Ilé ẹ̀jọ́ tún pàṣẹ pé ẹnikẹ́ni tó bá nífẹ̀ẹ́ láti ra àwọn dúkìá náà gbọ́dọ̀ yọjú láàárín ọ̀sẹ̀ méjì péré

Oríṣun àwòrán, Others
Ilé ẹjọ́ gíga ìlú Abuja tí pàṣẹ pé àjọ tó ń gbógun ti ìwà ìbàjé, ICPC, gbé ẹsẹ lé àwọn dúkìá kan tó jẹ́ ti akọ̀wé tẹ́lẹ̀ fún àjọ JAMB, Ọjọgbọn Dibu Ojerinde.
Lára àwọn dúkìá tí Ojerinde pàdánù sọwọ àjọ ICPC ni ileesẹ Rédíò Gravity FM tó wà n'ilu Igboho, ilé ẹ̀kọ́ Sapati tó wà lójú ọ̀nà Ajase Ipo, n'ilu Ilorin, ilé epo Soka tó wà n'ilu Ibadan àti ilé ìtura Òkè Afin tó wà níwájú Fáṣítì imọ ẹ̀rọ Ladoke Akintola n'ilu Ogbomoso.

Oríṣun àwòrán, Others
Àwọn dúkìá yókù tí Ojerinde yín pàdánù ni, ilé epo àti gaasi Doyin tó wà nilu Ibadan, ilé Tejumola to wá ní Ikeja n'ilu Eko tó fi mọ ilé awodamienu kan tó wà lojule Kẹrìnlá, Yobe close, Maitama n'ilu Abuja pẹ̀lú dúkìá rẹ miran tó wà ní orílẹ̀ èdè South Africa.
Kódà, Ojerinde tún pàdánù àwọn ìpín idokowo àti ọ̀pọ̀ owó goboi tó ní làwọn ilé ifowopamo sí ọwọ àjọ ICPC.
Ìkéde nípa àwọn dúkìá yìí, tí Ójẹrinde pàdánù sì ọwọ àjọ ICPC ni ilé ẹjọ́ ti tẹ síta, lójú àwọn ewé ìwé ìròyìn kan nilẹ wa .
Adájọ́ Ijeoma Ojukwu, lásìkò tó ń gbé àṣẹ náà kalẹ tun kéde pé, owó ìlú ni Ojerinde fi kó àwọn dúkìá náà jọ, èyí tíì ṣe ere tó rí láti ara ìwà ajẹbanu tó lòdì sofin.
Adájọ́ Ojukwu ṣàlàyé síwájú pé, ẹnikẹ́ni tó bá nífẹ̀ẹ́ láti ra àwọn dúkìá náà gbọ́dọ̀ gbé igbesẹ láti ṣe bẹ́ẹ̀ láàrin ọ̀sẹ̀ méjì péré nígbàtí ìjọba àpapọ̀ kò si gbọ́dọ̀ jogún àwọn dúkìá náà lẹ́yìn ó rẹyìn.
Àjọ ICPC ni yóò sì máa ṣe àkóso àwọn dúkìá náà Ogbeni David Igbodo, tíì ṣe igbá-kejì ọga agba ọlọ́pàá, ẹni tí wọ́n yàn bíi alákòóso fidihẹ lórí àwọn dúkìá náà, títí tilè ẹjọ́ yóò fi gbé àṣẹ míràn kalẹ lórí àwọn dúkìá náà.

Oríṣun àwòrán, ICPC












