Online Match Making: Ṣé aburú wà lórí yíyan ọkọ àbí aya lórí ayélujára?

Oríṣun àwòrán, KEMDI
Yoruba bọ wọn ni airin jinna, ni airi abuke ọkẹrẹ, bi eeyan ba rin jinna, yoo ri ibi ti wn ti n fi odo ibulẹ jẹun.
Rẹgi ni owe yii si ṣe pẹlu bi awọn obinrin ode oni ti ṣe bọ si oju ayelujara lati maa wa ọkọ, ti wọn si gbagbe asa wa to so mọ eto igbeyawo ati alarina.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Kí ló wà láàrin Olorì Badra àti Bobrisky, tí ọ̀rọ̀ wọn fi wọ̀?
- Wákàtí méjì àbọ̀ ní akẹ́kọ̀ọ́ yóò fi kẹ́kọ̀ọ́ lójúmọ́ - Ìjọba Oyo
- Bí pínpín owó ilù ṣe díjà sílẹ̀ láàrin àwa ìjòyè àti Oluwo rèé - Osa Iwo
- Ẹ wo àkọsílẹ̀ ọ̀pọ̀ ẹbùn tí ìkọ̀ọ̀kan olùdíje BB Naija tó kú nínú ilé, ti jẹ
- Kí ló mú kí ọkọ̀ kan tó jóná ráùráú lórí afárá Ojuelegba?
- Kíni 'Ẹ̀lẹ̀ daddy' Olorì Abbey Adeyemi ṣe tí ojú òpó ayélujára Instagram rẹ̀ fi ń yeruku lálá?
- Ìkébé mi tóbí ju ohun tí mo lè dọwọ́ bò lọ, n kìí fí ṣakọ- Nkechi Blessing
- Ẹ̀yin òṣìṣẹ́, ẹ má ṣáì lọ síbi iṣẹ́ lọ́jọ́ Ajé, olórí àwọn òṣìṣẹ́ ní Nàìjíríà tako ìyanṣẹ́lódì
Kii si ṣe awọn ọlọmọge nikan laa n wi, awọn to ti ṣe igbeyawo to sanpọn ati awọn mii ti ko ri ọkọ gan ko gbẹyin ninu awọn to n wa ọkọ lori ayelujara.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Bi eeyan ba lọ si oju opo Twitter tabi Instagram, to si tẹ ọrọ matchmaking sibẹ, yoo ri pe awọn oju opo alarina tọkọ-taya pọ nibẹ jaburata.
Lọpọ awọn oju opo itakun agbaye wọnyii, awọn obinrin, to fi mọ ọkunrin maa fi iroyin nipa ara wọn, iru ẹsin ti wọn n sin, ati iru ọkọ tabi aya, ti wọn n wa sita.
Diẹ lara awọn oju opo ololufẹ to gbajumọ lori ayelujara nilẹ Naijiria ni matchbybade, halal_matchmaking ati abujamatchmaking.
This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of Instagram post, 1

End of Instagram post, 2
Ki lo n mu awọn obinrin gbe iru igbesẹ yii?
Aṣa Yoruba, lo ni ilana tirẹ nipa ọkọ fifẹ tabi iyawo nini, eyi ti a daye ba.
Bi a ti ṣe jogun ba lọdọ awọn babanla wa, bi ọkunrin ba ri obinrin to wu lọkan, yoo lọ nipasẹ alarina lati kan si awọn obi obinrin naa.
Ojuse alarina si ni lati mọ hulẹ hulẹ nipa itan idile obinrin naa ati iru aisan to n se wọn ninu idile wọn.
Bi ọrọ ba wọ, ohun to kan ni ki wọn ṣe idana, ki igbeyawo si tẹle.
Gẹgẹ bi iwadi ti fi ye wa, lara awọn ohun to n mu ki obinrin maa wa ọkọ lori ayelujara tawọn kan sọ ni iwọnyii:
- Igbagbọ pe obinrin pọ ju ọkunrin lọ nitori naa ati ri ọkọ ṣoro diẹ
- Ailootọ awọn ọkunrin naa jẹ idi kan ti awọn obinrin mii fi sọ pe awọn n kan si oju opo lati mọ ẹni ti ko ni ṣaburu fun awọn
- Airaye ọpọ obinrin ode oni nitori iru iṣẹ ti wọn ṣe
- Onitiju lawọn obinrin mii ti wọn kii ṣaba ni ọrẹ pupọ
- Erongba lati fẹ ẹni to niṣẹ lapa, pupọ obinrin ni ko fẹ ọkọ ti ko ni le gbọ bukata wọn, ti eto alarina oju ayelujra yii si fun wọn lanfaani lati wa ẹni to niṣẹ lọwọ.
Iha wo lawọn eeyan Naijiria kọ si iṣẹlẹ yi?
Lọpọ igba ọkunrin lo maa n sọ ero ọkan lati fẹ obinrin.
Amọ ṣa ko saburu ti obinrin naa ba ni oun nifẹ ọkunrin yala labẹ ẹsin tabi aṣa Yoruba.
Erongba awọn eeyan lori ọrọ si ṣe ọtọọtọ
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 1

End of X post, 2

End of X post, 3
Ilẹ Yoruba nikan kọ ni o ti n ṣẹlẹ:
Ni oke ọya Naijria to ṣe pe wọn ko faramọ ki obinrin maa ṣe afihan ara rẹ si awọn ọkunrin, aṣa wiwa ọkọ loju ayelujara yii naa ti n gbalẹ nibẹ.
Ninu iwadii kan ti ileeṣẹ BBC ṣe, a ṣe alabapade oju opo pupọ ti awọn obinrin ti n wa ọkọ.

Oju opo wọnyii ti o jẹ ti ajọ aladani a maa fun awọn eeyan lanfaani lati wa ọkọ tabi iyawo.
This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of Instagram post, 3

End of Instagram post, 4

End of Instagram post, 5
Ṣe aburu wa ninu wiwa ọkọ loju opo ayelujara?
A ko le sọ pato boya anfaani wa tabi ko si ninu yiyan ọkọ abi aya lori ayelujara nitori iriri onikaluku se ọtọọtọ.
Nibi tawọn kan ti n ri ọkọ tabi iyawo fẹ lori ayelujara, bẹẹ naa ni awọn miran n pade awọn aṣebi loju opo ayelujara.
Amọ ṣa, awọn onimọ nipa ọrọ ifẹ fi ikilọ sita pe, ki awọn eeyan fi ọgbọn ati oye lo loju opo ayelujara, ki wọn maa ba gbe eegun eleegun.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 4
Ninu amọran wọn miran ni pe, ki awọn eeyan yii gbiyanju lati mọ ẹni ti wọn ba ṣalabapade daadaa nipa ibeere ati itọpinpin to peregede.
Wọn ni ki a maa gbagbe pe ọpọ alangba lo dakun de ilẹ, a ko mọ ẹni ti inu n run ninu wọn, ti asebi kii si kọ siwaju ori.,
Ki eledua ṣe ọkọ ati aya rere fun gbogbo mutumuwa.