Lagos-Ibadan Express: Ijọba àpàpọ ti ṣí afára Kara lẹyin àtúnṣe rẹ̀.

OPOPONA

Oríṣun àwòrán, FRSC

Àkọlé àwòrán, Ijọba àpàpọ ti ṣí afára Kara lẹyin àtúnṣe rẹ̀.

Ijọba àpapọ Naìjíríà ti ṣí òpópónà Lagos -Ibadan Express lẹ́yìn ti wọ́n pari àtúnṣe ẹgbẹ̀tá míta tó bàjẹ lojú ọ̀nà náà.

Ìròyìn sọ pé apá ibikan ní ìhà àfárá Kara àti Oríta Ishẹri ti ènìyàn ba fẹ́ wọ ìlú Eko ni wọ́n tì pa láti ọjọ kejì, oṣù kẹsàn an láti ṣe àtúnṣe.

Ati pe eyi si ló fa a ti wọ́n fi ń dári ọkọ si ọ̀na ibòmiran.

Abẹ̀wò àwọn akọròyìn si àgbègbè náà sàfihàn pé àwọn eléto ààbo àti àwọn oṣìṣẹ́ tó ń moju to ìgbòkègbodo ọkọ, pẹ̀lú àwọn òṣíṣẹ̀ ilé iṣẹ́ ìrìnnà, agbára àti ilé ìgbé wà níkalẹ̀ láti moju to ṣíṣí ọ̀nà náà.

Bakan náà ni àwọn alábojúto igbokedgbodò ọkọ (FRSC) dúro si òpin afára náà láti maa dari àwọn oní móto si ojú ọ̀na tuntun ti wọ́n ṣi.

Àkọlé fídíò, FUTA: Àwọn mẹ́jọ ló ṣíná ìyà fún Bolu ní FUTA

Igbakeji adari àjo náà, Taofik Iyanda wá fi ìdúnnú rẹ̀ hàn sí irú àtúnse to wáye loju opópóna marosẹ náà, bákan náà lo dupẹ lọ́wọ ijoba apapọ fun atunṣe oju popo ọhun.

FRSC

Oríṣun àwòrán, FRSC

Àkọlé àwòrán, Ijọba àpàpọ ti ṣí afára Kara lẹyin àtúnṣe rẹ̀.

O rọ àwọn awakọ láti maa rọra ṣe lóju pópó náà, àti pe wọ́n kò gbọ̀dọ kọja ìwọn ìjánu ti wọ́n ni ki wọ́n maa rin loju pópó marosẹ.

Àkọlé fídíò, Wòólì Alfred kú lọ́dún 1964, ó tún padà wà sí ìlú Agelu f'ọ́jọ́ mẹ́rìnlá!