Nigerian Yahoo Boys in Texas: Ọwọ́ FBI tẹ ọmọ Nàìjíríà ẹní ọdún 51 àtàwọn mìí lórí ẹsùn Yahoo yahoo ní Texas

Awọn ọmọ Naijiria mọkanla yoo foju ba ile ẹjọ lorileede Amẹrika lori ẹsun gbajuẹ ori ayelujara taa mọ si yahoo yahoo.
Ikede yi waye lati ẹnu adele agbẹjọro agba fun agbegbe ariwa Texas Prerak Shah.
O fi ọrọ yi sita lọjọru to kọja to si ṣalaye pe pupọ awọn arugbo lo ko si ọwọ awọn olubi wọn yi to lu wọn ni gbajuẹ to ni ṣe pẹlu ọrọ ifẹ.
Orisirisi ẹsun ni wọn fi kan awọn mọkanla wọnyi ti awọn alaṣẹ si sọ pe itakun awọn oni gbajuẹ yi ta kaakiri ṣugbọn ni Naijiria ni wọn ti ṣẹ wa.
Gẹgẹ bi awọn iwe ipẹjọ awọn arugbo ti ko lọkọ tabi iyawo tabi ti ọkọ wọn ti ṣalaisi lawọn oni jibiti wọn yi doju le pupọ.
Wọn ni niṣe ni wọn yoo lo ayederu orukọ ti wọn si lọ n lu awọn eeyan ni gbajuẹ loju opo tawọn eeyan ti n wa ololufẹ bi Match.com, ChistianMingle, JSwipe, ati PlentyofFish
Ni kete ti wọn ba ti ri awọn ti wọn n wa ololufẹ, irọ banta banta ni wọn maa n pa fun wọn lati le gba obitibiti owo dọla lọwọ wọn.
- Ìdí tí mo fi ń dé fìlà Abetiaja nì gbogbo ìgbà nìyìí - Alaafin
- Ìgbẹ́jọ́ ti bẹ̀rẹ̀ lórí ẹ̀sùn Baba Ijesha àti Princess tó ní ó fẹ́ bá ọmọ òun lájọṣepọ̀
- Ọwọ́ òfin ti tẹ ọ̀pọ̀ ọmọ Nàìjíríà lórí ẹ̀sùn jìbìtì l'Amẹrika- FBI
- Ọba Tejuosho tẹ ojú lọ́balọ́ba mọ́lẹ̀ fún ṣíṣe jìbìtì ìfẹ́ orí ayélujára - Ìgbìmọ̀ Afọbajẹ
- Ṣé o tí gbọ́ nípa eNaira, owó àìrí tuntun tí CBN ṣe ìfilọ́lẹ̀ rẹ̀? Nkan tí ó ní láti mọ̀ rèé
- Yàjó yàjó: Àwọn ajínígbé soro l'Eko, wọ́n jí Ọ̀gágun ojú òfurufú Sikiru Smith gbé
Agbẹjọro agba Prerak Shah sọ pe ''iru ẹsẹ yi buru jai nitori wọn lu awọn eeyan yi n gbajuẹ owo ati ọkan nitori pupọ n ṣe idaro airi eeyan ba sọrọ lọwọ lasiko ti wọn tu gba owo lọwọ wọn''
Ẹsun ti wọn fi kan awọn wọnyi niṣe pẹlu iru rẹ kan to ti ṣaaju waye ni iwọ oorun agbegbe Texas nibi ti ijọba ti fẹsun kan eeyan mẹtalelogun mii lori ẹsun gbajuẹ ori ayelujara.
Ninu awọn ti ijọba fẹsun kan ni ariwa Texas la ti ri
•David Animashaun, ẹni ọdun 38
•Oluwalobamise Michael Moses, ẹni ọdun 40
•Irabor Fatarr Musa, ẹni ọdun 51
•Ijeoma Okoro, ẹni ọdun 31
•Chukwemeka Orji, ẹni ọdun 36
•Emanuel Stanley Orji, ẹni ọdun 35
•Frederick Orji, ẹni ọdun 37
•Uwadiale Esezobor, ẹni ọdun 36
•Victor Idowu, ẹni ọdun 36
•Afeez Abiola Alao, ẹni ọdun 37
•Ambrose Sunday Ohide, ẹni ọdun 47
Lọwọ bayi,wọn kan ṣi fẹsun kan awọn ti ijọba kede orukọ wọn ni.
Bi wọn ba fi le da wọn lẹbi ni ile ẹjọ, o ṣeeṣe ki wọn ṣe to ẹwọn ọdun mẹwa si ogun ọdun.














