Mò ń retí kí wóͅͅn wá fi pańpéͅ oͅba mú mi ní Oͅjóͅ Ìsͅéͅgun – Donald Trump

Aworan

Oríṣun àwòrán, Others

Aareͅ orileͅede Amerika teͅleͅri, Donald Trump ni oun reti ki ileesͅeͅ oͅteͅleͅmuyeͅ ileͅ Amerika wa fi panpeͅ oͅba mu oun ni Oͅjoͅ Isͅeͅgun, oͅseͅ to n boͅ.

Eͅsun ti woͅn fi kan an ni pe o san owo goͅboͅi fun olowo nooͅbi kan lati gbeͅnu dakeͅ ṣaaju idibo sipo aareͅ lorileͅede Amẹrika.

Oͅkan ninu awoͅn agbeͅjoͅro Donald Trump ni awoͅn iroyin to n jade ni Trump ti n ko firi pe o ṣeese ki woͅn wa fi panpeͅ oͅba mu oun.

Amoͅ Trump kesi awoͅn ololufeͅ reͅ ki woͅn fi eͅhoonuhan tako iru isͅeͅleͅ beͅeͅ ko ma baa waye.

Ti woͅn ba fi eͅsun kan Trump, ti woͅn si fi panpeͅ oͅba mu, eyi yoo jasi pe oun ni aareͅ teͅleͅri akoͅkoͅ ti woͅn yoo fi eͅsun iwa oͅdaran kan lorileͅede Amerika.

Bakan naa ni o seese ko nipa lori eͅgbeͅ oselu Republican ati igbiyanju woͅn lati fi lede geͅgeͅ bi oludije sipo aareͅ ni oͅdun 2024.

Eͅsun ti woͅn fi kan Donald Trump

Fun oͅdun marun un bayii ni awoͅn agbeͅjoͅro ni ilu New York ti beͅreͅ si ni sͅewadii eͅsun pe Trump san owo goͅboͅi fun osere olowonoͅoͅbi teͅleͅ, Stormy Daniels saaju idibo sipo aareͅ oͅdun 2016.

Saaju ni arabinrin Daniels ti fi eͅsun kan agbeͅjoͅro Trump teͅleͅ, Michael Cohen pe woͅn san $130,000 (£107,000) fun owo, iyeͅn owo gba mabinu pe woͅn joͅ ni nkan poͅ ri.

Amoͅ Trump ni ko si nkan to joͅ beͅeͅ laarin awoͅn mejeeji, ati pe awoͅn eͅni ibi ni woͅn feͅ da erongba oun geͅgeͅ bi oloselu ru.

Eͅsun yii peͅlu oͅkan lara awoͅn eͅsun ti woͅn fi kan Trump to jeͅ eͅni oͅdun meͅrindinloͅgoͅrin, amoͅ to ni ohun ko jeͅbi eͅsun ti woͅn fi kan oun.