Dino Melaye ni àbímọ́ ni iṣẹ́ tíátà àti òṣèlú jẹ́ fún òun

Dino Melaye pẹlu Oṣere Desmond Elliot

Oríṣun àwòrán, dinomelaye

Sẹnetọ orilẹede Naijiria nigbakan ri, Dino Melaye ti ṣalaye pe ayanmọ oun latọrun wa ni lati ṣe ere tiata ati lati jẹ oloṣelu.

Lasiko to fi n ba awọn oniroyin sọrọ nibi afihan sinima kan to kopa ninu rẹ eyi ti wọn pe akori rẹ ni 'Lemonade' lo ti sọ bẹẹ.

Asofin Naijiria tẹlẹ ri

Oríṣun àwòrán, dinomelaye

Ṣe ẹ si mọ pe ọmọ ti yoo ba jẹ aṣamu, ati kekere ni iru wọn ti n ṣẹnu ṣamuṣamu.

Sẹnetọ Melaye tun ṣalaye pe idi ti oun fi kopa ninu ere sinima naa ni lati jẹ ko di mims fawọn ọmọ orilẹede Naijiria pe asiko to ki wọn bọ kuro ninu iṣoro wọn.

Àkọlé fídíò, Taa gan ló ń jí orin àti ohùn ara wọn lò nínú Adewale Ayuba àti Ajebori

O wa ke si ijọba lati gbe awọn ofin kalẹ ti yoo ṣe agbedide ẹka amuludun lorilẹede Naijiria.

Melaye ni "wọn bi mi mọ ere tiata ati oṣelu ni" ati pe ẹka to lamilaaka ni ẹka amuludun lorilẹede Naijiria eleyi to ni o fẹ loju ju ẹka epo rọbi lọ.