May Workers day: Ìkáyàsókè bá àwọn òṣìṣẹ́ nítorí àìmọ ọjọ́ ọ̀la lẹ́yìn Coronavirus

Ọjọ kinni oṣu karun ni ayajọ awọn oṣiṣẹ lorilẹede Naijiria ati lagbaye amọṣa yatọ si iṣoro tawọn oṣiṣẹ n fara gba ni atẹyinwa bii ipenija owo oṣu sisan lasiko, aisi igbega lẹnu iṣẹ lasiko ati oniruuru awọn iwa kotọ miran ti wọn n fi oju wina rẹ lẹnu iṣẹ, lọdun yii, ipenija ajakalẹ arun Coronavirus kun ipenija wọnyi koda o ti mu ẹmi ọpọ ninu wọn lọ.
Lasiko Coronavirus yii lagbaye, awọn oṣiṣẹ ẹka ilera naa lo n fara gba ọfa Coronavirus julọ.
Awọn ogo ọla orilẹede Naijiria lẹka eto ilera ni arun yii ti gba lọ tabi da wolẹ lọpọlọpọ igba.

Oríṣun àwòrán, Babajide Sanwo-olu
Dokita Alfa Saidu ti ọpọ n foju wo gẹgẹ bi eekan ati ogo iṣẹ iṣegun oyinbo kaakiri agbaye jade laye ni opin oṣu kẹta nipasẹ ikọlu arun COVID-19 lẹyin to ti fi ogoji ọdun ṣe iṣẹ iṣegun.
Kii ṣe dokita Alfa Saadu nikan ni dokita to jẹ ọmọ orilẹede Naijiria to tii kagbako arun yii lagbye. Lorilẹede Naijiria, gẹgẹ bi iroyin lati ọdọ ẹgbẹ awọn dokita iṣegun lorilẹede Naijiria, NMA, ọtalelugba o le mẹrin awọn dokita iṣegun oyinbo lo ti fara kan awọn eeyan to laarun coronavirus lorilẹede Naijiria ninu eyi ti ogun dokita ti ni arun yii. Meji ninu wọn lo ti pada bọ sipo alaafia ti mẹta si ti ku.
Ẹwẹ, awọn oṣiṣẹ miran lẹka eto ilera to ti fara kaaṣa arun yii jẹ mẹrindinlaadọrin ninu eyi ti mẹrin ninu wọn ti ku.
Bẹẹni minisita feto ilera lorilẹede Naijiria, NCDC, Dokita Osagie Ehanire ṣalaye pe ọrọ ti kuro nibẹ, nitori pe iye awọn oṣiṣẹ eto ilera to ti ko arun coronavirus bayii ti kuro ni ogoji (40), o ti dieeyan mẹtalelaadọfa (113).

Oríṣun àwòrán, Babajide sanwo-olu
Ọjọ ọla ṣu dẹdẹ fun iṣẹ awọn oṣiṣẹ
Bi awọn dokita atawọn oṣiṣẹ eto ilera miran ṣe n foju wina arun coronavirus lẹnu iṣẹ lawọn oṣiṣẹ miran n foju winna rẹ nipa yala pipadanu iṣẹ ni tabi aimọ igba ti owo oṣu yoo wọle.
ọpọlọpọ awọn oṣiṣẹ ni iroyin jẹ ko di mimọ pe awọn alaṣẹ ileeṣẹ wọn ti sọ sinu isinmi ọlọdọọdun ni tipa.
Bi awọn miran si ṣe n gba ẹdinwo oṣu ni awọn kan n gbadura kiṣẹ maa bọ lọwọ wọn.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ipaya to n ba ọpọ oṣiṣẹ bayii bi pupọ ninu wọn ṣe n pada sẹnu iṣẹ ni pipadanu iṣẹ. Ipaya yii ti dori ẹmi ọpọ oṣiṣẹ to bẹẹ gẹ ti alaga ẹgbẹ oṣelu APC to n ṣejọba lorilẹede Naijiria, Adams Oshiomhole, toun pẹlu ti figbakan ri jẹ aarẹ ẹgbẹ oṣiṣẹ lorilẹede Naijiria fi rawọ ẹbẹ sawọn agbanisisẹ lati maṣe da awọn oṣiṣẹ silẹ tabi dinowo wọn ku.
Ki lawọn ajọ agbaye n sọ nipa ọjọ iwaju awọn oṣiṣẹ lasiko ati lẹyin ajakalẹ arun Coronavirus.
Amọṣa, ajọ to n mojuto ọrọ awọn oṣiṣẹ lagbaye, ILO ti sọ pe ọgbọn ko digi lọrọ naa bayii nitoripe bi nnkan ṣe n lọ yii, igba o din marun miliọnu (195milion)lawọn eeyan ti yoo padanu iṣẹ wọn lagbaye nipasẹ ajakalẹ arun Coronavirus.

