Nkan tó yẹ kí o mọ̀ nípa Olaniyi Ben Agboola, olúdíje ẹgbẹ́ PRP nínú ìdìbò gómìnà ipinlẹ Ekiti

Olaniyi Ben Agboola

Oríṣun àwòrán, Olaniyi Ben Agboola /Facebook

Àkọlé àwòrán,

Ọkan lara àwọn to n dije fun ipo gomina ipinlẹ Ekiti, ti yoo waye lọjọ Abamẹta, ọjọ kejidinlogun, oṣu Kẹfà, ọdun 2022,ni Olaniyi Ben Agboola.

Ọdun 2018 ni Ọgbẹni Olaniyi Ben kọ́kọ́ wọ agbo oṣelu, lasiko to díje fun ipo gomina ipinlẹ Ekiti labẹ asia ẹgbẹ́ oṣelu Alliance for Democracy (AD).

Sugbọn ninu idibo ti ọdun yìí, lati inu ẹgbẹ́ oṣelu People's Redemption Party (PRP) ni yoo ti dije.

Ọdun 1970 ni wọn bi Olaniyi Ben Agboola n'ilu Odo-Oro Ekiti ni ijọba ibilẹ Ikọle

Olaniyi Ben Agboola

Oríṣun àwòrán, Olaniyi Ben Agboola/Facebook

O lọ si ile ẹ̀kọ́ gbogboniṣe Federal Polytechnic Ado-Ekiti, nibi to ti kẹkọọ gba iwe ẹri ninu akoso oko-owo, Business Administration and Management.

Lẹyin naa lo lọ si fasiti imọ ẹ̀rọ Ladoke Akintola, n'ilu Ogbomoso, lati gboye imọ ijinlẹ kejì, laarin ọdún 1997 si 1999.

Gẹ́gẹ́ bi akọsilẹ to kọ nipa ara rẹ si oju opo ayelujara Instagram, ogbontagi onimọ nípa òwò ṣíṣe ni Ben Agboola.

O si ti sisẹ ni àwọn ileeṣẹ nlanla ni Naijiria, ati nilẹ okeere, fun ọdun mẹẹdọgbọn.

Lọwọlọwọ, o jẹ oniṣowo ninu iṣẹ agbẹ.

Agboola sọ pe idi ti oun fi fẹ di gomina ipinlẹ Ekiti, ni lati ra ipinlẹ naa pada, ki oun si mu pada bọ sipo.