Remi Surutu kí èpè bọnú lórí ọ̀rọ̀ ọmọ rẹ̀ tó dolóògbé, ìdí rèé

Remi Surutu

Oríṣun àwòrán, Instagram

Gbajúgbajà òṣèré tíátà nnì, Remi Oshodi tí ọ̀pọ̀ mọ̀ sí Remi Surutu ti kọminú lórí bí ènìyàn kan ṣe fi ikú ọmọ rẹ̀ àgbà bú u.

Itahunsira laarin Surutu ati ẹni naa waye lórí ayélujára nítorí ẹgbẹ́ òṣèlú tí òṣèrébìnrin yìí yàn láàyò.

Nínú àtẹ̀jáde kan tí Remi Surutu fi sórí Instagram rẹ̀ ló ti ṣàfihàn bí ẹni náà ṣe kọ ọ̀rọ̀ sábẹ́ fídíò kan tó ṣe láti fi tàbùkù olùdíje sípò gómìnà ìpínlẹ̀ Eko lẹ́gbẹ́ òṣèlú Labour Party, Gbadebo Rhodes-Vivour.

Nínú fídíò náà ni Remi Surutu àti akẹgbẹ́ rẹ̀ kan, Lege Miami ti ní Rhodes-Vivour ń ṣe ọ̀yájú sí ààrẹ tí Nàìjíríà ṣẹ̀ṣẹ̀ dìbò yàn, Bola Ahmed Tinubu àti gómìnà ìpínlẹ̀ Eko, Babajide Sanwo-Olu.

Àmọ́ ọ̀pọ̀ àwọn olólùfẹ́ Remi Surutu ni kò nífẹ̀ẹ́ sí fídíò náà tí wọ́n sì ń fi èrò wọn hàn, tí ọ̀pọ̀ sì ń kọ èrò wọn lórí fídíò ọ̀hún.

Lára àwọn tí fídíò náà kò tẹ́ lọ́rùn ní ọmọbìnrin kan tí òun kọ pé agbanipa ni Remi Surutu kó má pa òun gẹ́gẹ́ bó ṣe pa ọmọ rẹ̀.

Èyí ló mú kí Remi Surutu fún ọmọbìnrin náà lésì pé ó rán òun létí nípa ohun tó jẹ́ ìbánújẹ́ àti ọgbẹ́ ọkàn jùlọ fún un láyé, tó sì ti èpè bọ ẹnu fún ọmọbìnrin náà.

Remi Surutu ní àsìkò ìjọba àwaarawa ni a wà, níbi tí èèyàn ti ní àǹfàní láti yan olùdíje tàbí ẹgbẹ́ tó bá wù ú láti tẹ̀lé.

Ó ní ṣe nítorí òun yan ẹgbẹ́ òṣèlú APC láàyò gẹ́gẹ́ bí tí òun ń tẹ̀lé ni ọmọbìnrin náà fi ń ọ̀rọ̀ ọmọ òun tó ṣe aláìsí bú òun.

Ó fi kún un pé ṣé òun pa ọmọ láti lè jẹ́ kí ẹgbẹ́ òṣèlú APC jáwé olúborí lásìkò ìbò ni àbí kí ni ó pa ọ̀rọ̀ ọmọ òun tó ti di olóògbé papọ̀ mọ́ ọ̀rọ̀ òṣèlú.

Kìí ṣe Remi Surutu nìkan ni òṣèré tí àwọn ọmọ Naijiria ti ń wọ́ lórí ọ̀rọ̀ olùdíje tí wọ́n bá yàn láàyò.

Bákan náà ló ké sí Ọlọ́run àti ẹlẹ́dàá ọmọ rẹ̀ náà láti jọ̀ọ́ jàre gbèjà òun jà lórí ọ̀rọ̀ yìí.

Gbajúmọ̀ òṣèré náà ní kò sí abiyamọ láyé tó gbàdúrà kí iná ọmọ jó òun nítorí náà òun mọ̀ wí pé ẹni tọ wà nídìí èébú náà yóó ko tirẹ̀ níwájú.

Skip Instagram post
Allow Instagram content?

This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of Instagram post

Kí ni Toyin Abraham ṣe tí wọ́n ń wọ́ ọ lórí ayélujára lọ́jọ́ ìdìbò gómìǹà?