- Coronavirus: Àwọn ohun tí a kò tíì mọ̀ nípa àrùn Covid-19
- Kí lo mọ̀ nípa fẹntilétọ̀, ohun èlò aṣèrànwọ́ èémí
- Ṣé òògùn Chloroquine lè dènà ààrùn Coronavirus bí?
- Coronavirus tún ti ṣe ọṣẹ́ lórí iṣẹ́ líla ojú ọ̀nà relùwe láti Eko sí Ibadan - Ìjọba àpapọ̀
- Àrùn Coronavirus fa'lẹ̀ya láwọn ìletò aláwọ̀dúdú ní Amẹ́ríkà

New symptoms of coronavirus: Ọwọ́ tẹ̀ èèyàn 65 tó tàpá sí òfin gbéléẹ níbi ayaẹyẹ ọjọ́ ìbí

Oríṣun àwòrán, others
Ìgbìmọ̀ amúṣẹ́yá ìpínlẹ̀ Eko lóríi Covid-19 ti mú àwọn aláríyá márùndínláàádọ́rin (65) lóríi ẹ̀sùn ìtàpá sí òfin gbéléẹ láti dẹ́kun àj]akálẹ̀ ààrùn Coronavirus ní ìpínlẹ̀ náà.
Ìròyìn fi hàn pé ibùdó ìgbáfẹ́ẹ 84 Parks and Gardens ni àwọn ènìyàn náà péjú sí ní àdúgbo Abule Egba fún ayẹyẹ ọjọ́ ìbí náà.
Ìròyín sọ pé ìgbìms náà lọ sí ibi ayẹyẹ náà ni lẹ́yìn ìgbà tí àwọn ará ìlú ta wọ́n lólobó.
Ọ̀gá iléeṣẹ́ LASEPA tó ń mojútó àyíká ní ìpínlẹ̀ Eko, Dolapo Fasawe, sọ wí pé wọ́n ti fi àwọn afurasí náà sọwọ́ sí àwọn ọlọ́pàá, lẹ́yìn tí wan ti ìbùdọ ìgbáfẹ́ náà pa.

Oríṣun àwòrán, others
Ọ̀gá LASEPA náà ṣe àlàyé pé àjàkálẹ̀ ààrùn ti sọ ará ìlú di ọ̀kan tí ó sì gbà wọ́n ní ìyànjú àti máà ìròyìntó àwọn aláṣẹ létí.
Agbẹnússọ ọlọ́pàá ní ìpínlẹ̀ náà, Bala Elkana, tó fi ìdí ọ̀rs náà múlẹ̀ , sọ pé lóríi ẹ̀sùn ìtàpá sí òfin kí onílé gbé ilé àti lílo ẹfgbò igi olóró ni wọ́n fi mú àwọn afurasí náà.
Murder: Alága ẹgbẹ́ NURTW tó gún ọlọ́pàá pá, gba ìdájọ́ ikú

