Agbébọn ya bo àgọ́ ìdìbò l‘Eko, jí àpótí ìbò gbé, ẹ̀mí kan bọ́, díẹ̀ farapa

Iroyin to n tẹ wa lọwọlọwọ sọ pe awọn agbebọn kan ti ya bo ibudo idibo Unit 075 to wa ni Iyana-Ishashi, nipinlẹ Eko.
Awọn olugbe agbegbe ọhun sọ fun awọn akọroyin BBC pe iṣẹlẹ naa ba awọn ninu jẹ nitori bi awọn agbebọn naa ṣe da eto dibo ru nibẹ.
Ọkan lara awọn olugbe ọhun, Colins Micheal to ti kọkọ dibo ṣaaju nibẹ ṣalaye pe awọn janduku kan lo ṣadede yabo ibudo naa ti wọn si ṣina ibọn bolẹ bi wọn ṣe n gbe apoti ibo lọ.
O ni “N ṣe ni a n dibo lọ jẹjẹ bii ọmọluabi ki a to dede bẹrẹ si n gbọ ariwo... Awọn eeyan bẹrẹ si n sare, bẹẹ naa la ri awọn janduku lori alupupu ti wọn wa da ibudo idibo wa ru.”
“Wọn ji apoti ibo gbe lọ, gbogbo awa ti a wa nibẹ ni a sa asala fun ẹmi wa.”
“Wọn gbe igo simi lori lati dibo fun ẹni ọkan mi ko fẹ”

Oríṣun àwòrán, others
Ẹlomiran ti ọrọ nasa tun ṣoju rẹ, Stanly Ndive, sọ pe awọn janduku mu ohun wọ ibudo idibo, wọn na igo si ori oun, wọn si fi agidi mu oun lati dibo fun ẹni ti ọkan oun ko fẹ.
O ni “Wọn na igo si ori mi bi wọn ṣe n mu mi lọ si ibudo idibo lati lọ dibo fun APC.”
Awọn janduku tun da ibo run agbegbe Ago Palace

Ni adugbo Startimes Estate to wa ni Ago Palace way, awọn janduku tun wọ inu adugbo lọ lati da ibo ru nibẹ.
Lara awọn olugbe adugbo ọhun to ba BBC Yoruba sọrọ, Folasade Owolabi sọ pe gbogbo awọn ara adugbo naa ti jade ladi dibo, amọ awọn janduku kan wa da adugbo naa ru.
O ni “Ohun ti a gbọ ni pe awọn jaduku fo ogiri Estate wa wọle.”
“Wọn ni awọn n fẹ ki a gbe ibudo idibo wa kuro ninu adugbo lọ si ẹnu ọna adugbo ki wọn le ri aye lati ṣe ohun to wu wọn.”
“Amọ nigba ti a kọ lati ṣe ohun ti wọn bere, ka to wi, ka to fọ, wọn ti bẹrẹ si n da gbogbo adugbo wa ru ti wọn si n na awọn oludibo.”
Awọ jauduku dana sun ohun elo idibo ni Ojo

Iroyin mii lati adugbo Tedi, ni Ojo to wa nipinlẹ Eko, awọn janduku tun ṣọṣẹ nibẹ.
Iroyin ni gbogbo ohun elo idibo ni awọn jaduku naa dana sun.
Lara awọn ohun ti wọn dana sun ni awọn beba, ẹrọ BVAS, atawọn ohun elo idibo mii.
Ẹnikan ti iṣẹlẹ naa ṣoju sọ pe bo tilẹ jẹ pe awọn ọlọpaa wa nibẹ lasiko ikọlu ọhun, iroyin ni ko si ohun ti wọn le ṣe.
Ọ̀rọ̀ di ìfaǹfà láàárín INEC àtàwọn olùgbé VGC lórí ibùdó ìdìbò

Àwọn olùdìbò ní agbègbè VGC ti fárígá pé àwọn kò ní dìbò ní ibi tí àwọn òṣìṣẹ́ àjọ INEC gbé kalẹ̀ fún àwọn láti dìbò.
Àwọn ènìyàn agbègbè náà ní láti ọjọ́ pípẹ́ ni àwọn ti máa ń dìbò nínú ọgbà àwọn nínú VGC àmọ́ tí INEC ṣàdédé yí padà lónìí láì ní ìdí kankan.
Wọ́n ní lásìkò ètò ìdìbò ààrẹ tó kọjá ibi tí àwọn ti to àga àti àwọn ẹrù àwọn sí ni àwọn tún ti tò ó kalẹ̀ sí ṣùgbọ́n tí àwọn òṣìṣẹ́ kọ̀ jálẹ̀ pé àwọn kò ní wọ inú ọgbà náà àyàfi tí bá ma wá bá àwọn ní títì.
Wọ́n ní INEC kò ní ẹ̀tọ́ láti yí ibùdó ìdìbò àwọn padà lọ́jọ́ ìdìbò gangan láì ṣe wí pé wọ́n sọ fún àwọn tẹ́lẹ̀.
Wọ́n fi kun pé láti ọdún pípẹ́ ni àwọn ti ń máa ń dìbò nínú ọgbà àwọn àti pé tí àwọn bá lọ bá wọn níbi tí wọ́n gbé ibùdó náà sí fún àwọn báyìí le ṣokùnf[]a kí wọ́n ní ìbò àwọn kò jẹ́ nǹkankan.



Àwọn òṣìṣẹ́ INEC kọ̀ láti wọ inú ọgbà VGC nítorí pé aago mẹ́rin òru ni wọ́n kúrò lásìkò ìbò ààrẹ - olùgbé VGC
Ọ̀kan lára àwọn ará agbègbè VGC tó bá BBC News Yorùbá sọ̀rọ̀, Alhaji Lukman Sulaimon ní láti ọdún 2011 ni òun ti máa ń dìbò ní agbègbè náà tó sì jẹ́ wí pé inú ọgbà yẹn ni àwọn ti máa ń dìbò.
Alhaji Sulaimon ní ó jẹ́ ohun ìyàlẹ́nu fún òun pé àwọn òṣìṣẹ́ INEC ní kí àwọn máa bọ̀ ní ìtagbangba lónìí.
Nígbà tó ń sọ̀rọ̀ ìdí tí àwọn òṣìṣẹ́ INEC fi fárígá, ó ní àwọn òṣìṣẹ́ INEC náà sọ wí pé aago mẹ́rin òru ni àwọn ènìyàn náà tó jẹ́ kí àwọn kúrò níbẹ̀ lẹ́yìn tí ìbò ti parí.
Ó fi kun pé láti nǹkan bíi aago mẹ́jọ òwúrọ̀ tí àwọn ti wà níbẹ̀ láti dìbò ṣùgbọ́n títí di nǹkan bíi aago méjìlá tí à ń kó ìròyìn yìí jọ àwọn ènìyàn náà kò ì tíì dìbò.
















