Oludije YPP, Debo Ranti Ajayi: Ekiti nílò gómìnà tó mọ́ ibi tí bàtà ti ń ta àwọn eèyàn

Àkọlé fídíò, Oludije YPP, Debo Ranti Ajayi: Ekiti nílò gómìnà tó mọ́ ibi tí bàtgà ti ń ta àwọn eèyàn

Se ohun kankan le ti Nasareti jade wa ni ibeere ọpọ lori gomina tuntun Ekiti?

Oludije sipo gomina ni ipinle Ekiti, Debo Ranti Ajayi gbalejo BBC Yoruba ni Ekiti.

O salaye awọn nakn to ni lọkan lati se fun awọn oludibo ni ipinle Ekiti.

Lojo Satide, ojo kejidinlogun, oṣu yii ni eto idibo naa yoo waye ti awon oludibo ni Ekiti a dibo yan eni to wu won.

Kini Debo Ranti tun sọ?

Oludije labẹ ẹgbẹ oselu Young Progressives Party yii tun sọ fun BBC Yoruba peoun lo maa jẹ gomina akọkọ to ti sin ipinle Ekiti kot o jade dupo gomina.

O menuba awon iriri to ti ni nile yii ati loke okun nigba to n geb nibẹ.

O sọ nipa awọn ayipada rere to fẹ mu ba igbeaye awọn ara ipìnle Ekiti.