Child marriage: Ààrẹ Philipines gbé òfin tí yóò fìyà jẹ ẹnikẹ́ni tó bá fẹ́ ọmọ dé kalẹ̀

Oríṣun àwòrán, AJ+
Aarẹ orileede Phillippines, Rodrigo Duterte, tí buwọ́lù ofin tó sọ fifi ọmọde fun ọkọ di ẹsẹ tó ní ijiya labẹ ofin.
Gẹgẹ baa ṣe rí ka ninu awọn iwe aṣẹ to jade, ẹwọn ọdun mejila ni ẹnikẹni tó bá wu iru iwà yi yóò fi gbara.
Lọjọ Kẹwa oṣù Kejìlá ọdun 2021 lo fọwọ sí ofin yii.
- Àwọn afurasí darandaran ṣoró ní ìpínlẹ̀ Ondo, wọ́n pa ènìyàn mẹ́ta, jó ọ̀pọ̀lọpọ̀ ilé àti oko
- Ọwọ ọlọ́pàá tẹ ọmọ ọdún 15 mẹ́ta lásìkò tí wọ́n fẹ́ fi èèyàn ṣe òògùn owó
- Mi ò ní sin òkú ọmọ mi títí màá fi rí ìdájọ́ òdodo gbà, kò báà jẹ́ ọgbọ̀n ọdún - Baba Sylvester Oromono
- Mi ò retí kí àwọn ọmọ Naijria gbóríyìn fún mi lẹ́yìn ìṣèjọba mi - Buhari
- Àwa náà ṣetán láti ma gbé oúnjẹ àti máàlù wà silẹ Igbo- Oloúnjẹ̀ ilẹ̀ Àríwá
- Oṣù díẹ̀ ṣẹ́yìn lé fún mi nítorí bí ojú ìyá mi tó fọ́ ṣe tún le koko - Funmi Awelewa
- Ènìyàn mọ́kàndínlógún pàdánù ẹ̀mí wọn nínú ìjàmbá ọkọ̀ ní Kano
- Ilé Ìgbìmọ̀ Aṣòfin orílẹ̀ èdè Kenya dá aṣòfin kan dúró nítorí súùtì
Ninu rẹ, wọn ka silẹ pe ìjọba ri "fifi ọmọde fun ọkọ gẹgẹ bí iwa ifiyajẹ ọmọde, eleyi to tabuku tó sì yẹpẹrẹ awọn ọmọde naa."
Labẹ òfin yii, ẹni to ba fi ọmọde fun ọkọ tàbí to se agbatẹru fifi ọmọde fun ọkọ le se ẹwọn ọdun mẹfa sí mejila pẹlu owo itanran.
Wọn tun le gbà irufẹ ọmọ bẹẹ kuro lọwọ obi tabi alagbatọ to ba se iru ẹ.
Bẹẹ lofin táa n wí yi tun sọ pe ẹnikẹni tó bá gbé ọmọde sile bi iyawo lọnà aitọ, yóò fi ẹwọn ọdun mẹfa tabi mejila gbára pẹlu owó itanran.
Ko sí eyikeyi igbeyawo pẹlu ọmọde ti ofin tuntun yi faaye gba.
Ajọ Oxfam International sọ pé, o kere tan awọn 726,000 ọmọdebinrin lawon eeyan n gbe ni'yawo lorileede Phillippines eleyi to mu ki wọn jẹ orile-ede kejila lori iwọn ti iru iṣesi yi ti n waye julọ.
Apa guusu ilẹ naa tii ṣe Mindanao ni iṣesi yi ti pọju lọ papaa laarin awọn Musulumi to n fẹ ju iyawo kan lọ.
Lagbegbe yi, wọn a máa n fẹ awọn ọmọdebinrin tọjọ orí wọn kò ju ọdun mẹtala lọ.
Awọn aiṣedede ati dọgbadọgba to n waye láwùjọ a máa ṣe okunfa iru isesi yi paapa laarin awọn ti ko rọwọ họri láwùjọ ati l'awọn ibi ti ikọlu ba ti n waye.
Ireti ijọba ni pe "ofin tuntun yi yoo yi awọn aṣa atijọ ti ko da to pada."
- Ẹgbẹ̀rúndínlàádọ́ta àwọn Agbéṣùmọ̀mí láti ṣekúpa láàrín oṣù méje- Iléeṣẹ́ ológun Nàìjírà
- Ka nípa àwọn Fásìtì 25 péré tí àjọ NUC ní ètò ẹ̀kọ́ wọ́n kájúẹ̀ ní Nàìjíríà
- Lásìkò ìséde Covid 19, wo bí àwọn olùgbé ìlú yí ṣé n fí fóónù ṣé pàṣípààrọ̀ oúnjẹ
- Inú wa dún pé Oba Oke dá ẹ̀mí Iyabo Oko padà, a gbàgbọ́ pé ìya wa ṣì máa gbádùn pẹ̀lú àdúrà- Omo Iyabo Oko
- Ìgbìmọ̀ Afọbajẹ ilú Ìbàdàn buwọ́lu Lékan Balógun gẹ́gẹ́ bí Olúbàdàn tuntun ṣùgbọ́n....
- Ìjọba Nàìjíríà kéde àwọn agbébọn gẹ́gẹ́ bíi agbésùnmọ̀mí káàkiri Nàìjíríà













