Igbákejì Gómìnà tẹ́lẹ̀ ní Ekiti, Bisi Egbeyemi, jáde láyé

Oríṣun àwòrán, Others
Oloye Bisi Egbeyemi to ti fi igba kan jeͅ igbakeji gomina nipinleͅ Ekiti ri ti di oloogbe
Owuro kutukutu Oͅjoͅ Satide, oͅjoͅ idibo ni Egbeyemi jade laye, ni ile iwosan gbajugbaja kan ni ipinleͅ Ekiti, leͅyin oͅdun moͅkandinloͅgoͅrin.
Oͅkan lara awoͅn to ba Egbeyemi sͅisͅeͅ nigba ti to wa ni isͅejoͅba ti ko feͅ ka da orukoͅ reͅ lo fi idi iroyin naa muleͅ.
O fikun un pe Ile iwosan adani kan ni igbakeji gómìnà àna naa ku si ni ilu Ado Ekiti.
Awon moͅleͅbi oloogbe oͅhun ko i ti fi atejade kankan sita lori iku eͅni woͅn to jade laye.
Ki Bisi Egbeyemi to doloogbe, o di igbo igbakeji gomina mu lati oͅdun 2018 si oͅdun 2022.
Ohun to yeͅ ki o moͅ nipa Bisi Egbeyemi

Oríṣun àwòrán, Twitter
- Oͅjoͅ Keͅjoͅ, Osu Karun un oͅdun 1944 ni woͅn bi Bisi Eͅgbeyemi ni ilu Ado Ekiti,
- O loͅ si ileeͅkoͅ alakoͅbeͅreͅ St. Saviour's Primary School, Ado-Ekiti, Holy Trinity Anglican School Ilawe-Ekiti (1958) ati Baptist School, Ado-Ekiti (1959),
- Leͅyin naa lo loͅ si ileeͅkoͅ Harding Memorial Secondary Modern School to si gba sabuke,
- Leͅyin naa lo keͅkoͅ lai loͅ si ileeͅkoͅ ijoͅba lasiko to n sͅisͅeͅ geͅgeͅ bi laabu ileeͅkoͅ Ekiti Parapoͅ College,
- Lasiko yii lo gba sabukeͅ WAEC reͅ to fi moͅ GCE ni oͅdun 1972,
- Leͅyin naa lo koͅ eͅkoͅ imoͅ Biology ati Physical Education ni Fasiti Eko, to si sͅetan peͅlu ami eͅyͅ to pegede,
- Bakan naa ni Bisi Egbeyemi loͅ si fasiti ile-ifeͅ OAU lati loͅ keͅkoͅ imo ofin lati oͅdun 1977 si 1980,
- Leͅyin naa lo loͅ si ileeͅkoͅ imoͅ ofin Lagos Law School to si beͅreͅ isͅeͅ amofin ni oͅdun 1981,
- Lasiko to wa ni ileeͅkoͅ ni Fasiti Ifeͅ ati Fasiti Eko lo ti jeͅ adari awoͅn akeͅkoͅoͅ ni kilaasi reͅ, ni fasiti mejeeji ti o ti koͅ eͅkoͅ,
- Ni oͅdun 2010 si 2014 lo di ipo adari ile igbafeͅ Owena Motels nipinleͅ Ondo ati adari ileesͅeͅ Odua Investment Company,
- Oͅdun 2017 ni o dije du ipo igbakeji gomina nipinleͅ Ekiti peͅlu Kayode Fayemi to dije geͅgeͅbi gomina ti woͅ si woͅle,
- Ni oͅdun 2020 ni o soͅ wi pe ko si otitoͅ ninu iroyin pe woͅn feͅ yoͅ oun nipo nitori awoͅn kan ni ko yeͅ ko di ipo igbakeji gomina naa mu,
- Oͅdun 2022 lo kuro ni ipo geͅgeͅ bi igbakeji gomina amoͅ ko jeͅ Oͅloͅrun ni ipe ni oͅjoͅ kejidinlogun, osu keͅta, oͅdun 2023.