Toyin Abraham

Oríṣun àwòrán, OTHERS

Fa ki n fa a tun ti ru soke lori ayelujara lonii ọjọ idibo gomina ati aṣofin ipinlẹ to si gbe orukọ gbajugbaja oṣere Toyin Abraham sori bii harahara.

Ṣe ni awọn ọdọ doju ọrọ kọ oṣere obinrin naa gẹgẹ bi wọn ṣe n kọ oniruuru ọrọ ati ibeere sita ti wọn si n lẹ orukọ rẹ mọ ọ lati lee jẹ ko ri gbogbo ohun ti wọ́n n kọ nipa rẹ.

Lara ohun to faa ti wọn tun fi wọ Toyin Abraham lọ sori ayelujara paapaa, oju opo Twitter ni awọn kudiẹ kudiẹ to yọju lasiko ti eto idibo n lọ lọwọ.

Kete ti awọn eeyan ri bi igboro ṣe bẹrẹ si ni daru lawọn apa ibi kọọkan ni wọn n fi aworan, fọnran ati ọrọ sita pe ki Toyin Abraham wa wo wahala ti o n to sẹyin wọn n fa ni ilu o. Amọ ko sẹni to lee fi aridaju kan pato gbe lẹyin ọrọ yii wipe awọn eeyan kan pato lo da wahala silẹ lọjọ idibo Naijiria.

Skip X post
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of X post

Ki wa ni ti oṣere Toyin Abraham ninu ọrọ tito ilu ati iṣejọba?

Toyin Abraham, Tinubu ati Sanwoolu

Oríṣun àwòrán, OTHERS

Nigba ti gbogbo ọmọ Naijiria n gbaradi fun eto idibo, awọn gbajugbaja oṣere bẹrẹ si ni polongo fun oludije to wu wọ́n lati dibo fun.

Toyin Abraham naa bọ si oju opo ayelujara rẹ gẹgẹ bi ọmọ Naijiria to si fi lede pe ohun gangan ni “Asiwaju Baby” bẹẹ si ni Asiwaju ni oun yoo tẹka oun fun iyẹ Bola Tinubu oludije to pada jawe olubori.

Ṣaaju idibo naa, ọpọlọpọ ọdọ Naijiria ti yari pe ẹgbẹ oṣelu to wa lori alefa lọwọlọwọ ti ba ilu jẹ torinaa awọn ko fẹ ẹnikẹni lati ẹgbẹ naa ko di aarẹ awọn.

Ibanujẹ lo jẹ fun ọpọ wọn nigba ti wọn ri oṣere ti wọn fẹran gan to wa n kede kaakiri pe “Asiwaju Baby” ni oun.

“Aarẹ temi kan ṣaa yaayi ṣaa” – Eyi ni ọrọ ti Toyin Abraham kọ sita nigba to n kan sara si oludije ipo aarẹ to fẹran.

Kete ti wọn rii ni awọn ololufẹ Toyin ti inu wn ko dun si ọrọ naa ti han an ti awọn mii si n bu ẹnu atẹ lu toyin lati igba naa pe o n ṣatilẹyin fun oludije ti ko ni nnkankan lati fun awọn.

Awọn oṣere mii ti awọn eeyan n bu ẹnu atẹ lu tori oludije ti wọn dibo fun.

Awọn oṣere

Oríṣun àwòrán, OTHERS

Ẹwẹ, kii ṣe Toyin Abraham nikan ni gbajugbaja oṣere ti awọn eeyan n kọ ẹnu si tori pe o fi oju oludije rẹ han.

Lara awọn mii ti ẹnu n kun lori wọn naa ni Debo Macaroni, Iyabo Ojo, Saheed Balogun, Iyabadan, olorin nni Falzthebadguy ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Ni ọjọ Satide ọjọ Kejidinlogun Oṣu Kẹta ti idibo gomina ati aṣofin ipinlẹ waye, ṣe ni awọn kan tun bọ sori opo Twitter ti wọn doju ọrọ kọ Toyin Abraham amọ́ oun naa ko fi ṣe ọmọ lọ ile lọ gba esi wa, oun naa fesi si ohun ti wọn n fi lọ ọ.