Ukraine sí ọ̀nà sílẹ̀ láti gbé àgbàdo kọjá kí ìyàn má ba jà lágbáyé.

Oríṣun àwòrán, Google
Orilẹede Ukraine ti ṣi ọna meji silẹ ni Poland ati Romania ki iyan ounjẹ ma bẹ silẹ ni agbaye.
Igbakeji minisita fun ọrọ Ilẹ okeere ni Ukraine, Dmytro Senik lo sọ bẹẹ pe agbaye ti wa ni pepele iyan ounjẹ nitori ogun Russia ati Ukraine.
Wọn ni Russia lo ṣokunfa iyan naa pẹlu bi wọn ṣe dina oju omi ti wọn n gba ko ounjẹ lọ si awọn orilẹede miran lagbaye.
Eyi fa ọwọngogo ounjẹ ati ki ounjẹ ọhun ma pọ yanturu to fun awọn eniyan.
Orilẹede Ukraine ni orilẹede kẹta lagbaye to n ta agbado si awọn orilẹede miran lagbaye, amọ ogun ti wọn n ja pẹlu Russia ko jẹ ki wọn le ko ounjẹ jade lọ.
Amọ Ijọba Ukraine ni awọn n ba Baltic sọrọ lọwọ ki wọn le ṣi ọna miran silẹ fun ounjẹ lati kọja.
Bi o ṣe n lọ ni Ukraine loni ree...
Ado oloro ti wọn ju si ileeṣẹ chemical plant ni Azot ti jẹ ki ina sọ ni agbegbe naa ti araalu to le ni ẹgbẹrin sa pamọ si.
Awọn alaṣẹ Ukraine ni ikọ ọmọogun ilẹ naa ṣi di Azot plant naa mu, ti Russia si sọ pe awọn ko ṣetan lati gba a lọwọ wọn.
Ọmọogun Ilẹ Gẹẹsi tẹlẹri to n ja fun Ukraine ti ri iku he ninu Ogun to n waye naa. Awọn ẹbi rẹ si ti kesi awọn orilẹede lagbaye lati fi ohun ijagun ranṣẹ si Ukraine.
Ikọ ọmọogun Russia ti ba afara to de Severodonetsk ati lysychansk papọ jẹ lẹyin ti wọn ju ado oloro ẹlẹkẹta si.
Ile ounjẹ McDonald ti wọn ṣẹṣẹ tunṣe, ti ṣi ni Moscow loni, labẹ orukọ tuntun ‘vkusno i tochka’ to tunmọ si "tasty and that's it" ni Ede Gẹẹsi.












