Lẹyìn tó tẹ ìyá arúgbó 70 pa,erin padà wá lọ́jọ́ ìsìnkú láti wá gbé òkú sálọ

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Eemọ nla leleyi afi bi aransi!
Bi kii ba si ṣe pe awa naa ri aridaju rẹ, a ko ba maa sọ pe boya eeyan kan ro ọrọ naa sọ ni.
Ṣugbọn ohun to ṣẹlẹ ni tootọ ni. Ẹ tẹti bẹlẹjẹ lati maa fi ọkan ba ọrọ yi bọ.
Iroyin taa mu tọ yin wa ni pe erin kan lẹyin to tẹ iya arugbo ẹni aadọrin ọdun kan pa, o tun wa oku iya lọ si ibi isinku to si tun gbe oku naa to si tẹ mọlẹ.
Bawo gaan nlo ṣe ṣẹlẹ
Ileeṣẹ ọlọpaa ni orileede India lofidi ọrọ yi mulẹ pe erin kan tẹ iya arugbo kan pa nibi toti n pọnmi ni idi kanga.
Ladugbo Mayurbhanj ni Odisha ni iṣẹlẹ yi ti waye lọjọ Abamẹta yi.
Gẹgẹ bi wọn ṣe sọ, iya ẹni ọdun aadọrin yi taa mọ si Maya Murmu n pọnmi lọwọ nidi kanga ni erin inu igbo yi to rin irin aare kuro nibi aaye igbẹrankopamọ si Dalma ṣadede doju ija kọ.
O tẹ iya mọlẹ ti iya si farapa yanayana.
Awọn eeyan to wa nibẹ du ẹmi iya nipa siasare lati gbe lọ si ile iwosan amọ o padanu ẹmi rẹ lọwọ eṣe to ni nitori bi erin naa ṣe tẹ mọlẹ.
Insipẹkitọ ọlọpaa agọ ọlọpaa to wa ni Rasgovindpur,Lopamudra Nayak fidi ọrọ yi mulẹ.
Ko tan sibẹ, erin tun wa oku iya wa sibi isinku
Awọn mọlẹbi ko fi ọrọ naa falẹ, bi iya ti ṣe ku,wọn gbe oku wa sile ti wọn si mura lati ṣe eto isinku.
Gẹgẹ bi iṣe wọn ni India wọn palẹmọ oku ti wọn si ko igi jọ lati sun oku.
Ori ibi ti wọn gbe oku si ni irọlẹ ọjọ taa n wi yi ni erin naa ba tun ṣadede yọ si wọn.
Ka to wi ka to fọ, o ti fẹnu gbe oku iya to si ju danu.
Ko tan sibẹ, erin naa tun tẹ oku yi mọlẹ ki awọn eeyan to ribi le salọ ti wọn si gbe oku nilẹ pada.
Isinku pada waye
Eeyan kan ti iṣẹlẹ yi ṣoju rẹ sọ pe awọn mọlẹbi pada tun palẹmọ oku yi lẹẹkeeji lẹyin iṣẹlẹ yi.
Ko si ẹni to le ṣalaye nkan to mu ki erin yi foju ija han aaye ati oku iya yi.
O to bi wakati meloo kan lẹyin ti erin tẹ oku iya yi pa nigba keji ki wọn to pada ṣeto isinku fun iya arugbo ọhun.
A ko ribi fidi ọrọ mulẹ boya wọn ti ri erin naa da pada si aaye ẹrano to ti sa kuro.















