Ìyá Olúmọ Abẹ́òkúta jáde láyé lẹní ọdún 137

Aworan Iya Olumo

Oríṣun àwòrán, Omo Lamurudu

Aworan iya Olumo

Oríṣun àwòrán, Omo Lamurudu

Iroyin to tẹ wa lọwọ lakoko yi ti sọ pe Oloye Arabinrin Sinatu Adukẹ Sanni ti ọpọ awọn eeyan mọ si Iya Olumọ ti jade laye.

BBC YORUBA gbọ pe Iya Olumọ jade laye sinu ile rẹ to wa Itoko niluu Abẹokuta, ipinlẹ Ogun, laarọ Ọjọru, Wẹside, ana.

Ori oke Olumo ni Iya Olumo wa ni iya to

Ọdun 1885 ni wọn bi Iya Olumọ, to si lo ọpọlọpọ igbesi aye rẹ labẹ oke to gbajumọ daadaa lagbaye, eyi ti wọn fi sọri ilu Abẹokuta, iyẹn Olumọ.

Iya Olumọ lo wa ni iṣakoso bi wọn ṣe n bọ oke Olumọ lọdọọdun, to si mọ pupọ nipa bi wọn ṣe tẹ ilu Ẹgba, to jẹ olori ilu to wa niluu Abẹokuta.

Iya yii tun wa nibẹ bi wọn ṣe yan Alake ilẹ Ẹgba mẹrin ọtọọtọ titi to fi de ori Ọba Michael Adedọtun Arẹmu Gbadebọ.

Ẹkunrẹrẹ iroyin naa n bọ laipẹ.