Ìjọba Eko ti bẹ̀rẹ̀ sí ní rún àwọn ọ̀kadà tí wọ́n gbà gẹ́gẹ́ bí wọ́n se sèlérí

Ijoba ipinle Eko ti bẹ̀rẹ̀ si ni mu ileri wọ́n se bayii.
Eyi waye lori awon okada alupupu ti ọwọ́ tẹ̀ lẹ́yin ofin tui Gomina Sanwo Olu se lori olokada ni awon agbegbe kọ́ọ́kan ni ipuinle Eko

Ijọba ibilẹ mẹfa ni ijọba ti fofin de wiwa ọkada, ti awọn agbofinro si mu wa si imuṣẹ ni awọn ijọba ibilẹ bii Eti-Ọsa, Ikẹja, Surulere, Lagos Mainland, Lagos Island ati Apapa.
Bakan naa ni wọn fikun un pe Ọjọ Ẹti ni awọn yoo ru awọn ọkada womuwomu. Agbẹnusọ fun ileeṣẹ ọlọpaa, Benjamin Hundeyin sọ fun BBC pe o kere tan ogoje ọkada ni awọn ti gba.
O ni awọn gba ọkada naa ati awọn ti wọn ba fi ọkada jiṣẹ nitori o gbe eniyan kan, eleyii to tako ofin ipinlẹ Eko.
Kini ijiya fun ọkada ti ọwọ ba tẹ?
Ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Eko ni ki awọn eniyan gbagbe nipa ọkada ti ọwọ awọn ba ti tẹ nitori ko tun kan ọwọ wọn mọ lailai.Wọn ni ileẹjọ ni awọn yoo gbe ẹni to n wa ọkada naa ati ẹni ti wọn gbe lọ.
Ijoba ìpínlẹ̀ Eko bẹ̀rẹ̀ fífi òfin de àwọn ọlọ́kadà ní ìjọba ìbílẹ̀ mẹ́fà, rọ àwọn ará ìlú láti fọkàn balẹ̀

Ijọba ipinlé Eko ti rọ awọn ara ilu lati fi ọkan wọn balẹ lẹyin fifi ofin de irina awọn ọlọkada ni agbegbe ijọba ibile mefe ni ipinlẹ naa.
Awọn ijọba ibilẹ naa ni Ikeja, Surulere, Eti-Osa, Lagos Mainland, Lagos Island ati Apapa.
Gomina ipinlẹ Eko, Babjide Sanwo -Olu ni o ṣapejuwe igbesẹ naa gẹgẹ bi ọna akọkọ lati da aabo bo awọn ara ilu.
Ijọba ti ni o ti bẹrẹ si ni gba kẹkẹ Maruwa ati Ọkada to ba ti kọja ala ti wọn fi de wọn.
Wọn ni bio tilẹ jẹ pe Ọjọ Kini, Oṣu Kẹfa ni gbedeke ti ijọba fi lede lati fofin de lilo ọkada ati maruwa ni awọn opopona ati ijọba ibilẹ, awọn ti bẹrẹ si ni gba awọn ọkada to ba ti rufin.
Wọn ni awọn ijọba ibilẹ mẹfa ti ofin naa de ni Eti-Osa, Ikeja, Lagos Island, Lagos Mainland, Apapa ati Surulere.
“Lẹyin ayẹwo wa lori bi awọn ọlọkada se n sisẹ ni ijọba ibilé mefa ti a fi ofin de ni ọjọ kini oṣu kẹji ọdun 2020, a ri pẹ iwabajẹ laarin awọn ọlọkada ni ko dikun rara.
“Ni bayi, Ijọba ipinlẹ Eko ti wa fi ofin ti o lọjọ de awọn ọlọkada ni ijọba ibile mefa, ti o bere bere lati ọjọ kini oṣu kefa ọdun 2022.”

Ìdí tí Ìjọba ìpínlẹ̀ Eko fòfin de ọ̀kadà ní ìjọba ìbílẹ̀ mẹ́fà
Ijọba ipinlẹ Eko ti fofin de awọn ọlọkada ni ijọba ibilẹ mẹfa ọtọtọ ni ipinlẹ naa nitori eto abo.
Ofin tuntun yii ni yoo bẹrẹ si n fẹsẹ mulẹ lati ọjọ kinni, oṣu Kẹfa, ọdun 2022 yii.
Sanwo-Olu lo fi ikeke naa sita lọjọbọ lasiko ipade kan pẹlu awọn agbofinro.
O ni "A ko fẹ ri ọkada kankan ni awọn agbegbe bii Ikeja, Lagos Mainland, Lagos Island, Eti-Osa, Surulere, ati Apapa mọ."
"Ofin tuntun yii jẹ ibẹrẹ iru rẹ, ofin naa yoo si bẹrẹ si n mulẹ lati ọjọ kinni, oṣu Kẹfa, ọdun ti a wa yii."
"A fẹ ki awọn ọlọkada mọ pe kii ṣe awọn agbegbe ti a darukọ yii nikan ni ako ti fẹ ri wọn mọ, ki awọn to wa lagbegbe to ku tete lọ maa wa iṣẹ mii ṣe."
Lara awọn to wa nibi ipade ti ikede naa ti jade ni awọn ọga ọlọpaa kaakiri ipinlẹ Eko, to fi mọ awọn mii ti ọrọ eto eto abo kan.
Sanwo-Olu sọ siwaju nibi ipade naa pe "A ti n bu yin gbọ bayii, pe lati ọjọ kinnu, oṣu Kẹfa, a ko fẹ ri awọn ọlọkada kankan laarin igboro awọn ibi ti a durukọ yii mọ."
'Sound Engineer' ti awọn afurasi ọlọkada pa nitori N100
Bo tilẹ jẹ pe kii ṣe igba akọkọ ree ti ijọba ipinlẹ Eko yoo fofin de ọlọkada, iroyin ni igbesẹ tuntun yii ko ṣẹyin iku okunrin kan ti orukọ rẹ n jẹ David Imoh ti awọn afurasi ọlọkada kan pa.
Awọn afurasi naa tu ologbe ọhun si ihoho, wọn lu niluu bara, wọn si tun dana sun Lekki, eyii to wa ni ijọba ibilẹ Eti Osa.
Ṣaaju ikede yii lọjọ Aje ni ijọba Eko ti kọkọ gbẹsẹle awọn ọkada ti iye rẹ ko din ni mẹtalelọgọfa ni Eti Osa yii kan naa, ti wọn si tun fi ṣikun mu awọn to n wa awọn ọkada ọhun.












