Láyé! Mi ò ní pe Sanwo-Olu láti kí i kú oríire, irọ́ ni ìbò tó gbé e wọlé - Gbadebo Rhodes-Vivour

Babajide Sanwo-Olu àti Gbadebo Rhodes-Vivour

Oríṣun àwòrán, Twitter

Olùdíje sípò gómìnà ìpínlẹ̀ Eko lẹ́gbẹ́ òṣèlú Labour Party, Gbadebo Rhodes-Vivour ti fárígá pé òun kò ní pé gómìnà Babajide Sanwo-Olu láti ki kú oríire bí INEC ṣe kéde rẹ̀ bí ẹni tó gbégbá ìbò fún sáà kejì.

Rhodes-Vivour nígbà tó ń bá àwọn akọ̀ròyìn sọ̀rọ̀ lẹ́yìn tí INEC kéde pé gómìnà Babajide Sanwo-Olu ló jáwé olúborí níbi ètò ìdìbò gómìnà tó wáyé lọ́jọ́ Àbámẹ́ta ní ọ̀pọ̀ àwọn èrú ló wáyé lásìkò ìbò náà.

Ó ní ọ̀pọ̀ àwọn èsì ìbò ni INEC ti yí kí wọ́n tó gbé e sórí ayélujára tó sì tún jẹ́ pé ọ̀pọ̀ èsì ni kìí ṣe ti gómìnà, tó jẹ́ ti ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin àmọ́ tí wọ́n kà papọ̀ fún ìbò gómìnà.

“Gbogbo àwọn èsì ìbò yìí ni a ní lọ́wọ́, ẹgbẹ́ òṣèlú wa ló ń lékè nín;u àwọn èsì ìbò tó wà lọ́wọ́ wa, ilé ẹjọ́ ni yóó sì báwa yanjú gbogbo rẹ̀.”

Ó ní òun kọ gbogbo èsì ìbò àti àgbékalẹ̀ ètò ìdìbò tó wáyé ní ìpínlẹ̀ Eko nítorí ètò ìdìbò náà kò gbé oúnjẹ fẹ́gbẹ́ gba àwo bọ̀.

Ìwà jàgídíjàgan ló wáyé ní gbogbo àwọn ibùdó ìdìbò, ọ̀pọ̀ ènìyàn ló farapa

“Láti ìgbà tí wọ́n ti bí mi, ètò ìdìbò tó wáyé ní ọdún 2023 ní ìpínlẹ̀ Eko yìí ló burú jùlọ nítorí ẹnikẹ́ni tó bá tó fẹ́ dìbò fún ẹgbẹ́ Labour Party, níṣe ni wọ́n ń nà wọ́n kúrò níbẹ̀.”

“Ó lé ní ènìyàn méjìlá ti mo san owó ìtọ́jú wọn ní ilé ìwòsàn lẹ́yìn tí wọ́n ṣe wọ́n léṣe ní ibùdó ìdìbò, ẹsẹ̀ ẹlòmíràn ti kán tó nílò iṣẹ́ abẹ, ẹlòmíràn dákú tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ jí.”

“Mo bu ẹnu àtẹ́ lu ètò ìdìbò yìí ní gbogbo ọ̀nà, mi ò sì ní kí Babajide Sanwo-Olu kú oríire fún ètò ìdìbò tí kò lẹ́sẹ̀ kankan.”

Ó ní gbogbo àwọn ìwà jàgídíjàgan àti ìwà ìpáǹle ló kún ètò ìdìbò náà fọ́fọ́ tí àwọn jàǹdùkú sì ń fòró ẹ̀mí àwọn ènìyàn lásìkò tí wọ́n fẹ́ dìbò.

Rhodes-Vivour rọ àwọn ènìyàn ìpínlẹ̀ Eko láti ṣe àdúrótì fún òun lójúnà àti lè ri pé àwọn gba ohun tó jẹ́ ẹ̀tọ́ àwọn padà lọ́wọ́ ìjọba tó wà lóde.

Skip X post
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of X post

Ilé ẹjọ́ ló máa yanjú gbogbo ọ̀rọ̀ yìí

Gbadebo Rhodes-Vivour

Oríṣun àwòrán, Twitter

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Gbadebo Rhodes-Vivour ní gbogbo àwọn èsì ìdìbò tó wà ní ọwọ́ àwọn ni àwọn yóò ṣe àkójọ rẹ̀ láti lọ ṣàgbékalẹ̀ rẹ̀ ní ilé ẹjọ́ láti fi hàn pé àwọn jáwé olúborí ìbò náà.

Bákan náà ló ní àwọn ènìyàn nílò dìde fún ara wọn láti ri pé wọ́n jàjà lòdì sí ìwà ẹlẹ́yàmẹ̀yà èyí tó fojú hàn gidi lásìkò ìbò gómìnà Eko.

Ó ní láti ìgbà #endsars ni gbogbo àwọn nǹkan bíi títẹ ẹ̀tọ́ ọmọnìyàn lójú mọ́lẹ̀ ti ń wáyé ti gbogbo àwọn sì gbọdọ̀ gbárùkù tìí láti fòpin sí ìwà bẹ́ẹ̀.

“Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ibùdó ìdìbò ni a ní èròńgbà láti sọ fún ilé ẹjọ́ láti da àwọn ìbò ibẹ̀ nù kí wọ́n ṣètò ìdìbò mìíràn nítorí gbogbo nǹkan tó wáyé níbẹ̀ kìí ṣe ìdìbò.”

“Gbogbo àwọn agbẹjọ́rò wa la ti kàn sí, wọ́n sì ti ń ṣe àkójọ gbogbo àwọn èsì ìbò tó wà lọ́wọ́ wa láti fi gbé ẹjọ́ wa ró níwájú ìgbìmọ̀ tó ń gbọ́ ẹ̀hónú ìbò.

“A jẹ gbogbo àwọn tó fi ẹ̀mí wọn lélẹ̀ láti jáde dìbò fún wa pẹ̀lú gbogbo ìpèníjà tí wọ́n kàn lásìkò ìbò náà ní ipa láti pe APC àti INEC lẹ́jọ́ lórí èsì ìbò náà.”