọ ẹkun ọhun ṣugbọn ko gba.
Aṣẹyinwa aṣẹyinbọ, wọn pada yinbọn pa ẹkun naa lati yọ apa arakunrin ọhun lẹnu rẹ.
Wọn gbe arakunrin naa lọ si ile iwosan nibi to ti n gba itọju.

Ile igbẹrankopamọ naa sọ pe iṣẹ ti wọn gba arakunrin naa fun ni pe ko maa tun ile igbọnsẹ ati ile itaja ṣe .
Ko lẹtọ bi wọn ti ṣe sọ lati wọ aaye ibi ti ẹkun naa wa.
A gbọ pe ẹkun naa ti wa ni aaye igbẹrankopamọ naa si lati ọdun 2020.
Iku rẹ jẹ eleyi to dun ọpọ awọn olugbe agbegbe naa nitori awọn eeyan lo dawo ki wọn fi le gba ẹkun naa wa sibẹ.
Awọn ẹkunMaly bi iru ti Eko yi sọ wọn.Kaakiri agbaye iru rẹ to ṣẹku ko ju igba lọ gẹgẹ bi ajọ to n risi itọju awọn ẹranko World Wildlife Fund ṣe wi.












