Ajagunigbala Moses Olajide, pásítọ̀ tó fẹ́ di gómìnà ipinlẹ Ekiti lábẹ́ àsìá ẹgbẹ́ AAC

Oríṣun àwòrán, Ajagunigbala Moses Olajide/Facebook
Oludije fun ipo gomina labẹ asia ẹgbẹ́ oṣelu African Action Congress (AAC) ninu idibo ipinlẹ Ekiti ti yoo waye lọ́jọ́ kejidinlogun, oṣu Kẹfa, ọdun 2022, ni Ajagunigbala Moses Olajide.
Wọn bi ni ọjọ kẹẹdogun, oṣu Kẹjọ, ọdun 1964, n'ilu Aramoko, nipinlẹ Ekiti.
Gẹ́gẹ́ bi akọsilẹ nipa rẹ to wa lori ayelujara Facebook, o ni iwe ẹri ile ẹ̀kọ́ girama ati ti GCE.
Bakan naa lo gba iwe ẹri ninu imọ Bíbélì ni Fasiti ilu Calabar.
Alufaa ni Ajagunigbala ninu ijọ African Apostolic Church, n'ilu Igede-Ekiti.

Oríṣun àwòrán, Ajagunigbala Moses Olajide
Lọdun 2018, wọn yan an gẹgẹ bi akọwe ikede fun ẹgbẹ́ oṣelu Mega Party of Nigeria (MPN), lasiko idibo gomina ipinlẹ Ekiti lọdun 2018.
Oludije ẹgbẹ́ AAC ọhun sọ pe oun yoo mu atunṣe ba ẹka eto ilera nipinlẹ Ekiti.
Bákan naa lo ni oun yoo ṣe atunto igbokegbodo ọkọ, to fi mọ eto aabo, nipinlẹ naa.