Oríṣun àwòrán, Other
Ilé ẹjọ́ gíga ti Ikeja n'ilu Èkó tí dá ẹjọ́ ikú fún alaga ẹgbẹ́ awakọ èrò NURTW, ẹ̀ka ti Boundary/Ayetoro nipinlẹ Eko, Saheed Arogundade lórí ẹ̀sùn pé ó pa ọlọ́pàá kan.
Ọlọpaa náà, Gbenga Oladipupo nii ṣe ẹni ọdún méjìlélọ́gbọ̀n, nígbà tó ṣe alabapade ikú òjìji náà.
Nígbà tó ń gbé ìdájọ́ rẹ kalẹ, èyí tó gbà wákàtí mẹta gbáko, adájọ́ Olabisi Akinade pàṣẹ pé, nítorí ìpèsè ààbò tó péye, kí wọn tí gbogbo ọ̀nà tó wọ inú gbọ̀ngàn igbejọ náà, kí wọn sì kó àwọn kọ́kọ́rọ́ rẹ wá fún òun, lọ́nà àti dènà kí idaru-dapọ má bàa wáyé lásìkò tí igbejọ bá ń lọ lọ́wọ́.
Nínú àlàyé rẹ, aṣáájú ikọ olupẹjọ, Arábìnrin C Rotimi-Odutola ṣàlàyé fun ilé ẹjọ́ pé ọ̀daràn náà ṣẹ ẹsẹ ọhun lọ́jọ́ kẹwàá oṣù kẹrin ni ìkòríta Gbara, Ayetoro ládùúgbò Ajegunle nílùú Eko.
"Olóògbé náà ń wà ọkada lọ láti ṣe abẹwo si màmá rẹ, Arábìnrin Mojisola Martins ni ile rẹ to wá ní òpópónà Olayinka ni Ajegunle, nígbà tí àwọn gende mẹ́rin ṣẹburu rẹ nikorita Gbàrà, àwọn mẹta nínú wọn mú Ọlọpaa náà mọ́lẹ̀, tí Arogundade sì ń gùn olóògbé náà laimọye ìgbà, kí gbogbo wọn to salọ."
"Wọn gbe olóògbé tó fara gba ọgbẹ náà lọ sílè ìwòsàn àmọ́ ẹpa kò boro mọ, Ọlọpaa náà jáde láyé."
Ikọ olupẹjọ náà ni, ẹsẹ kan ṣoṣo tí olóògbé náà ṣẹ àwọn awakọ èrò náà, tí wọ́n fi rán án sọrun ọsan gangan ni pé, ó sewuri fún àwọn onikẹkẹ Maruwa láti máa na Ayetoro, èyí tó ń mú adinku bá owó tí àwọn awakọ èrò ń pá.
Nínú ìdájọ́ rẹ, adájọ́ ni ikọ olupẹjọ fi ẹri tó dájú hàn pé Arogundade lo gbẹmi Ọlọpaa naa, to sì ni kí wọn yẹ igi fún un, títí tí ẹ̀mí yóò fi bọ lára rẹ.
Àmọ́ Adájọ́ Akinlade fún àwọn olujẹjọ márùn-ún yòókù tó ń jẹjọ pẹ̀lú Arogundade ni ìdáǹdè lórí ẹ̀sùn onikoko méjì, tí wọn fi kan wọn.
Ní kété tí adájọ́ gbé ìdájọ́ rẹ kalẹ tán, ní Arogundade ṣubú lulẹ nílé ẹjọ́, táwọn mọlẹbi rẹ náà sì bu sí ẹkún kíkorò.
Ọwọ́ ọlọ́pàá tẹ afurasí ọkùnrin tó fipá bá ìyàwó rẹ̀ lòpọ̀, tí obìnrin náà sì gbabẹ̀ kú
Awọn agbofinro ti mu afurasi kan lori ẹsun wi pe o fipa ba iyawo rẹ lopọ ti obinrin naa si gba ibẹ dreo ọrun.

Oríṣun àwòrán, Other
Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Jigawa, Abdu Jinjiri ṣalaye pe abule Kankaleru ni ijọba ibilẹ Ringim ni iṣẹlẹ ọhun ti ṣẹlẹ.
Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ni ọkunrin naa, Alasan Audu fipa ba iyawo rẹ lopọ lẹyin ti obinrin naa kọ lati fun un.
- Àwọn èèrò ìwòran ní kóótù gbalé ẹjọ́ dọ́gbà ẹ̀wọ́n l'Ọṣun
- Wo àwọn ọmọbìnrin tó mu ìtọ̀ ara wọn nítorí òùngbẹ aṣálẹ̀ Sahara
- 'Dokita ilé ìwòsàn ló gba ẹsẹ̀ lọ́wọ́ mi'
- ‘Pussypedia’ rèé, ojú òpó tó ń mú àdínkù bá ìṣòro ìmọ̀ nípa ẹ̀yà ara obìnrin
- Lórí ọ̀rọ̀ Ogun Majek, mi ò lọ́rọ́ láti sọ, ẹ lọ pe ẹni tára rẹ̀ kò yá- Mr. Latin lórí àìsàn Ogun Majek
- Iléèwé Chrisland yóò wọlé padà lọ́jọ́ Ajé, wọ́n ní òfin ìgbélé coronavirus kò mú ìgbẹ̀kọ́ orí ayélujára
- Ìyàn ń bọ̀ ní Nàìjíríà lẹ́yìn coronavirus àyàfi... - Ẹgbẹ́ àgbẹ̀ kìlọ̀
Ọgbẹni Abdu Jinjiri fikun ọrọ rẹ pe awọn tọkọ taya naa ti n ni ede-ai-yede tẹlẹ ti wọn fẹ ara wọn fun ogunjo pere ki ṣaaju iṣẹlẹ naa.
Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ni iyawo naa to di oloogbe, ẹni ọdun metadinlogun ko fẹ fẹ ọkunrin naa lọkọ, ṣugbọn wọn mu ni tipa tipa lati fẹ ẹ.

Oríṣun àwòrán, Other
Iwadii awọn ọlọpaa fihan pe laago mẹrin oru ni ọkunrin naa wọle tọ iyawo rẹ lọ, ṣugbọn obinrin naa ko gba lati jọ ni ajọṣepọ pẹlu ọkọ rẹ nitori oun kọ lo wu u lati fẹ.
Bayii ni atẹjade ileeṣẹ ọlọpaa sọ pe ọkunrin naa fipa ba iyawo rẹ lopọ lati le tan ifẹ inu ara rẹ.












