Ekiti 2022: Ǹjẹ́ o mo Olùdíje ẹgbẹ́ òṣèlú NNPP?
Oladosu Abiodun ọmọ àgbà ọ̀jẹ̀ òṣèré Peter Fatomilola náà ń díje dupò gómìnà Ekiti

Oríṣun àwòrán, Screenshot
Oladosu Abiodun Fatomilola ẹni ọdun mẹtadinlaadọta jẹ ọmọ bibi ilu Ifishin ni Ipinlẹ Ekiti.
Ọmọ gbajumọ oṣere tiata, Peter Fatomilola, ni olujide naa.
Ìgbà àkọ́kọ́ rèé tí Fatomilola ń díje dupò gómínà lábẹ́ ẹgbẹ́ òṣèlú labẹ asia ẹgbẹ oselu New Nigeria Peoples Party(NNPP).
Fatomilola bẹrẹ ile ẹkọ alakọọbẹrẹ ni Moremi High School niluu Ile Ife ni Ipinlẹ Osun.
Ó tẹsiwaju ninu iwe kika rẹ ni Fasiti Obafemi Awolowo, nibi ti o ti ka iwe gba òye.

Oríṣun àwòrán, Screenshot
Ki Fatomilola to darapọ mọ oṣelu, ó ṣiṣẹ pẹlu D'Concept Entertainment gẹgẹ bi oludamoran
Ko tan si be, Fatomilola jẹ Olukọ ni ọpọlọpọ ile iwe ni orilẹ ede Naijiria
Bakana ni nigba kan ri, o jé sọrọsọrọ pẹlu ile ise telifisan ati radio.
Nígbà tí alága ẹgbẹ́ òṣèlú New Nigeria People Party(NNPP) ní ìpínlẹ̀ Ekiti, Hon Yinka Dada gbé àsíá ẹgbẹ́ lé Fatomilola lọ́wọ́ gẹ́gẹ́ bí olùdíje ẹgbẹ́ náà, O ní àsìkò ti tó láti gba ìpÍnlẹ̀ Ekiti là lọ́wọ́ àwọn àjòjì ati awọn afi asiko sofo.
Bákan náà ló jẹ́jẹ̀ẹ́ pẹ oun sétan láti ṣiṣẹ́ sin àwọn ènìyàn ìpínlẹ̀ Ekiti pẹlu iberun olorun àti láti le ri pé ìpínlẹ̀ Ekiti rí ìdàgbàsókè àti ìlọsíwájú ni ọpọlọpọ ona.












