Yoruba Culture: Wo àwọn ẹ̀yà ara rẹ̀ níbí lédè Yorùba

Àkọlé fídíò, Àwọn ọ̀jọ̀gbọ́n Yorùbá foríkorí gbé ìwé tó lè sọ ẹ̀yà ara yín lédè Yorùbá.

Ṣe ẹ mọ pe iwe kan tiwa to n sọ itumọ ẹya ara yin lede?

Ẹgbẹ awọn akọsẹmọṣẹ ninu ede Yoruba kora jọ gẹgẹ bi awọn ọjgbọn ede lati ṣe ohun iwuri yii latari pe wọn ko fẹ ki aṣa Yoruba parun.

Aworan ẹya ara

Ọpọlọpọ lo ti n n lo ilana aṣọ wiwọ, ounjẹ, ilu ati ijo gẹgẹ bi ọna tiwọn lati gbe aṣa Yoruba larugẹ ṣugbọn ni ti awọn ọjọgbọn yii, imọ ọpọlọ ati ọgbọn ori ni wọn fi fikuluku ti wọn forikori lati ṣe agbejade iwe yii.

Ẹya ara ọkunrin, obinrin koda ti ewurẹ, awọn egungun ati ẹya ara inu ẹni pẹlu ọpọlọpọ nkan mii lo ye yekeyeke ninu iwe naa.

Aworan ẹya ara

Ọgbẹni Emiola Oluwabunmi to jẹ ọkan lara awọn onimọ naa jẹ ko di mimọ pe yoo tun wulo fun awọn ẹya tabi ede miiran to jẹ pe ede Yoruba ni wọn fi n kọ ara wọn to fi mọ ni awn ileewe alakọbẹrẹ.

Lara awọn to gbe eto yii kalẹ mii tun ṣe afiwe imọ ede ni Naijiria pẹlu ti awọn orilẹede to ti dagba soke bii China to jẹ wi pe wọn maa n fi ede abinibi wọn yangan nibikibi.

Ko da wọn fẹ kawọn onimọ iṣegun oyinbo to fi mọ awọn ọmọ ileewe to n kọ nipa imọ iṣegun oyinbo mu anfani yii lo daadaa.