Fuji: Èmi àti Adewale Ayuba ò ja, Ọlọ́run ló fún mi lóhùn t'èmi - Ajebori Onifuji

Àkọlé fídíò, Taa gan ló ń jí orin àti ohùn ara wọn lò nínú Adewale Ayuba àti Ajebori

Asimiyu Ajebori lorukọ tirẹ ti ọpọ mọ si "Ọmọ gba Feeder".

Gẹgẹ bo ṣe sọ ọ̀, Ajebori ni oun ko kọ orin lọdọ ẹnikẹni tabi ji ohun olohun lo rara.

Ajebori ni orin Apala ni Baba oun n kọ ti iya rẹ́naa si jẹ olorin pẹlu.

Ẹwẹ bi ẹ ko ba tii gbojusoke wo aworan to wa ninu fidio yii, ohun ti ẹ n gbọ lasan a jẹ ki ẹ ro pe Adewale Ayuba lo n kọrin ni.

Ṣugbọn nigba ti Ajebori tẹnu bọrọ fun BBC Yoruba, o ni "kí n tó bẹ̀rẹ̀ orin tèmi, mi ò m'ẹni tó ń jẹ́ Ayuba",

síbẹ̀, bí ẹ̀pà l'ohùn àti ijó Ajebori àti Adewale Ayuba jọ ara wọn ti ọpọlọpọ si n beere pe taa gan lo n ji orin ati ohun ara wọn lo ninu awọn mejeeji.

1983 lo bẹrẹ orin tirẹ gangan.

Idahun wa lẹkunrẹrẹ ninu fidio yii.