Adebayo Shittu: Ọ̀rọ̀ Boko Haram ti kọjá Buhari nìkan, àwọn èèyàn kan lókèrè ló fẹ́ ba iṣẹ́ Buhari jẹ́
"Ṣe ẹ ro pe aarẹ Buhari funra rẹ ki awọn agbenipawo ati Boko Haram maa ṣe ọṣẹ bi wọn ṣe n ṣe yii?".
Gbajumọ oloṣelu lorilẹede Naijiria to tun jẹ minisita fun ibanisọrọ to ṣẹṣẹ pari saa rẹ ni Agbẹjọro Adebayo Shittu to si fi ilu Ibadan ṣe ibugbe.
Adebayo Shittu kẹnu bọ ọrọ rẹpẹtẹ ninu ifọrọwanilẹnuwo pẹlu BBC yoruba to si n gbe lẹyin aarẹ Muhammadu Buhari pe ki awọn eeyan to n buu naa fi ara si ipo rẹ.
"Gbogbo awa ọmọ Naijriria naa la ni aiṣedede, awọn olori wa, wọn o jabọ latọrun, inu wa naa ni wọn ti jade".
Adebayo boju wo gbogbo bi nkan ṣe n lọ lọwọlọwọ lorilede Naijiria eyi to n mu ki ọpọlọpọ maa sọ pe ijọba Buhari ko dara.
"Buhari àti ìjọba rẹ̀ ń làágùn, ìyẹ́ àdiyẹ wọn ni kò jẹ́ kí ẹ mọ̀".
Adebayo ni awọn kan to fara sin si awọn orilẹede okere kan lo ṣaa fẹ fi dandan ba gbogbo iṣẹ ati akitiyan aarẹ Muhammadu Buhari jẹ paapaa lori eto aabo ni Naijiria.
O ni awọn yii lo n ko oniruuru nkan ijagun nla nla fun ikọ Boko Haram atawọn ẹgbẹ adigunjale mii to n fitina orilẹede Naijiria lọwọlọwọ.
- Àwọn Oba Yorùbá kan rèé tí wọ́n rọ̀ lóyè, tí Oba míràn jẹ lójú ayé wọn
- 'Kàǹkàn ìbílẹ̀, òògùn, àwọ̀tẹ́lẹ̀ àti fóònù lá bá lẹ́gbẹ̀ẹ́ òkú obìnrin tí wọ́n dédé jù sí àdúgbò wa l'Akure'
- Mọ̀ nípa àìsàn tó ń mú ǹkan ọmọkùnrin lè gìdìgbà láì rọlẹ̀
- 'Àwa Ọlọ́pàá ò lè sọ bóyá lóòtọ́ ọmọ Yahoo ló ju òkú obìnrin s'ẹ́gbẹ̀ẹ́ ṣọ́ọ̀ṣì, ẹní bá mọ̀ọ́ kó fojú hàn'
- Dandan kọ́ ni kí o ṣe àyẹ̀wò DNA tí kò bá sí ẹni tó n bá ọ du ọmọ rẹ - Rotimi Salami
- Ẹ̀yin obìnrin, ẹ má fọkàn síi pé gbogbo ènìyàn ló máa fi iṣẹ́ ọfíìsì jẹun, ẹ wo àwòkọ́ṣe mi - Adekemi Olugbade



